Ẹ̀mí Mímọ́: Ǹjẹ́ A Gba Iná Jẹ Àbí A Se Ìdáàbòbò Kí á má baà Gba Iná Jẹ?Àpẹrẹ
Agbára, kókó ẹ̀rí Onígbàgbọ́
Ó yà mí l'ẹ́nu nígbàtí mo kà nínú Marku 16:8 pé àwọn ọmọ-ẹ̀hìn, kí Jésù tó gòkè re òrun, kò gbàgbọ́. Àìgbàgbọ́ kan náà ni a rí ní Marku 16:11. Lẹ́hìn náà, ní ẹsẹ̀ méjì sí'sàlẹ̀ ní ẹsẹ̀ 13, àwọn ọ̀rọ̀ mẹ́ta kan náà- wọn kò gbàgbọ́. Lẹ́ẹ̀kan si, ní ẹsẹ̀ 14, àwọn ọ̀rọ̀ mẹ́ta kan náà-wọn kò gbàgbọ́. Ṣùgbọ́n ohun tí ó yà mí l'ẹ́nu jù lọ ni pé ní ẹsẹ̀ 15 tí ó tẹ̀lé e, Jésù sọ fún àwọn aláìgbàgbọ́ àti onígbàgbọ́ olùbẹ̀rù wọ̀nyí pé, “Ẹ lọ sí gbogbo ayé, kí ẹ sì wàásù Ìhìn Rere fún gbogbo ẹ̀dá.”
Ká ní pé mo bá wà níbẹ̀, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n sọ èyí, èmi ìbá ti tọ Jésù wá láti ẹ̀yìn, èmi ìbá sì s'ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sí etí Rẹ̀ pé, “Olúwa, Ìwọ kò mọ̀ pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí O ṣẹ̀ṣẹ̀ fún ní Iṣẹ Gíga Jù Lọ jẹ́ àkójọpọ̀ aláìgbàgbọ́ bí? Wọn kì yóò ní lè ṣe é.” Mo rò pé Jésù yóò yí padà, yóò fi ìka Rẹ̀ lé ètè Rẹ̀, yóò sì sọ ní ìdákẹ́jẹ́ fún mi pé, "Bonnke, ìwọ kò mọ̀ pé Mo ní àṣírí kan."
Kíni àṣírí náà? Ní ẹsẹ̀ 20, a kà pé: “Wọ́n jáde lọ, wọ́n sì wàásù níbi gbogbo, Olúwa sì ń bá wọn ṣiṣẹ́, ó sì ń fi ìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ nípasẹ̀ àwọn àmì tí ó tẹ̀ lé e, Amin.” Kíni ó ṣẹlẹ̀ láàrín ẹsẹ̀ 14 ati ẹsẹ̀ 20? Ní ìlànà ìṣíṣẹ ntẹ̀lé, Ìṣe Àwọn Àpóstélì Orí 2 ṣẹlẹ̀. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà jáde kúrò nínú àìlera wọn, wọ́n sì dé ibi agbára láti ṣe ohun tí Jésù pa l'áṣẹ fún wọn láti ṣe: “Ṣugbọn ẹ̀yin yóo gba agbára nígbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé yin. Ẹ óo wá máa ṣe ẹlẹ́rìí mi ní Jerusalẹmu, ati ní gbogbo Judia ati ní Samaria ati títí dé òpin ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8). Ní ọ̀nà kan náà, gbogbo wa lé fi àìlera sílẹ̀ kí a sì tẹ̀ sínú agbára àìlópin.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Agbára àgbàyanu, tó ń jí òkú dìde ḿbẹ nínú rẹ. Ajíhìnrere Reinhard Bonnke ti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tó nípọn nípa Ẹ̀mí Mímọ́ fún ọ àti wípé ó kọ àwọn Kókó Àgbàyanu nípa Agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ̀kọ́ Ọlọ́jọ́ Méje yìí ma mú ọ ronú nípa Ẹ̀mí Mímọ́ àti wípé ó máa ru ọ́ sókè láti ní ìgbàgbọ́ nínú agbára Ẹ̀mí náà tó ń gbé nínú rẹ.
More