Lilépa KáróòtìÀpẹrẹ
Lílépa Àṣeyọrí
Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn Ọba tó jẹ nínú Bíbélì, kòsí ẹnikẹ́ni tó ṣe àṣeyọrí tó Sólómọ́nì. Ọ̀rọ̀ ajé Ísírẹ́lì ròkè nígbà ìjọba rẹ̀. Lábẹ́ ìṣọ́ọ rẹ̀ ni a ti kọ́ tẹ́mpílì Ọlọ́run. Ó kọ́ ààfin ọba fún ara rẹ̀. Àwọn adarí a máa tí òkèèrè wá láti wo ọlá rẹ̀, tí wọn yóò sì mú ẹ̀bùn wúrà àti àwọn ẹ̀ṣọ́ iyebíye wá. Kòsí ìbéèrè tí a jùsi tí kò lè dáhùn. Àwọn obìnrin ààyò ló yíiká. Gbogbo ǹkan tí ènìyàn lè fi tọrọ ni a fi jíǹkí rẹ̀.
Tó bá ní ẹnìkan tó yẹ kí inú rẹ̀ máa dùn torí gbogbo àṣeyọrí tí wọn gbáyé ṣe, Sólómọ́nì ló yẹ kí ẹni náà jẹ́. Ṣùgbọ́n nínú ìwé oníwàásù, ọ̀tọ̀ ni àlàyé tí Sólómọ́nì ṣe níbẹ̀. Ohun tí ó sọ ni wípé, “Mo kórìíra gbogbo ǹkan tí mo làágùn láti kó jọ ...” Ó ṣe àlàyé síwájú síi, “nítorí ó pọn dandan fúnmi láti fi gbogbo rẹ̀ sílẹ̀ fẹ̀ni tó máa delé lẹ́yìn mi.”
Sólómọ́nì ní ìṣípayá nípa ǹkan kan. Wípé a kò lè mú ǹkankan lọ lẹ́yìn tí a bá papòdà. Bóyá ìgbéga, ilé, ẹ̀bùn ìdánimọ̀, ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́, tàbí ìrìn àjò fún ìsinmi, laó fi sílẹ̀ lọ.
O lè máa ròó wípé kí ló wá ṣe kókó láyé yìí gan?
Sólómọ́nì rí ìdáhùn kan sì ìbéèrè yìí. Ní ìparí ìwé oníwàásù, ó ṣe àkójọ pọ̀ gbogbo rẹ̀, “bẹ̀rù Ọlọrun, kí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́, nítorí èyí nìkan ni iṣẹ́ ọmọ eniyan.”
Láì farabalẹ̀, èyí lè fara jọ ọ̀rọ̀ ìrúni-sókè, ṣùgbọ́n túbọ̀ farabalẹ̀ káà. Sólómọ́nì sọ wípé àwọn ohun tí a nílò láti lépa láyé nìyí: ìbẹ̀rù Ọlọ́run—èyí tó túmọ̀ sí fífẹ́ràn Rẹ̀, bíbu ọlá fún Un, pẹ̀lú títẹ̀lé ọ̀rọ̀ Rẹ̀.
Ó ti mọ́wa lára láti máa gbọ́ ọ̀rọ̀ ìyànjú inú ayé tó ń wípé, “Sáré! Má ṣe dúró. Ṣé o rí ọrọ̀ yẹn? Àti àwọn ǹkan iyì wọ̀nyí? Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn bíi tìrẹ ló ń lépa wọn, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́kí èyí fa ìrẹ̀wẹ̀sì. Jà fún wọn! Máa lọ! Kí ló tún kù tofẹ́ fi ayéè rẹ ṣe? Ìdíje ni ayé jẹ́, àwọn tó tayọ nìkan ló sì máa yege.”
Ṣùgbọ́n Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ wípé, “Fẹ́ràn Ọlọ́run. Kí o sì ṣe rere.”
Ṣe ìjíròrò lóríi bí èyí ti rọrùn fún gbogbo ènìyàn. Bóyá o ti gbéyàwó tàbí o ṣì dáwà. Jẹ ọlọ́rọ̀ tàbí òtòṣì. Ọmọdé tàbí àgbà. Ní ìléra tàbí ṣe àìsàn. Ṣáà ti fẹ́ràn Ọlọ́run kí o sì ṣe rere.
Gba èyí rò: Kíni yóò yí padà nípa òní tí gbogbo ìlépa rẹ bá kú sí fífẹ́ràn Ọlọ́run àti ṣíṣe rere? Báwo loti máa ṣe àṣeyọrí nínú ìlépa yìí?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Gbogbo wá ló ǹ lépa nǹkan kan.O sábà máa ń jẹ́ nǹkan tí kò sí lárọ́wọ́tó bíi—iṣẹ́ tó dára, ilé tó tún dára,ìdílé pípé, àfọwọ́sí àwọn ẹlòmíràn. Àmó ńjẹ́ èyí kì í múni se àárẹ̀? See kò sí ọ̀nà mìíràn tó dára ni? Ṣe ìwádìí nínú ètò Bíbélì titun tí Life.Church, tí ń tè lé onírúurú ìwàásù Pastor Craig Groeschel nípa, lílépa kárọ́ọ̀tì.
More