Lilépa KáróòtìÀpẹrẹ
Lílépa Òkìkí
Nínú èdè Gíríìkì, ọ̀rọ̀ tí wọ́n ńlò fún Òkìkí ni—phēmē, wọ́n sì ń pè ní fā'-mā— A lo ọ̀rọ̀ yí ní ẹ̀ẹ̀mejì péré nínú májẹ̀mú titun. Wọn a má sábà túmọ̀ rẹ̀ sí ọ̀rọ̀, ìjábọ̀, tàbí ìròyìn. Báyìí ni a se lo Òkìkí phēmē ní Lúkù 4:14 KJV:
Jésù padà sí Gálílì pẹlu agbára Ẹ̀mí Mímọ́: Òkìkí rẹ̀ kàn ká gbogbo ìgbèríko.
Níbo ni Jésù ti ńpadà bọ̀ tí ó jẹ́ kí Òkìkí rẹ̀ kàn ká gbogbo ìgbèríko? Ejẹ́ kí á wòó. Ní Luku orí kìnní, agbọ́ nípa ìbíi Jésù. Ní Luku orí kejì, a bí Jésù ósì dàgbà di ọmọkùnrin kékeré. Ní Luku orí kẹta, a se ìrì bọmi fún un. Lákòtán, ní àwọn ẹsẹ tí o bẹ̀rẹ̀ Luku orí kẹrin, Jésù ń gba àwẹ̀, ósì la ìdánwò tí sátánì gbé wá kọjá. Èyí mú wa padà sí Luku orí kẹrin ẹsẹ̀ kẹrìnlá.
Lẹ́yìn náà Jésù darí sí Gálílì, ókún fún agbára È̩mí Mímọ́.Ìjábọ̀ nípa rẹ̀ tàn ká gbogbo agbègbè yí ní kíákíá.
Nínú ẹ̀kọ́ kíkà tòní, a ó wo ìtàn nípa gbogbo ìdánwò tí ó là kọjá nínú aginjù. Jésù ń gbàwẹ̀ nínú aginjù fún ogójì ọjọ́, bí ó se ńgbàwẹ̀, sátánì fúnrarẹ̀ dán Jésù wò pẹ̀lú irú ohúnjẹ tí kò tọ́ (Luku 4:3-4), Òkìkí(Luku 4:5-8), àti ìgbàgbọ́ (Luku 4: 9-12). Lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan, Jésù kọ àwọn ìdánwò yí, ósì dáhùn pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Luku 4:14 Òkìkí òrí bíi irú èyí tí à ńlépa, njẹ́ ó rí bẹ́ẹ̀? Ódàbí a má ńlépa irú èyí tí sátánì fẹ́ fún Jésù nínú aginjù. Ìpèsè láì sí ìtẹ́lọ́rùn(Luku 4:3-4), ọlá láì sí ìfaradà (Luku 4:5-8), àti ìgbàlà láì sí ìjọ̀wọ́ ara wa (Luku 4:9-12).
Ejẹ́ kí á ro ìtẹ́wọ́gbà ní ẹnu isẹ́, ìtẹ́wọ́gbà ti àwùjọ ayélujára, àti ìgbóríyìn láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mííràn. Ó jẹ́ kí inú wa dùn fún ìgbà díẹ̀, lẹ́yìn èyí a tún bẹ̀rẹ̀ síní wá síi. Tí a bá fẹ́ sọ òótọ́, àwọn àkókò kán ti wà tí a fẹ́ kí àwọn ènìyàn rí wa, tàbí kí á gbajúmọ̀ fún nkànkan.
A ó tún kà nípa ìdánwò ìkẹyìn tí sàtánì wí fún Jésù wípé kí ó bẹ́ láti orí téńté òrùlé nítorí Ọlọ́run yó tẹ́wọ́ gbà kí ó má bá subú. Njẹ́ ìwọ ti gba àdúrà tí o fẹ́ fi ipá jẹ́ kí Ólọ́run se nkan ní ọ̀nà tìrẹ nìkan, ní àkókò tí o fẹ́? Kò bu ọlá fún Ọlọ́run rárá-nítorínà ni Jésù se dáhùn ó sì wípé kí á má dán Ọlọ́run wò báyí.
Èdè kán wà tí a ti se àtúntò rẹ̀, wọ́n ńpè ní PIE—Proto-Indo-European—alálẹ̀ tí a kò tí kọ sí àwọn Griki. Orísun ọ̀rọ̀ PIE tí ó di òkìkí phēmē, ni -bha, tí ó túmọ̀ sí "títàn" àti "ọ̀rọ̀ sísọ". Nítorí nàà ẹjẹ́ kí a padà sí orísun wa. A kò dá wa láti jẹ́ Ìmọ́lẹ̀ Náà-JÉSÙ- ṣùgbọ́n a pè wá láti tan ìmọ́lẹ̀ ẹ rẹ̀. A kì se Ọ̀rọ̀ náà- Ìhìnrere Johánù sọ wípé Jésù ni Ọ̀rọ̀ náà- ṣùgbọ́n a pè wá láti sọ ọ̀rọ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ sí gbogbo àgbáyé.
Lílépa Òkìkí túmọ̀ sí kí á wá ohun tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run kàkà kí á máa wá jíjẹ́ ọlọ́run fúnrarẹ̀. Èyí ni àkókò ìdánwò nínú ìwé náà. Má se subú sínú ìdánwò yìí. Nígbàkúgbà tí o bá dojúkọ ìdánwò òkìkí, se ohun tí Jésù se. Tan ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run nípa sísọ ọ̀rọ̀ rẹ. Tí o bá sì ti se eléyìí, ohun ti ó ṣẹlẹ̀ ní Luku 4:14 yíò ṣẹlẹ̀. Òkìkí Jésù yíò tàn káàkiri.
Gbàdúrà: Ọlọ́run, Báwo ni ìyànjú mì láti ní ìtẹ́wọ́gbà se ńmú mi kúrò nínú títan ìmọ́lẹ̀ rẹ? Mo fẹ́ sá tẹ̀lé O pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó wà nínú mì. Àmín.
Nípa Ìpèsè yìí
Gbogbo wá ló ǹ lépa nǹkan kan.O sábà máa ń jẹ́ nǹkan tí kò sí lárọ́wọ́tó bíi—iṣẹ́ tó dára, ilé tó tún dára,ìdílé pípé, àfọwọ́sí àwọn ẹlòmíràn. Àmó ńjẹ́ èyí kì í múni se àárẹ̀? See kò sí ọ̀nà mìíràn tó dára ni? Ṣe ìwádìí nínú ètò Bíbélì titun tí Life.Church, tí ń tè lé onírúurú ìwàásù Pastor Craig Groeschel nípa, lílépa kárọ́ọ̀tì.
More