NIGBATI ayaba Ṣeba si gbọ́ okiki Solomoni niti orukọ Oluwa, o wá lati fi àlọ dán a wò. O si wá si Jerusalemu pẹlu ẹgbẹ nlanla, ibakasiẹ ti o ru turari, ati ọ̀pọlọpọ wura, ati okuta oniyebiye: nigbati o si de ọdọ Solomoni o ba a sọ gbogbo eyiti mbẹ li ọkàn rẹ̀. Solomoni si fi èsi si gbogbo ọ̀rọ rẹ̀, kò si ibère kan ti o pamọ fun ọba ti kò si sọ fun u. Nigbati ayaba Ṣeba si ti ri gbogbo ọgbọ́n Solomoni, ati ile ti o ti kọ́. Ati onjẹ tabili rẹ̀, ati ijoko awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, ati iduro awọn iranṣẹ rẹ̀, ati iwọṣọ wọn, ati awọn agbọti rẹ̀, ati ọna ti o mba goke lọ si ile Oluwa; kò kù agbara kan fun u mọ. O si wi fun ọba pe, Otitọ li ọ̀rọ ti mo gbọ́ ni ilẹ mi niti iṣe rẹ ati niti ọgbọ́n rẹ. Ṣugbọn emi kò gba ọ̀rọ na gbọ́, titi mo fi de, ti oju mi si ti ri: si kiyesi i, a kò sọ idajì wọn fun mi: iwọ si ti fi ọgbọ́n ati irọra kún okiki ti mo gbọ́. Ibukún ni fun awọn enia rẹ, ibukún ni fun awọn iranṣẹ rẹ wọnyi, ti nduro niwaju rẹ nigbagbogbo, ti ngbọ́ ọgbọ́n rẹ.
Kà I. A. Ọba 10
Feti si I. A. Ọba 10
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. A. Ọba 10:1-8
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò