Jésù: àsíá Ìṣẹ́gun waÀpẹrẹ
Ìṣẹ́gun Lórí Ikú
Nígbàtí Jésù kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa tó sì ra ìdáríjì fún wa, Ó gbà wá lọ́wọ́ ìyapa ayérayé kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Ó pààrọ̀ ìmúlẹ̀mófo ikú sí ìrètí ìyè nínú ọjọ́ ọ̀la tí kò lópin níwájú Ọlọ́run. Nígbàtí Ó jíǹde kúrò ní isà òkú, Jésù pàtẹ ìṣẹ́gun tí kò l'ẹ́gbẹ́ lóríi ikú, tó ń jẹ́rìí pé agbára ikú kò leè dúró l'ẹ́gbẹ́ ti Rẹ̀. Nínú Ìwé Ìfihàn 1:18, Ó, “Ẹ̀mi ni Eni tí ó ń bẹ láààyè, tí ó sì ti kú; sì kíyèsi i, èmi sì ń bẹ láààyè sí i títí láé! Mo sì ní kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti ipò òkú lọ́wọ́.”
Botilẹ̀jẹ́pé ikú jẹ́ òtítọ́ tó nira fún wa nínú ayé, bí a ti ṣe ń pàdánù àwọn tó sún mọ́ wa àti ní gbẹ̀yìn tí àwa náà ń kọjú sí àti bọ́ àgọ́ ara ikú wa, a lè di òtítọ́ yìí mú pé Jésù ni Ó di kọ́kọ́rọ́ ikú mú, Ó sì ti pèsè ọ̀nà fún wa láti gbà wọ ẹnu ilẹ̀kùn míràn wọ ayé tí kò ní ìpẹ̀kun. Ikú ní ayé yìí kìí ṣe òpin ìtàn náà. Ọ̀pọ̀lọpọ nkan ló ṣì ń bọ̀ lẹ́yìn! Jésù ṣèlérí nínú Ìwé Jòhánù 11: 25, “Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú yóò yè.”
Nítorí tí Jésù ti gbà wá là kúrò lọ́wọ́ ikú ayérayé, a ò ní lò láti gbé nínú ẹ̀rù. A ní òmìnira láti gbé ayé pẹ̀lú àníkún àti ìgboyà, níwọ̀n ìgbà tí a mọ̀ pé oun yòówù tí kò báà dé láyé yìí, a ó sì gbé pẹ̀lú Ọlọ́run àti ní àárín àwùjọ àwọn ìdílé Rẹ̀. Nígbàtí a tilẹ̀ ń ba inú jẹ́ fún àwọn olùfẹ́, à ń ba inú jẹ́ bíi ẹni tó ní ìrètí, tó sì mọ̀ pé bí wọ́n bá fi ìgbàgbọ́ wọn sínú Jésù, a ó jọ ní ìpàdé a ó sì jọ ní ìrírí ògo Ọlọ́run ní àpapọ̀.
Ní ọjọ́ ìsinmi Àjíǹde yìí, jẹ́ kí ìtumọ̀ ìṣẹ́gun Jésù lórí ikú gbilẹ̀ ní ọkàn rẹ kí o sì yí àfojúsùn rẹ kúrò ní àìlera ayé yìí sí àmọ̀dájú ayérayé wa ní ọ̀run. Ikú ó ní oró mọ́! Yọ̀ nínú ìṣẹ́gun Rẹ̀, kún fún ìmoore, kó sì máa dàgbà si nínú ìdánilójú rẹ pe gbogbo ènìyàn ní ayé ló nílò láti ní ìrètí ọ̀run tí ìwọ náà ní. Èyí ni ọkàn Rẹ̀ nígbàtí Ó ún kú fún ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo aráyé: pé kí ọkàn kan nínú wa má ṣe lo ayérayé ní ìyapa kúrò lọ́dọ̀ Rẹ̀. Kò sí ọ̀nà tí ó tún dára láti fi ọkàn ìmoore hàn fún ohun tó ti ṣe fún ọ ju kí ó sọ fún gbogbo ayé nípa ìfẹ́ Rẹ̀ fún wọn. Báyìí ni a ó ṣe mú ayé yìí ní ìtumọ̀ tó péye. Nítorínáà, jáde síta kí ó sì gbé ayé tó kún rẹ́rẹ́ - nítorí Ó wà láàyè!
Gbà àwòrán tòní sílẹ̀ níbí here.
Nípa Ìpèsè yìí
Nígbà tí a bá ń ṣe ayẹyẹ ajinde, à ń ṣe ayẹyẹ ìṣẹ́gun tí ó ga jùlọ nínú ìtàn. Nípa ikú àti ajinde Jésù', ó borí agbára ẹ̀ṣẹ̀ àti isà òkú títí láí, àti gbogbo ohun àbájáde wọn, ó sì yàn láti pín ìṣẹ́gun náà pẹ̀lú wa. Ní ọ̀sẹ̀ ayẹyẹ yii, jẹ́ kí á wọ inú díẹ̀ nínú àwọn odi agbára tí ó ṣẹ́gun, ṣe àṣàrò lóríi ìjà tí ó jà fún wa, kí o sì yìín gẹ́gẹ́bíi àsíá ìṣẹ́gun wa.
More