Jésù: àsíá Ìṣẹ́gun waÀpẹrẹ

Jesus: Our Banner of Victory

Ọjọ́ 1 nínú 7

Ìṣẹ́gun Lórí È̩ṣẹ̀

Nígbà tí Ádámù àti Éfà ṣ'àìgbọràn sí Ọlọ́run tí wọ́n sì jẹ èso Igi Ìmọ Rere àti Búburú nínú Ọgbà Édénì, ẹ̀ṣẹ̀ di ọ̀kan lára ìṣẹ̀dá ọmọ ènìyàn. Láti ìgbà yí, ẹnikẹ́ni tí a bá bí nípa ti ara wà ní ìyapa pẹ̀lú Ọ́lọ́run nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yí. Nítorí pé Ọlọ́run jẹ́ pípé, kò leè wà nítòsí ibi tí ẹ̀ṣẹ̀ bá wà. Ní Májẹ̀mú Àtijọ́, ó ṣe dandan fún àwọn ọmọ Ísrẹ́lì láti máa fi ọ̀dọ́ àgùtàn tí kò l'ábàmọ́ rúbọ nìgbà gbogbo láti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ wọn dànù. Ẹbọ náà ní láti pé kí ó lè tán gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ - ọ̀nà yìí nìkan ni ẹnikẹ́ni lè fi ní ìdúró t'ó pé níwájú Ọlọ́run.

A máa ń sábà pe Jésù ní "Ọ̀dọ́ Àgùtàn Ọlọ́run" nítorí pé fífi ara Rẹ̀ rúbọ lórí àgbélébùú tán ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo ènìyàn. Ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ ìṣẹ́ ìyanu tí àgbelébùú ṣe ni pé ó yí ègún ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù àti Éfà padà:Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ kan ṣe fa ìpínyà láàrin Ọlọ́run àti ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni ìfarajì tí ẹnìkan tó pé'ye ṣe, ṣe bo ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo ènìyàn mọ́lẹ̀, ó sì lànà fún ìlàjà pẹ̀lú Ọlọ́run. Nítorí pé Jésù fi ara rẹ̀ rúbọ fún wa, a ní ànfààní láti ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run lẹ́ẹ̀kan si. Nígbà tí Ọlọ́run bá wò wá, ẹ̀ṣẹ̀ wa kọ́ ló ń rí - ìwà mímọ́ Ọmọ Rẹ̀ ni Ó ń rí.

Bí a ṣe ń bẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀ Àjínde yìí, ya àsìkò sọ́tọ̀ láti ronú lórí ẹ̀bùn aláràgbàyídá tí Jésù fún wa nígbà tí ó fi ẹ̀mi Rẹ̀ lélẹ̀ láti bo ẹ̀ṣẹ̀ wa. Àpọ́stélì Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ Rómù 6:23 nípa sísọ pé "Ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀." Ní pàtàkì, a ti di òkú nítorí ìwà àìsòdodo wa, àyànmọ́ wa sì ni ìyapa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù tẹ̀síwájú nínú ẹsẹ yìí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ òtítọ́ ti ìràpadà: "ṣùgbọ́n ẹ̀bùn Ọlọrun ni ìyè àìnípẹ̀kun pẹ̀lú Jésù Krístì Olúwa wa." Jésù ti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ wa, ó sì ti ṣeéṣe fún wa láti gbé pẹ̀lú Ọlọ́run títí láíláí!

Ṣíwájú, nítorí pé Jésù ti fi òdodo Rẹ̀ bò wá, ayé wa ti bọ́ lọ́wọ́ agbára ẹ̀ṣẹ̀. Má ṣe gba ìṣẹ̀dá ẹ̀ṣẹ̀ rẹ àtijọ́ láàyè láti mú ọ lẹ́rú. Jésù ti ṣẹ́gun ẹ̀ṣẹ̀, Ó sì ti ṣe ọ́ ní alábàpín ìṣẹ́gun yìí! Kí o lè wà ní òmìnira ni a ṣe tú ọ sílẹ̀. Máa rìn ní òmìnira!

Àkàálẹ̀ àwòrán t'òníhere

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Jesus: Our Banner of Victory

Nígbà tí a bá ń ṣe ayẹyẹ ajinde, à ń ṣe ayẹyẹ ìṣẹ́gun tí ó ga jùlọ nínú ìtàn. Nípa ikú àti ajinde Jésù', ó borí agbára ẹ̀ṣẹ̀ àti isà òkú títí láí, àti gbogbo ohun àbájáde wọn, ó sì yàn láti pín ìṣẹ́gun náà pẹ̀lú wa. Ní ọ̀sẹ̀ ayẹyẹ yii, jẹ́ kí á wọ inú díẹ̀ nínú àwọn odi agbára tí ó ṣẹ́gun, ṣe àṣàrò lóríi ìjà tí ó jà fún wa, kí o sì yìín gẹ́gẹ́bíi àsíá ìṣẹ́gun wa.

More

A fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ ọ ìjọ ti àwọn ilẹ̀ gíga fún pípèsè ètò yí. Fún ìsọfúnni síi, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò:https://www.churchofthehighlands.com