Jésù: àsíá Ìṣẹ́gun waÀpẹrẹ
?Ìṣẹ́gun Lóríi Àìsàn
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa pé nípa nínà Jésù a mú wa lára da. Nígbàtí Jésù kú tó sì jíǹde, Ó ṣẹ́gun ẹ̀sẹ̀, ikú, ati àìsàn irú èyí tí ó wù kó jẹ́ títí ayérayé. Ó jẹ́ ìyàlẹ́nu pé nípasẹ̀ Rẹ̀, a pín nínú ìṣẹ́gun! Ṣùgbọ́n kínì ìṣẹ́gun lóríi àìsàn jẹ́ fún wa, níwọ̀n ìgbà tí a ṣì wà nínú ayé tó ti bàjé yìí?
Nínú ìwé Májẹ̀mú Tuntun yíká, a rí op ọ̀pọ̀lọpọ àpẹẹrẹ iṣẹ́ ìwòsàn ribiribi tí Jésù ṣe àti àwọn Àpọ́sítélì nípa agbára orúkọ Rẹ̀. Ní kíkà àwọn ìjẹ rí ìwòsàn yìí, ó rọrùn láti lérò pé Ọlọ́run yíò dáhùn àwọn àdúrà wa tó dá lórí àìsàn ní ọ̀nà kan pàtó: ìtú sílẹ̀ lọ́gán lọ́wọ́ ìrora, ìwòsàn tó kolẹ̀ lọ́wọ́ àìsàn tí kò gbọ́ òògùn, tàbí ìṣẹ́gun lóríi àníyàn. Kíni ṣíṣe nígbàtí ìrírí wa bá yàtọ̀ sí àfojúsùn wa? A ní lò láti ṣọ́ra láti ma dín ìjìnlè agbára ìwòsàn kù nínú èrò wa.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún wa nínú ìwé Róòmù 8:28 pé Ọlọ́run Ń mú ṣe oun gbogbo ṣiṣẹ́ pọ̀ sí réré fún àwọn tó fẹ́ Ẹ. Kò túmọ̀ sí pé gbogbo oun tó ún ṣẹlẹ̀ ló dára - Ìṣẹ́gun Jésù lórí ẹ̀sẹ̀ àti ikú kò fa igi lé àwọn oríṣiríṣi àdánwò tí a ó là kọjá láyé. Kódà, nínú Jòhánù 16:33, Jésù ṣe ìlérí pé a ó ní ìrírí ìpọ́njú nínú ayé, àti àìsàn, láì ṣiyèméjì wà lára ìpọ́njú tí à ń là kọjá. Botilẹ̀jẹ́pé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni Ọlọ́run má Ń dásí ọ̀rọ̀ pẹ̀lú iṣẹ́ ìyanu, síbẹ̀ a ò lè fọwọ́ sọ yà pé ìwòsàn tó pegedé wá ní ayé yìí. Ṣùgbọ́n a leè fọwọ́ sọ yà lórí ìṣẹ́gun ayérayé tí ìgbàlà ọkàn wa mú dání. A ó lo ayérayé níwájú Ọlọ́run, nínú ekúnrẹ́rẹ́ ayọ̀, àti ìdáǹdè lọ́wọ́ àìsàn, ẹ̀sẹ̀, ìrora, àti àníyàn.
Ẹ má ṣe jẹ́ kí agara dá a yín nígbàtí ó jọ pé àdúrà kò gbà tàbí àbáyọrí tí kò bá èrò ọkàn wa dọ́gba. Ọlọ́run gbọ́ àdúrà rẹ, àti nínú ohun gbogbo, Ó ún ṣiṣẹ́ fún réré rẹ àti ògo ti Rẹ. Bí a ṣe ń tẹsíwájú nínú àkókò this Easter yí, bèèrè kí Ọlọ́run fún ọ ní ìwòye ti o gbòòrò. Nígbàtí a bá fi òtítọ́ orun sí ọkàn wa, a ó lè gbàdúrà pẹ̀lú ìgboyà a ó sì fi ọkàn akin la ìṣòro yọ wù kọjá pẹ̀lú ìdánilójú pé, bótiwùkórí, a óò ṣẹ́gun.
Gba ẹ̀dà àwòrán òní here.
Nípa Ìpèsè yìí
Nígbà tí a bá ń ṣe ayẹyẹ ajinde, à ń ṣe ayẹyẹ ìṣẹ́gun tí ó ga jùlọ nínú ìtàn. Nípa ikú àti ajinde Jésù', ó borí agbára ẹ̀ṣẹ̀ àti isà òkú títí láí, àti gbogbo ohun àbájáde wọn, ó sì yàn láti pín ìṣẹ́gun náà pẹ̀lú wa. Ní ọ̀sẹ̀ ayẹyẹ yii, jẹ́ kí á wọ inú díẹ̀ nínú àwọn odi agbára tí ó ṣẹ́gun, ṣe àṣàrò lóríi ìjà tí ó jà fún wa, kí o sì yìín gẹ́gẹ́bíi àsíá ìṣẹ́gun wa.
More