Jésù: àsíá Ìṣẹ́gun waÀpẹrẹ
Ìṣẹ́gun Lórí Ìtìjú
Ọ̀tá a máa fẹ́ràn láti sọ̀rọ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ wípé Sátánì ń d'ọdẹ kiri bíi kìnnìún tó ń wá ẹni tí yóò pa jẹ. Nínú ìwé Ìfihàn, a pèé ní olùfisùn; a sọ fún wa wípé t'ọ̀sán t'òru ni ó fi ń fi wá sùn níwájú Ọlọ́run. Ọlọ́gbọ́n àrékérekè ni Sátánì, ó sì mọ̀ wípé ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó rọrùn jùlọ fún un láti pa, gbà, àti ba ìpinnu Ọlọ́run fún ayé wa jẹ́ ní láti mú wa wá sí ìrántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa lóòrè kóòrè. Ifẹ́ rẹ ni kí a máa gbé nínú ìtìjú.
Ṣo ríi, ẹ̀bi nííṣe pẹ̀lú ǹkan tí a ṣe, àmọ́ ìtìjú nííṣe pẹ̀lú irú èèyàn tí a jẹ́. Púpọ̀ nínú wa gbà wípé Ọlọ́run ma dárí àṣìṣe wa jìn àmọ́ a ṣí ń gba ọ̀tá láàyè láti fẹ̀sùn kàn wá àti láti mú wa rẹ̀wẹ̀sì nípasẹ̀ àwọn irọ́ nípa irú ẹ̀dá tí a jẹ́. Àwọn irọ́ wọ̀nyí a máa fa ìdíwọ́ lọ́nà ṣíṣe ojúṣe wa ní ìlànà Ọlọ́run fún ayé wa. A pè wá láti ṣe àmúlò àwọn ẹ̀bùn àti tálẹ́ńtì tí Ọlọ́run fún wa láti mú àyípadà rere bá ayé yìí, àmọ́ tí a kò bá j'ara wa gbà kúrò lọ́wọ́ ìtìjú àti èrò àìyẹ, ó ma ṣòro láti ṣe gbogbo iṣẹ́ tí Ó gbé ka iwájú wa.
Nígbà tí Jésù pàrọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wa fún òdodo rẹ̀ lórí igi àgbélébùú, Ó sọ wá di ẹ̀dá titun. Ìhùwàsí wa ní àtijọ́ kò ní ǹkankan ṣe pẹ̀lú irú èèyàn tí a jẹ́ lónìí. Ọmọ Ọlọ́run l'àwa ńṣe, àwọn tí a ti fi ẹ̀ṣẹ̀ wọn jìn, nípasẹ̀ ore-ọ̀fẹ́, tí a sì ti ró lágbára láti ṣe iṣẹ́ ńláǹlà fún ògo Rẹ̀. Èyí nìkan tó láti fún wa ní ìdánimọ̀ titun. Ohùn ìtìjú tó ń sọ̀rọ̀ lòdì sí òtítọ́ yìí jẹ́ irọ́ pọ́nbélé.
Jálẹ̀ ọ̀sẹ̀ Àjíǹde yìí, rántí ǹkan tí Ọlọ́run sọ nípa rẹ, ìwọ ọmọ Rẹ̀, kí o sì mú gbogbo èrò tó lòdì sí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ní ìgbèkùn. Jésù wá kí a ba lè ní ìyè ní kíkún. Gbá ìtìjú sí ẹ̀gbẹ̀ẹ́, kí o sì máa tọ ipasẹ̀ ìmúṣẹ ètò Ọlọ́run fún ayé rẹ!
Ṣe àkáálẹ̀ àwòrán t'òní níbí.
Nípa Ìpèsè yìí
Nígbà tí a bá ń ṣe ayẹyẹ ajinde, à ń ṣe ayẹyẹ ìṣẹ́gun tí ó ga jùlọ nínú ìtàn. Nípa ikú àti ajinde Jésù', ó borí agbára ẹ̀ṣẹ̀ àti isà òkú títí láí, àti gbogbo ohun àbájáde wọn, ó sì yàn láti pín ìṣẹ́gun náà pẹ̀lú wa. Ní ọ̀sẹ̀ ayẹyẹ yii, jẹ́ kí á wọ inú díẹ̀ nínú àwọn odi agbára tí ó ṣẹ́gun, ṣe àṣàrò lóríi ìjà tí ó jà fún wa, kí o sì yìín gẹ́gẹ́bíi àsíá ìṣẹ́gun wa.
More