Jésù: àsíá Ìṣẹ́gun waÀpẹrẹ
Ìṣẹ́gun Lórí Ẹ̀bi
Ọ̀kan lára àwọn ìlépa Sátánì ni láti múwa gbé lábẹ́ òjìji ẹ̀bi fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àtijọ́. Sátánì mọ̀ wípé bí a tilẹ̀ gbàgbọ́ nínú ikú Jésù fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, tí a sì gbé àjàgà ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ náà, a kò ní lè jẹ àǹfààní gbogbo ìbùkún àti òmìnira tó wà nínú ìdáríjì. Níṣe laó kàn máa gbé nínú òjìji ẹ̀ṣẹ̀ wa tó burú jù lọ. Nínú ìwé Jòhánù 9:5, Jésù ṣe àkàwé ara Rẹ̀ gẹ́gẹ́bí Ìmọ́lẹ̀ ayé. Àmọ́ ní Mátíù 5:14 àti 16, Jésù tún sọ wípé, “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ìlú tí a tẹ̀dó lórí òkè kò lè farasin...Bákan náà, Ẹ jẹ ki imọlẹ nyin ki o mọlẹ tobẹ̃ niwaju enia, ki nwọn ki o le mã ri iṣẹ rere nyin, ki nwọn ki o le ma yìn Baba nyin ti mbẹ li ọrun logo.” Jésù kò ní retí wípé kí a jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún ògo Rẹ̀ láìṣe ètò fún wa láti jáde kúrò nínú òkùnkùn ẹ̀bi.
Orin Dáfídì 103:10-12 sọ fún wa wípé ìfẹ́ Ọlọ́run síwa nípọn ju bí a ti lérò lọ, àti wípé Ó ti mú ìkùnà wa jìnà sí sàkánì wa tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí àlà náà jìnà ju ohun tí a lè gbà rò lọ. Nígbà tí Jésù kú lórí àgbélébùú, Ó gbé àjàgà ẹ̀ṣẹ̀ kúrò lọ́rùn àwọn tó gbàgbọ́ títí láé. Ní báyìí a lè rí ìdáríjì Rẹ̀ gbà l'ọ́fẹ̀ẹ́, a lè gbé ìgbé ayé aláìlẹ́bi, a sì ní ìgboyà àti ìfọ̀kànbalẹ̀ láti tọ Ọlọ́run lọ pẹ̀lú.
Bí àyájọ́ àjíǹde Jésù ti ń súnmọ́ etílé, ẹ jẹ́ kí a rántí wípé kìíṣe ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nìkan ni ikú Rẹ̀ jogún fún wa, bíkòṣe pẹ̀lú àṣẹ láti lè bọ́ gbogbo àjàgà ẹ̀bi. Gbogbo gbèsè ẹ̀ṣẹ̀, kódà tí ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jù, ni a ti san pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ Jésù. Máa lọ nínú òmìnira Rẹ̀ lónìí!
Ṣe àkáálẹ̀ àwòrán t'òní here.
Nípa Ìpèsè yìí
Nígbà tí a bá ń ṣe ayẹyẹ ajinde, à ń ṣe ayẹyẹ ìṣẹ́gun tí ó ga jùlọ nínú ìtàn. Nípa ikú àti ajinde Jésù', ó borí agbára ẹ̀ṣẹ̀ àti isà òkú títí láí, àti gbogbo ohun àbájáde wọn, ó sì yàn láti pín ìṣẹ́gun náà pẹ̀lú wa. Ní ọ̀sẹ̀ ayẹyẹ yii, jẹ́ kí á wọ inú díẹ̀ nínú àwọn odi agbára tí ó ṣẹ́gun, ṣe àṣàrò lóríi ìjà tí ó jà fún wa, kí o sì yìín gẹ́gẹ́bíi àsíá ìṣẹ́gun wa.
More