Ọgbọ̀n tó Múná-dóko: Ìrìn-àjò Ọjọ́ Méje fún Àwọn Bàbá Àpẹrẹ
Kíni Àwọn Ìran-tó-ńbọ̀ Ma Mọ̀ọ́ Fún?
“Ohun tí bàbá kan sa gbogbo ipá rẹ̀ láti lépa, àwọn ọmọ rẹ̀ ma lépa rẹ̀ ní ìwọ̀tùn-wòsì. Ohun tí bàbá yìí bá wá lépa ní ìwọ̀tùn-wòsì, níṣe ni àwọn ọmọ rẹ̀ máa yẹ̀bá fún-un . . . àfi to bá rí ǹkan tí àwọn ọmọ-ọmọọ̀ rẹ ńṣe kí o tó lè mọ èsì-ìdánwò rẹ!”
Nígbà tí mo kọ́kọ́ gbọ́ ǹkan tó jọmọ́ èyí lẹ́nu sọ̀rọ̀-sọ̀rọ̀ kan, nkò fi taratara gbàá wọlé. Kòlè jóòótọ́, ní gbogbo ìgbà. Ṣùgbọ́n ọ̀gbẹ́ni yìí wá lo oríṣiríṣi àpẹẹrẹ láti inú ọ̀rọ̀-Ọlọ́run.
Ábúráhámù. Ẹni tó fara rẹ̀ jìn. Tó ńgbọ́ràn. Tó ṣe àgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ náà ìgbàgbọ́. Ísákì ọmọ rẹ̀ ńkọ́? Lótìítọ́ ọkùnrin dídára ló jẹ́, ṣùgbọ́n kùdìẹ̀-kudiẹ àìgbọràn sí ìlànà Ọlọ́run àti sísọ̀kalẹ̀ lọ sí Íjíbítì wà níbẹ̀. Ṣé ẹ kò tíì gbàgbé ìgbà tó parọ̀ wípé àbúrò ni aya rẹ̀ jẹ́ síi, ẹ̀ṣẹ̀ kaánà tí bàbá rẹ̀ dá lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn.
Tío bá yẹ ayé àwọn ọmọ-ọmọ rẹ wò, ǹjẹ́ ǹkan tí sọ̀rọ̀-sọ̀rọ̀ yìí wí jẹ́ òtítọ́ bí?
Àwọn ọmọ Ísákì, Jákọ́bù àti Ésáù jẹ́ ènìyàn dáradára. Ṣùgbọ́n ẹ̀tànjẹ tí Jákọ́bù fi gba ogún-ìbí ńkọ́? Àbí àìnísùúrù tí Ésáù fi tàá fún oúnjẹ?
Kókó ibẹ̀ ni wípé àwa bàbá ní láti lépa Ọlọ́run pẹ̀lú ìtara, kìíṣe pẹ̀lú ìmẹ́lẹ́. Láìmọ̀, àwọn ọmọwa ti ńṣe ìpinnu nípa bí ìgbàgbọ́ wọn yóò ti nípọn tó fún ara wọn nípasẹ̀ ṣíṣọ́ bí ìgbàgbọ́ wá ti ṣe pàtàkì tó síwa.
Má fi àyè kankan sílẹ̀. Sa gbogbo ipáà rẹ. Jẹ́kí gbogbo ayé mọ ìpinnu rẹ láti, fi araà rẹ jìn, láì ṣẹ́ ǹkankan kù, nínú àdúrà, ìdá-mẹ́wàá, ìfẹ́, gẹ́gẹ́bí ọmọ-lẹ́yìn-Kristi tó ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọrẹ-ọ̀fẹ́.
Kí ó lè dájú, bó tilẹ̀ jẹ́ láti òní lọ, wípé pẹ̀lú ìtara nio fi wá Ọlọ́run. Máṣe fàyè sílẹ̀ fún enì-kankan láti pè ọ́ ní oní-ìmẹ́lẹ́ títí láí.
A kìí mọ̀, bóyá àwọn ọmọ-ọmọọ̀ rẹ pẹ̀lú máa ṣàṣeyọrí!
Ìbéèrè: Ǹjẹ́ àwọn ọmọ rẹ lè ṣe àpèjúwe rẹ gẹ́gẹ́ bíi ènìyàn tó ní ìtara fún Krístì nínú ìfẹ́?
Ǹjẹ́ ètò yìí ti pè ọ́ níjà gẹ́gẹ́ bíi bàbá?
Kọ́ si nípa ètòoẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọgbọ́n tó Múná-dóko.
Nípa Ìpèsè yìí
Ó máa ń yani lẹ́nu ìwọ̀n ipa tí bàbá kó nínú irú ẹ̀yán tí a jẹ́. Kò sí ẹnì náà tó lè bọ́ lọ́wọ́ agbára àti ipáa bàbá tíó bí wọn. Nígbà tí ọ̀pọ̀ ọkùnrin kò ṣe tán láti di bàbá, ó ṣe pàtàkì fún wọn láti wá ìtọ́ni – láti inú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti lọ́dọ̀ àwọn bàbá míràn. Ọgbọ́n tó múná-dóko jẹ́ ìrìn-àjò lọ sí ipa ọgbọ́n àti ìrírí fún àwọn bàbá, nípa títẹ̀lé àwọn ìlànà àti ọgbọ́n láti inú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú ìṣúra ìrírí ọ̀kan nínú àwọn bàbá tó dàgbà jù wá lọ, tíó ti k'ọ́gbọ́n nípasẹ̀ àwọn àṣìṣe rẹ̀.
More