Ọgbọ̀n tó Múná-dóko: Ìrìn-àjò Ọjọ́ Méje fún Àwọn Bàbá Àpẹrẹ

Radical Wisdom: A 7-Day Journey For Fathers

Ọjọ́ 1 nínú 7

Ohun Tío Fògo Fún L'omáa Rígbà

Ǹjẹ́ ìwọ ti rí ibi tí ìyà ti ń “múra” fún ọ̀dọ́mọ-bìnrin rẹ̀ rí, tíó sì ńlo oríṣiríṣi 'gbénró' bíi àtíkè, làáálì, àti ìtọ́tè fún ọmọ rẹ̀ láti kékeré? Lẹ́yìn èyí laó wá sọ fún-un ọmọ náà bí ó ti rẹwà tó, èyí kìí ṣe nítorí ó rẹwà ní tòótọ́, ṣùgbọ́n nítorí ọmọ náà (tàbí màmá rẹ) ń tiraka láti fún-un ní ìdánilójú.

Ǹjẹ́ oti dé ibití a ti ńgbá bọ́ọ́ọ̀lù aláfigigbá fún àwọn ọmọdé rí tío sì rí bàbá kan tó ń pariwo bí ọmọ rẹ̀ tí ń yege lóríi pápá? Tí àwọn akẹgbẹ́ẹ rẹ̀ sì yọ̀mọ bóti gbá bọ́ọ́ọ̀lù sínú àwọ̀n.

Moti wà lókè èèpẹ̀ fún ìgbà tíó tó láti rí ǹkan tí àwọn ọ̀dọ́mọ-bìnrin àti ọ̀dọ́mọ-kùnrin yìí dà nígbà tí wọ́n dàgbà tán, lópin rẹ̀ mo wá ri wípé ohun a fògo fún làá rígbà!

Nígbà tí a bá ńlo ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí àti owó tí kò níye láti múra fún àwọn ọmọ wa àfi bíi egúngún, wọn yóò di “ajígbọ́tẹ̀ṣọ́” tí wọ́n bá dàgbà. Nígbà tí àwọn ọmọkùnrin wa kòbá ní ǹkan méjì tí wọn gba oríyìn fún ju eré-ìdárayá, àìníkaánṣe kò jìnà sí wọn tí wọ́n bá dàgbà tán.

Kòsí ohun tó burú nínú àń múra tàbí lo ẹ̀ṣọ́, kòsí aburú nínú ṣíṣe ère-ìdárayá.

Ṣùgbọ́n ṣe àkíyèsí ohun tí ò ń fògo fún lára àwọn ọmọ rẹ.

Nínú èdè mi, ọ̀rọ̀ náà “fògo” ni a lè lò dípòo “oríyìn.” Ohun tío bá gbóríyìn fún lára àwọn ọmọ rẹ ni wọn yóò lépa rẹ̀ bí wọ́n ti ń dàgbà.

Gbìyànjú láti fògo fún ìkáàánú tí ọmọọ̀ rẹ ńṣe f'ẹ́lòmíràn. O bá wọn níbi tí wọ́n ti ńran àbúrò tàbí ẹ̀gbọ́n wọn lọ́wọ́. Yìn wọ́n fún èyí. Fògo fún wọn nígbà tí wọ́n bá ń gbàdúrà, ka Bíbélì, bèrè nípa Jésù, àti nígbà tí wọn bá f'ọrẹ fún ìjọ, tàbí àwọn aláìní.

Rántí, ìwọ lò ń darí ní gbogbo ìgbà. Ṣùgbọ́n ibo lò ń daríi wọn lọ.

Ìbéèrè: Ǹjẹ́ o máa darí nípa fífi ògo fún ohun tío nírètí láti rí gbà nígbà tí àwọn ọmọ rẹ bá dàgbà tán?

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Radical Wisdom: A 7-Day Journey For Fathers

Ó máa ń yani lẹ́nu ìwọ̀n ipa tí bàbá kó nínú irú ẹ̀yán tí a jẹ́. Kò sí ẹnì náà tó lè bọ́ lọ́wọ́ agbára àti ipáa bàbá tíó bí wọn. Nígbà tí ọ̀pọ̀ ọkùnrin kò ṣe tán láti di bàbá, ó ṣe pàtàkì fún wọn láti wá ìtọ́ni – láti inú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti lọ́dọ̀ àwọn bàbá míràn. Ọgbọ́n tó múná-dóko jẹ́ ìrìn-àjò lọ sí ipa ọgbọ́n àti ìrírí fún àwọn bàbá, nípa títẹ̀lé àwọn ìlànà àti ọgbọ́n láti inú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú ìṣúra ìrírí ọ̀kan nínú àwọn bàbá tó dàgbà jù wá lọ, tíó ti k'ọ́gbọ́n nípasẹ̀ àwọn àṣìṣe rẹ̀.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹgbẹ́ẹ akọ́ni lẹ́kọ̀ó̩ Ọgbó̩n tó múná fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: http://radicalwisdombook.com