Ọgbọ̀n tó Múná-dóko: Ìrìn-àjò Ọjọ́ Méje fún Àwọn Bàbá Àpẹrẹ

Radical Wisdom: A 7-Day Journey For Fathers

Ọjọ́ 3 nínú 7

Àgùntàn Tí Kòní Olùṣọ́

Bíi àgùntàn ni àwọn ọmọ-wẹ́wẹ́ tirí. Wọ́n ń dàgbà lọ sípò ìdáwà, ṣùgbọ́n lákòókò yìí, ipá àti agbára ọ̀dọ́ a máa gùn wọ́n—pẹ̀lú ewu àìní ìrírí tó ń kojú wọn.

Bí àgùntàn, wọ́n nílò olùṣọ́ . . . ẹnìkan tí yóò máa ṣọ́ wọn. Wọ́n nílò bàbá. Bàbá gidi. Ó wá bani nínújẹ́, wípé ọ̀pọ̀ ọmọ ni ó ń dàgbà láìní olùṣọ́.

Mo nírètí wípé ìwọ wá lára àwọn bàbá tíó mú ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bíi olùṣọ́ ni òkúnkúndùn. Kíni iṣẹ́ẹ bàbá tí ńṣe olùṣọ́? 

  1. Ìtọ́jú - Bí àwọn olùṣọ́ tií mọ ibi tí àwọn àgùntàn wọn wà, bẹ́ẹ̀ ni àwọn bàbá ti mọ ibi tí àwọn ọmọ wọn wà . . . nípa ti ara, nípa ìbárẹ́, àti nípa ǹkan ti ẹ̀mí. 
  2. Dídarí - Olùṣọ́ máa ń mú kí àwọn àgùntàn wọn wà papọ̀ nínú agbo kan. Irú ojúṣe yìí ni àwọn bàbá pẹ̀lú ní, èyí tíó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú dídúró ti ìyàwóo rẹ̀. Àwọn àgùntàn wẹẹrẹ ò lè dúró lójúkan tí a bá jẹ́ kí àwọn àgbà méjì yìí (bàbà àti màmá) lọ ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
  3. Bíbọ́ wọn - Olùṣọ́ ni máa pèsèe púpọ̀ nínú oúnjẹ àwọn àgùntàn. Àwọn bàbá ni láti ṣe èyí fún àwọn ọmọ wọn. Kò yẹ kí bàbá tí kò m'ojúṣe rẹ̀ wà . . . pàápàá kámári láàrin àwọn bàbá tó jẹ́ Krìstẹ́nì. Ní àfikún pípèsè ohun èlòo ti ara fún wọn, àwọn bàbá ní láti pèsè ìfẹ́ àìnípẹ̀kun, tí kò sì ní ìdiwọ̀n fún àwọn ọmọ wọn, pẹ̀lú ìpèsè oúnjẹ ẹ̀mí fún wọn.
  4. Ṣe ìdábòbò - Àwọn olùṣọ́ máa ńṣe ohun tíó bá gbà láti lè jìnà ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun tí ó lè pa àwọn àgùntàn lára tàbí ṣìwọ́n lọ́nà. Àwọn bàbá á máa dáàbò bo àwọn ọmọ wọn kúrò nínú ewu tí ńbọ̀ lát'òde pẹ̀lú yíyẹ̀bá kúrò nínú pípa wọ́n lára nípasẹ̀ ìbínú, àìl'áròjinlẹ̀, tàbí àìbìkítà. 

Ọ̀pọ̀ bàbá ni yóò fi agbo ọgọ́rùn-ún dín ni oókan àgùntàn sílẹ̀ láti wá ẹyọ kan tíó nù. Ǹjẹ́ ìwọ pẹ̀lú ṣetán láti tọ́jú, darí, bọ́, àti dáàbò bòwọ́n?

Ìbéèrè: Ǹjẹ́ ìwọ ńṣe àkíyèsí tó láti mọ̀ tí ọ̀kan nínú àgùntàn rẹ bá ti ń fàsẹ́yìn

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Radical Wisdom: A 7-Day Journey For Fathers

Ó máa ń yani lẹ́nu ìwọ̀n ipa tí bàbá kó nínú irú ẹ̀yán tí a jẹ́. Kò sí ẹnì náà tó lè bọ́ lọ́wọ́ agbára àti ipáa bàbá tíó bí wọn. Nígbà tí ọ̀pọ̀ ọkùnrin kò ṣe tán láti di bàbá, ó ṣe pàtàkì fún wọn láti wá ìtọ́ni – láti inú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti lọ́dọ̀ àwọn bàbá míràn. Ọgbọ́n tó múná-dóko jẹ́ ìrìn-àjò lọ sí ipa ọgbọ́n àti ìrírí fún àwọn bàbá, nípa títẹ̀lé àwọn ìlànà àti ọgbọ́n láti inú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú ìṣúra ìrírí ọ̀kan nínú àwọn bàbá tó dàgbà jù wá lọ, tíó ti k'ọ́gbọ́n nípasẹ̀ àwọn àṣìṣe rẹ̀.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹgbẹ́ẹ akọ́ni lẹ́kọ̀ó̩ Ọgbó̩n tó múná fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: http://radicalwisdombook.com