Ọgbọ̀n tó Múná-dóko: Ìrìn-àjò Ọjọ́ Méje fún Àwọn Bàbá Àpẹrẹ

Radical Wisdom: A 7-Day Journey For Fathers

Ọjọ́ 2 nínú 7

Baba tóní Àbámọ̀ Kéréje 

Àsìkò kan wà nínú okòwò nígbà tí ètò ṣíṣe ìpinnu nípa títẹ̀lé “ìlànà ẹlẹ́sẹẹsẹ” wọ́pọ̀. Aṣe àgbékalẹ̀ àwọn ètò asìí ń tẹ́lẹ̀ èyí tíó ní súrà àṣeyọrí jùlọ nínú gbogbo rẹ̀. A maá ńṣe èyíjẹ-èyíòjẹ pẹ̀lú àwọn ohun tí à ńṣe, nírètí wípé a máa jẹ lọ́pọ̀ ìgbà.

Gẹ́gẹ́ bíi bàbá, a kò fẹ́ fi àwọn ọmọwa ta “kàlòkàlò”. Pẹ̀lú gbogbo ìgbìyànjú tí a lè ṣe, kòsí ìdánilójú wípé wọn yóò di àgbà tíó yanjú, tó sì ń tẹ́lẹ̀ Jésù. Ṣùgbọ́n a lè ṣe àwọn ìpinnu tó máa mú àbámọ̀ jìnà síwa! A lè pinu láti máṣe ohun tí yóò mú àbámọ̀ wàá lọ́jọ́ iwájú.

Ọ̀pọ̀ ọkùnrin ló ní ọgbẹ́ nípasẹ̀ àwọn bàbá tí kò kọ́ láti kó ahọ́n àti ìbínú wọn níjàánu. “Ẹ̀yin bàbá, ẹ máṣe mú àwọn ọmọ yín bínú; dípò èyí, ẹ tọ́ wọn nínú ẹ̀kọ́ àti ìlànà Olúwa.” Tóbá wá burú jù, a ní láti dákẹ́ jẹ́. Kí a kó ìdájọ́ àti ìbínú wá níjàánu. A kìí mọ wípé a ńṣeé lọ́pọ̀ ìgbà . . . àfi lẹ́yìn tó bá ká lójú wa tán.

Nígbà tawà ní kékeré a máa ń retí ọ̀rọ̀ ìgbóríyìn àti ìwúrí látọ̀dọ̀ bàbá wa, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ nínú wa ni kò jẹ àǹfààní rẹ̀. Ìyàlẹ́nu ni àwọn ọ̀nà tí ìgbéraga fi ń múwa rọpá-rọsẹ̀ jẹ́. Aò kọ̀ láti gòkè tàbí wọ gegele, àti kúrú tàbí ga kò ṣòro, ṣùgbọ́n fífi agídí pẹ̀lú ìfòyà tó ń díwa lọ́wọ́ tì, láti sọ fún àwọn ọmọwa bí a ti fẹ́ràn wọn tó ni ìjọ̀gbọ̀n ibẹ̀.

Ǹjẹ́ o ṣe tán láti ṣe gbogbo ohun tíó gbà láti tọ́ àwọn ọmọọ̀ rẹ? Ǹjẹ́ ó ńṣe ojúṣe rẹ bíi bàbá láti lè ní àbámọ̀ tíó kéré jùlọ?

Ìbéèrè: Ǹjẹ́ olè bèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run láti fihàn ọ́ ǹkan tíò lè mú àbámọ̀ tó lágbára bá ọ lọ́jọọ wájú gẹ́gẹ́ bíi bàbá? Kóo sìwá bèrè lọ́wọ́ Rẹ̀ láti fún ọ ní ìgboyà láti múu irú ǹkan bẹ́ẹ̀ balẹ̀ ní kíákíá?

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Radical Wisdom: A 7-Day Journey For Fathers

Ó máa ń yani lẹ́nu ìwọ̀n ipa tí bàbá kó nínú irú ẹ̀yán tí a jẹ́. Kò sí ẹnì náà tó lè bọ́ lọ́wọ́ agbára àti ipáa bàbá tíó bí wọn. Nígbà tí ọ̀pọ̀ ọkùnrin kò ṣe tán láti di bàbá, ó ṣe pàtàkì fún wọn láti wá ìtọ́ni – láti inú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti lọ́dọ̀ àwọn bàbá míràn. Ọgbọ́n tó múná-dóko jẹ́ ìrìn-àjò lọ sí ipa ọgbọ́n àti ìrírí fún àwọn bàbá, nípa títẹ̀lé àwọn ìlànà àti ọgbọ́n láti inú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú ìṣúra ìrírí ọ̀kan nínú àwọn bàbá tó dàgbà jù wá lọ, tíó ti k'ọ́gbọ́n nípasẹ̀ àwọn àṣìṣe rẹ̀.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹgbẹ́ẹ akọ́ni lẹ́kọ̀ó̩ Ọgbó̩n tó múná fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: http://radicalwisdombook.com