Ọgbọ̀n tó Múná-dóko: Ìrìn-àjò Ọjọ́ Méje fún Àwọn Bàbá Àpẹrẹ

Radical Wisdom: A 7-Day Journey For Fathers

Ọjọ́ 4 nínú 7

Jíjẹ Oúnjẹ-Alẹ́ Papọ̀  

Mo lè ka iye ǹkan tí ayaàmi máa ń tẹnu mọ́ pẹ̀lú àwọn ìka ọwọ́ kan. Oúnjẹ-Alẹ́ lápapọ̀ jẹ́ ọ̀kan nínúu rẹ̀.

Yóò bèrè lọ́wọ́ mi “Ìgbà wo lo máa délé?”. Èmi yóò sì fèsì pé “Iṣẹ́ pọ̀ lọ́wọ́ mi . . . óṣeéṣe kópẹ́ díẹ̀”. Láì rẹ̀wẹ̀sì, kíá óti fún mi lésì, “Ṣe kíá níbẹ̀yẹn kóo sì bọ́ sọ́nà. Nínú ẹbí yìí, a máa ńjẹ oúnjẹ-alẹ́ papọ̀. Ópẹ́jù ago mẹ́fà-àbọ̀ oúnjẹ tí délẹ̀ a sì ti wà níbi tábìlì-ìjẹun!”

Moti fẹ̀ẹ́ lójú díẹ̀, ṣùgbọ́n òtítọ́ ni ọ̀pọ̀ọ rẹ̀. Ayaàmi máa ń tenu mọ wípé ka máa jẹun papọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹbí ní alaalẹ́. Ní ìbẹ̀rẹ̀, nkò rí ìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì.

Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, pàápàá bí àwọn ọmọwa ti ń dàgbà, ni motó mọ ìdí tí àbá yìí fi ṣe iyebíye. Ó jẹ́ ìgbà kan ní gbogbo ọjọ́ tí a maá ń ríra lójú-kojú. A sì máa ń sọ̀rọ̀ nípa oríṣiríṣi ǹkan. A lè gbọ́ ẹ̀dùn-ọkàn wọn, wọ́n sì lè gbọ́ tiwa pẹ̀lú. Ànfàní lójẹ́ fún wọn láti rí bí àwọn òbíi wọn ti ń sọ̀rọ̀, ṣiṣẹ́ papọ̀, àti bí wọ́n ti fẹ́ràn ara wọn. Ọmọwa kùnrin àti obìnrin yóò jókòó láti rí bóti yẹ kí ẹbí rí.

Bí kìí ṣe n'ílé, ibo ni àwọn ọmọọ̀rẹ yóò ti kọ́ nípa ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn, ìbáṣepọ̀ nínú ẹbí, jíjẹ́ olóòótọ́, ìkáàánú, bí atií yanjú àríyànjiyàn nínú ìbárẹ́, àti ìdáríjì? Tani yóò ran wọ́n lọ́wọ́ láti gbaradì fún ìgbéyàwó àti bí a tií darí ẹbí? Nkò tíì gbọ rí bọ́yá ilé-ẹ̀kọ́ kan wà tí àti lè kọ́ni bí a ṣe lèjẹ́ ọkọ tàbí aya tó “dángájíá” tí àwọn ọmọwa tilè kọ́ ǹkan wọ̀nyí.

Ìbéèrè: Ǹjẹ́ ẹbíìrẹ máa ń jókòó papọ̀ lóórè-kóòrè? Bi araà léèrè, “Ní ogún-ọdún sí àkókò yìí, ṣé àwọn ǹkan tí wọ́n ti kọ́ níta kòní rupa iná ẹ̀kọ́-ilé?”

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Radical Wisdom: A 7-Day Journey For Fathers

Ó máa ń yani lẹ́nu ìwọ̀n ipa tí bàbá kó nínú irú ẹ̀yán tí a jẹ́. Kò sí ẹnì náà tó lè bọ́ lọ́wọ́ agbára àti ipáa bàbá tíó bí wọn. Nígbà tí ọ̀pọ̀ ọkùnrin kò ṣe tán láti di bàbá, ó ṣe pàtàkì fún wọn láti wá ìtọ́ni – láti inú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti lọ́dọ̀ àwọn bàbá míràn. Ọgbọ́n tó múná-dóko jẹ́ ìrìn-àjò lọ sí ipa ọgbọ́n àti ìrírí fún àwọn bàbá, nípa títẹ̀lé àwọn ìlànà àti ọgbọ́n láti inú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú ìṣúra ìrírí ọ̀kan nínú àwọn bàbá tó dàgbà jù wá lọ, tíó ti k'ọ́gbọ́n nípasẹ̀ àwọn àṣìṣe rẹ̀.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹgbẹ́ẹ akọ́ni lẹ́kọ̀ó̩ Ọgbó̩n tó múná fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: http://radicalwisdombook.com