Ọgbọ̀n tó Múná-dóko: Ìrìn-àjò Ọjọ́ Méje fún Àwọn Bàbá Àpẹrẹ

Radical Wisdom: A 7-Day Journey For Fathers

Ọjọ́ 5 nínú 7

Ọ̀pọ̀ kojúu Ọ̀nwọ́n

Àti tọ́ àwọn ọmọ kò rọrùn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ iṣẹ́ tó lejù lóde. Kò sí ìwé-ìtọ́ni kankan, kòsí àlàálẹ̀ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀, Ọlọ́run kò tún wá mu rọrùn nípa dídá ọmọ kàànkan pẹ̀lú ìwà tirẹ̀. Nínú ìrìn-àjò yìí, gbogbo ìlànà tío bá rí tó m'ọ́pọlọ dání; gbà á yẹ̀wò, tó bá sì ṣiṣẹ́, o lè bẹ̀rẹ̀ sí ní mulò fún ẹbíì rẹ. 

Nítorí èyí, màá ṣe àbá ìlànà kan: ṣe àgbékalẹ̀ agbègbè ọ̀pọ̀ fún àwọn ọmọ rẹ.

Àwọn ọmọdé nílò ìfẹ́ wọ́n sì ń fẹ́ẹ pẹ̀lú. Bíi ohunkóhun tó wà láyé, tí kò bá wọ́pọ̀, nígbà náà ni yóò di iyebíye àti wípé ó lèfa ìjọ̀gbọ̀n. Tóbá wà lọ́pọ̀, kòní sì wàhálà.

Ẹjẹ́ kalo epo-rọ̀bì àti iyọ̀ gẹ́gẹ́bí àpẹẹrẹ. Gbogbo orílẹ̀-èdè ló nílò epo-rọ̀bì, torí èyí ọ̀pọ̀ ló ńfi iga-gbága fún-un. Ó gbówó lórí, ó sì ṣeé ṣe kí iye yìí tún bọ̀ lọ sókè. A máa ń jà, máa ń fìgbà-kan-bọ̀kan, máa ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, a sì máa ń ta ọkàn wa fún epo-rọ̀bì yìí.

Ní ìdà kejì, iyọ̀ ṣe pàtàkì fún ìgbé-ayé ènìyàn, ṣùgbọ́n ó wọ́pọ̀ kárí ayé. Náírà díẹ̀ ma ra àpò iyọ̀ ńlá. Ó wà ní jàntí-rẹrẹ. 

Nígbà tí bàbá bá kùnà láti fàyè sílẹ̀ láti bá àwọn ọmọ lò, nígbà tí ọwọ́ọ wọn bá kún débi wípé àwọn ọmọ kò mọ ìwúlò wọn, nígbà tí ojúu bàbá kìí gbélẹ̀ àti tí kìí fìgbà kankan sí nílé láti bá wọn lò, agbègbè ọ̀nwọ́n ni èyí. 

Ṣùgbọ́n nígbà tí bàbá bá pèsè ìfẹ́ tí kò ní ìpẹ̀kun, nígbà tí ojúu bàbá bá gbélẹ̀, ìfiga-gbága máa dínkù, fífi igbá-kan-bọ̀kan máa dínkù, àti wípé àlàáfíà yóò túbọ̀ jọba nínú ilé. Bàbá ní láti wà níbẹ̀ fún wọn nípa ti ara àti ẹ̀mí.

Agbègbè ọ̀pọ̀ kìí yọjú fúnra rẹ̀, kò sì rọrùn láti ṣètò rẹ̀.

Ṣùgbọ́n tí abá tiraka fún-un, èso rẹ̀ tóbẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Ìbéèrè: Ṣe agbègbè ọ̀pọ̀ àbí tí ọ̀nwọ́n ni iléè rẹ jẹ́? Àwọn ọmọdé máa ń dàgbà bótiyẹ ní agbègbè tó ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìfẹ́. Ṣùgbọ́n tipátipá ni wọ́n fi ń dàgbà ní agbègbè ọ̀nwọ́n.

Ọjọ́ 4Ọjọ́ 6

Nípa Ìpèsè yìí

Radical Wisdom: A 7-Day Journey For Fathers

Ó máa ń yani lẹ́nu ìwọ̀n ipa tí bàbá kó nínú irú ẹ̀yán tí a jẹ́. Kò sí ẹnì náà tó lè bọ́ lọ́wọ́ agbára àti ipáa bàbá tíó bí wọn. Nígbà tí ọ̀pọ̀ ọkùnrin kò ṣe tán láti di bàbá, ó ṣe pàtàkì fún wọn láti wá ìtọ́ni – láti inú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti lọ́dọ̀ àwọn bàbá míràn. Ọgbọ́n tó múná-dóko jẹ́ ìrìn-àjò lọ sí ipa ọgbọ́n àti ìrírí fún àwọn bàbá, nípa títẹ̀lé àwọn ìlànà àti ọgbọ́n láti inú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú ìṣúra ìrírí ọ̀kan nínú àwọn bàbá tó dàgbà jù wá lọ, tíó ti k'ọ́gbọ́n nípasẹ̀ àwọn àṣìṣe rẹ̀.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹgbẹ́ẹ akọ́ni lẹ́kọ̀ó̩ Ọgbó̩n tó múná fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: http://radicalwisdombook.com