Ọgbọ̀n tó Múná-dóko: Ìrìn-àjò Ọjọ́ Méje fún Àwọn Bàbá Àpẹrẹ
Àwọn Bàbá Tó Ńtẹ̀lé Jésù
Àwọn bàbá tó ń tẹ̀lé Jésù máa ń ran ọmọ wọn lọ́wọ́ láti ní òye irú ẹni tí wọ́n jẹ́ nínú Krístì. Ǹjẹ́ ọmọ rẹ mọ̀ wípé Ọba àwọn ọba ti gbàátọ́—wípé ati dáríjìí pátápátá, ó pójú òṣùwọ̀n, àti wípé ó yẹ ní gbogbo ọ̀nà?
Nígbà tí àwọn ọmọ bá ní òye ẹni tí wọ́n jẹ́ nínú Krístì, ni wọ́n tó lè ṣe àwárí ìdánimọ̀ tíó nítumọ̀. Ìdánimọ̀ yìí yóò mu rọrùn fún wọn láti mọ ǹkan tíó tọ́ láti ṣe ní àkókò tí a bá ní ìpòrúru ọkàn, tàbí nígbà tí àwọn òbí bá fà sẹ́yìn láti ṣe ìpinnu kan.
Èrò tí yóò malọ lọ́kàn wọ́n yóò jọmọ́ “Kíni Jésù mafẹ̀ kí n ṣe?” nítorí ìdánimọ̀ wọ́n nínú Krístì ló jẹ́ ìpìlẹ̀ ẹni tí wọ́n jẹ́.
Àwọn ọ̀rẹ́ mí Craig àti Kerry ní ọmọbìnrin àgbàyanu mẹ́ta. Nígbà tí ọ̀rọ̀ bá dé oríi ìpinnu nípa àwọn aṣọ péńpé, Kerry yóò bèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ o lérò wípé aṣọ yìí tọ̀nà?” Ọ̀pọ̀ ọmọ ló máa fapá gún-rí, lérò wípé màmá wọn fẹ́ máa fọwọ́ lalẹ̀ fún wọn.
Ṣùgbọ́n àwọn ọmọbìnrin yìí ti ṣe àgbékalẹ̀ ìdánimọ̀ tiwọn . . . pẹ̀lú gbèdéke fún ohun tó tọ́ àti ìdà-kejì rẹ̀. Wọ́n tí sọ apá sílẹ̀ nínú àwọn ìjà nípa irú aṣọ tí wọ́n lè wọ nítorí wọ́n ti ní àròjinlẹ̀ fúnra wọn. “Mo mọ irú ẹni t'émi íṣe. Ènìyàn bíi tèmi kìí wọ irú aṣọ bá yẹn. Ènìyàn bíi tèmi kìí ṣe irú ǹkan bá yẹn.”
Ìbéèrè: Ǹjẹ́ ìwọ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ mafi ìdánimọ̀ ṣe àfojúsùn yín bí, tí yóò wá mú wọn dá ẹni tí wọn jẹ́ nínú Krístì mọ̀?
Nípa Ìpèsè yìí
Ó máa ń yani lẹ́nu ìwọ̀n ipa tí bàbá kó nínú irú ẹ̀yán tí a jẹ́. Kò sí ẹnì náà tó lè bọ́ lọ́wọ́ agbára àti ipáa bàbá tíó bí wọn. Nígbà tí ọ̀pọ̀ ọkùnrin kò ṣe tán láti di bàbá, ó ṣe pàtàkì fún wọn láti wá ìtọ́ni – láti inú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti lọ́dọ̀ àwọn bàbá míràn. Ọgbọ́n tó múná-dóko jẹ́ ìrìn-àjò lọ sí ipa ọgbọ́n àti ìrírí fún àwọn bàbá, nípa títẹ̀lé àwọn ìlànà àti ọgbọ́n láti inú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú ìṣúra ìrírí ọ̀kan nínú àwọn bàbá tó dàgbà jù wá lọ, tíó ti k'ọ́gbọ́n nípasẹ̀ àwọn àṣìṣe rẹ̀.
More