Ẹnití a Yàn: Rán Ara Rẹ Létí Ìhìnrere Lójoojúmọ́Àpẹrẹ
“Bí ó tí ṣe jẹ́ nìyẹn, mò ń mú gbogbo rẹ̀ wà s'ópin.”
Àtẹ̀jísẹ́ yí jáde lójú ẹ̀rọ ìléwọ́ alágbéká ọ̀rẹ́ mi Ryan láti nọ̀mbá tí ó ṣe àjèjì sí ní alẹ ọjọ ìṣẹ́gun kan ní déédéé ágogo mẹ́jọ alẹ́. O ṣẹṣẹ joko lori àga ìrọ̀gbọ̀kú lẹhin ti o fi ẹnu ko awọn ọmọ wẹwẹ rẹ l'ẹnu pé ó dì òwúrọ̀ lẹhin isẹ àṣekára òòjọ.
“Ma binu, tani eléyìí? ” o tẹ àtẹ̀jísẹ́ pada.
Sarah ni orúkọ̀ rẹ̀. Ó ríi pe òun ti tẹ àtẹ̀jísẹ́ sí nọmba ti ko tọ ó sì túúbá.
“Dúró ná” Ryan tẹ àtẹ̀jísẹ́ pada. “Mo le ṣe ìrànlọ́wọ́.”
Bí wọn ṣe ń tẹ àtẹ̀jísẹ́ sì ara wọn fún bí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú nìyìíi. Sarah sọ ìtàn ara rẹ̀ fún ún. Ó jẹ àjálù ńlá. Ọgbẹ ikẹhin ni ti abaniláyéjẹ́ ọrẹkunrin rẹ̀ tí ó fi òpin sí ìbásepọ̀ láàárín wọ́n. Ryan ń tẹ síwájú àti gbìyànjú lati jẹ ki Sarah mọ̀ nípa ifẹ Jesu ati bí ó ṣe ṣe iyebíye sí Ọlọ́run sí laibikita ohun gbogbo tí ó ń là kọjá. Ó sọ fún Sarah pé kí ó ma ṣe gbé ayé rẹ̀lórí èrò ọ̀dọ́mọkùnrin ọmọ ọdun méjìlélógún náà.
“Ó tí bọ́” o tẹ àtẹ̀jíṣẹ̀pada, “Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ dá odindi igo oògùn olóró kan jẹ ni.”
Ryan bẹ̀ẹ́ pé kí ó sọ ibiti o wa fún òun. Ó sì sọ fún pé òun àti ìyàwó òun yíò wa gbé lọ sí ilé -ìwòsàn. O sọ ibẹ̀ fun, wọn sì yara gbé lọ si ile-iwosan, nibiti awọn dokita ti ṣe itọju rẹ̀ lẹsẹkẹsẹ a sì dóòla ẹmi rẹ.
Ní àwọn oṣù tí ó tẹ̀lèe, oju Sarah bẹ̀rẹ̀ láti máà sí díẹ̀ díẹ̀ lati rí bi òun ṣe níye lórí ninu Kristi sí. Paríparí rẹ ní pé ó lọ si Ile-ẹkọ giga Kristiẹni kan lati lepa èrò Ọlọrun fun ìgbésí-ayé rẹ̀. Ọlọrun ti ràá padà; O ti gba ìgbésí-ayé ti ko wulo ní ìwòye ayé wa yí—ati pàápàá fúnrárárẹ—̀o yíì padà. Ó jẹ́ ẹni tó tóó kú fún.
Làkókò ti ọ̀rẹ́ mi kan ti n gba oyè MBA lórí ìdáwọ́lé ìdókòwò, ọ̀jọ̀gbọ́n kan nínú ọrọ-aje ti gbin ipilẹ ìmọ̀ràn kan si wọn nínú: ìdíyelé ohun kan dá lórí iye tí ẹnikan yíò san fún un.
Iye ti a san fun irapada wa ni ẹjẹ Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun. Ṣe idiyele tí ó ju èyí wá bí? Ṣe ohunkohun le jẹ ki ìdíyelé ju bayi lọ?
Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ńja ogun ojoojumọ lati gbe ìdíyelé wa lori iye ti Ọlọrun san lórí wa. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni orisi iye miran ti a ńlo lati díwọ̀n ìdíyelé wa. A ńlo iye bíì aṣeyọri, ẹbí, bí a ṣe rí wa sí, ọrọ̀, ẹ̀yà, ẹ̀kọ́ tí a ní, olórí àmúyẹ,bí a ṣe lókìkí tó, bí a tí ṣe pọ tó, "àti bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀ lọ.”
Awọn eniyan ń gbìyànjú lati fi ìdíyelé wọn hàn tabi kí wọ́n gbe nínú ibanujẹ nitori wọn lérò pé wọn ko jà mọ ńkankan.
Èyí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ipá tí ó l'ágbára jùlọ láti wàásù Ihinrere si ọkàn rẹ. O ń rán ọkàn rẹ̀ létí nípa ìdíyelé rẹ̀ nínú ninu Kristi nipa rírán ara rẹ létí ìdíyelé gíga tí a san láti rà ọ́ padà.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Kíni yíò ṣẹlẹ̀ bí o bá jí tí o sì rán ara rẹ létí ìhìnrere lójoojúmọ́? Ètò ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ -7 yìí wà láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe èyí! Ìhìnrere kò kàn gbà wá là nìkan, ó tún wà fún ìmúdúró wà ní gbogbo ọjọ́ ayé wa. Òǹkọ̀wé àti Ajíhìnrere Matt Brown ti ṣe ètò kíkà yìí láti inú ìwé ìfọkànsìn ọlọ́jọ́-30 tí Matt Brown àti Ryan Skoog kọ.
More