Ẹnití a Yàn: Rán Ara Rẹ Létí Ìhìnrere Lójoojúmọ́Àpẹrẹ

Chosen: Remind Yourself Of The Gospel Everyday

Ọjọ́ 4 nínú 7

Ìjọ kékeré kan rin ìrìn àjò ìhìnrere nígbà kan láti lọ kọ́ ilé ìjọsìn sí inú abúlé kéréje kan ní Russia. Wọ́n ńkọ́ ilé yìí pẹ̀lú òkúta tí wọ́n yọ láti ara ọgbà ẹ̀wọ̀n tí wọ́n ti kọ̀ sí lé ní ìlú Russia. Ìwòran tó lágbára ní! 

Àmójútó tó péye ni wọ́n ṣe láti dá àwọn òkúta yí sí. Nígbàtí wọ́n ń yọ ìkan nínú àwọn òkúta yìí ńlá ibẹ̀, wọ́n rí òkúta kan tí wọ́n tí gbẹ́ inú rẹ̀ tí wọ́n sì fi àdó; nínú àdó yìí ni ọ̀rọ̀ tí wọ́n sáré kọ: “Àwa ní àkójọ Krìstẹ́nì ti àwọn Òṣèlú t'Oba láṣẹ fi ipá mu láti fi òkúta ilé ìjọsìn wa kọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n níbití a ó wà títí a ó fi kú. Àdúrà wa nipé lọ́jọ́ kan àwọn òkúta yìí yóò padà di lílò láti kọ́ ilé ìjọsìn míràn.” 

Nígbàtí Krístì jíǹde nínú òkú, Ó yàn láti kọ́kọ́ fi ara Rẹ̀ han Màríà Magidalénì. Ní ìgbà náà, ẹ̀rí láti ẹnu ọmọbìnrin kò já mọ́ ńkan ní ilé ìgbẹjọ́. Ṣùgbọ́n Jésù mú obìnrin aláìní kan gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí àkọ́kọ́, Ó ń fihan gbogbo ayé ọmọbìnrin tó wá láti ìpín kékeré tí a fún ní ìròyìn ńlá jùlọ ní àgbáyé tí ó lè tẹ orí ìjọba tí ó rinlẹ̀ jùlọ ní ìtàn ọmọnìyàn ba. Nítorínà lónìí, ìjọba Ọlọ́run ń dàgbà si ní ọ̀nà ẹgbẹẹ̀gbẹ̀rún lójojúmọ́, ọkùnrin àti obìnrin ń fi ayé wọn jìn fún Krístì, nígbàtí ìjọba Róòmù wà ní ahoro.

Ìtàn Ìhìnrere jẹ́ ìtàn àwọn ènìyàn tí a kò kà sí tí wọ́n ń jẹ́rìí tí wọ́n sì ń ní ìrírí àgbàyanu agbára àjíǹde. Ìgbàkúùgbà tí ó bá ń ṣe ọ bíi aláìní àti aláìlágbára, Krístì tó jíǹde dúró ní ìmúratán láti fi agbára Rẹ̀ hàn nípasẹ̀ rẹ. Gbogbo àwọn agbọndan ayé rẹ tí ó jọ pé kòjámọ́ nǹkan kan ní ọ̀gangan ibi tí Krístì ń wá láti ṣe iṣẹ́ àmì àjíǹde míràn. 

Krístì ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ tí ó gajù lọ láàrin àwọn ènìyàn tí a kò kà sí nkankan, ní àwọn ìlú tí kò já mọ́ ńkan, ní àwọn àkókò tí ẹnikẹ́ni kò kà sí. Ọ̀pọ̀ àwọn iṣẹ́ ìyanu kò ṣẹlẹ̀ ní tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù ṣùgbọ́n ní ẹ̀bá àwọn ìgbèríko. Tí o bá wà ní ibìkan tí kò wúni lórí, ó ṣeéṣẹ kó jẹ́ ibi tó ye gan-an ló wà fún agbára àjíǹde Ọlọ́run láti bẹẹ́ sílẹ̀. 

Nígbàtí ìwọ náà bá bẹ̀rẹ̀ sí ní pín ìhìnrere pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ lójojúmọ́, oó bẹ̀rẹ̀ sí ní rí àjíǹde ní ọ̀pọ̀ ibi tó bójú mu àti ní ọ̀pọ̀ ọjọ́, ibi agbègbè, àti ènìyàn. 

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Chosen: Remind Yourself Of The Gospel Everyday

Kíni yíò ṣẹlẹ̀ bí o bá jí tí o sì rán ara rẹ létí ìhìnrere lójoojúmọ́? Ètò ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ -7 yìí wà láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe èyí! Ìhìnrere kò kàn gbà wá là nìkan, ó tún wà fún ìmúdúró wà ní gbogbo ọjọ́ ayé wa. Òǹkọ̀wé àti Ajíhìnrere Matt Brown ti ṣe ètò kíkà yìí láti inú ìwé ìfọkànsìn ọlọ́jọ́-30 tí Matt Brown àti Ryan Skoog kọ.

More

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Think Eternity fún ìpèsè ètò yíi. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ kàn sí: https://www.thinke.org