Ẹnití a Yàn: Rán Ara Rẹ Létí Ìhìnrere Lójoojúmọ́Àpẹrẹ

Chosen: Remind Yourself Of The Gospel Everyday

Ọjọ́ 3 nínú 7

Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà to fìdí mú lè jù tí a fi lè tọ́ ọkàn wa kó ní ìfẹ́ Ọlọ́run ni kí á ma wàásù Ìhìnrere fún ọkàn wa. Iye ìwọ̀n bí ọkàn rẹ bá ṣe ń rí àgbélébùú Jésù sí, bẹ́ẹ̀ náà ni ìmọ̀yi àti ibọlá fun yíò ṣe ru jáde nínú rẹ. A dá ènìyàn láti hùwà báyìí sí ìrúbọ. Tí a bá sì ròó lọ, yíò ṣòro kí á tó rí ìrúbọ míràn tí o ju èyí tí Jésù ṣe lọ. 

Tí o bá rìnrìn àjò ká gbogbo àgbáyé, gbólóhùn kan tí ò fẹ́ ẹ̀ jọ ra níbi gbogbo--ní àárín oríṣiríṣi àṣà--ni ẹsẹ̀ Bíbélì tí ó jẹ́ mí mọ̀ nínú orin Dáfídì 103:1 "Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi"

Ṣe àtúpalẹ̀ gbólóhùn yìí. Dáfídì ń kọ́ ọkàn rẹ̀ nípa wí wàásù fún. Dáfídì sọ fún ọkàn rẹ̀ bí yíò ṣe gbáà atí bí yíò ṣe hùwà sí Ìhìnrere náà: ọkàn, yin Olúwa, bóyá o fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ àbí o kọ̀. Kìí ṣe pé ó ún kọ orin dídùn; óún bá ara rè sọ̀rọ̀, ó ńṣe ìpèníja fún ọkàn rẹ̀ láti dàgbà si. Ìwé mímó ṣe àpèjúwe irú ìwà yí, bí ó ṣe sọ wípé "Dáfídì mú ara rẹ̀ lọ́kàn le nínú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀." (1 Samuel 30:6 Byo). 

Nítòótọ́ ó jẹ́ iṣẹ́ àmúyangàn Krìsténì tó ti sonú, tó jẹ́ ẹwà ìkóraẹniníjánu. Dípò kí á máa gba ìdarí láti àdà bọ̀ ohun tí à ń là kọjá lọ́wọ́lọ́wọ́, àṣà tí kò dúró déédéé, àwọn ènìyàn layiká rẹ, tabi èyí tí ó tún burú jù, lati ori Ìkànnì Ìbánidọ́rẹ̀, wo ọkàn re lójú kí o sì sọ fun pé kí ó wo àgbélébùú, kí ó sì wo àjíǹde. Pàṣẹ fún ọkàn rẹ láti mú nínú ìkáàánú Krístì, èniti Ó fi èjìká Rẹ̀ tí a yẹ̀ tí a ṣà lọ́gbẹ́ gbé ẹrù wiwo ẹ̀sẹ̀ rẹ. 

Ìgbà míràn ó ni láti fi ipá mú ọkàn rẹ láti wòó. Jòhánù Onítẹ̀bọmi pariwo jáde sí orílẹ̀ ayé "Sì wó!" tabi "Ó di dandan kí o wòó!" Ó sọ pé “Wo Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ aráyé lọ!"(Jòhánù 1:29). Àṣẹ ojojúmọ́ ni èyí. A ní láti wòó! Wo Igi àgbélébùú tí Jésù ti jìyà púpò fún ẹ̀sẹ̀ ti ko da kí ìwọ leè yọ̀ gidigidi nínú òdodo tí o kò yẹ fún. 

Ìhìnrere di oúnjẹ ojojúmọ́ fún ọkàn wa, tí ó sì mú ọkàn wá le. Ó ma ṣòro púpò láti ma ṣe àròyé, ma kẹ́dùn fún ara wa tàbí láti ma ṣe àníyàn nígbàtí ọkàn wa bá ń wo ẹ̀jẹ̀ tí ó ń sàn wá lẹ̀ láti ojú Krístì tí afi ègún ya. Ìmoore á di ohun àtọkàn wá láì fi ipá ṣe tí a bá ń ṣèyí láti òwúrọ̀ di alẹ́. 

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Chosen: Remind Yourself Of The Gospel Everyday

Kíni yíò ṣẹlẹ̀ bí o bá jí tí o sì rán ara rẹ létí ìhìnrere lójoojúmọ́? Ètò ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ -7 yìí wà láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe èyí! Ìhìnrere kò kàn gbà wá là nìkan, ó tún wà fún ìmúdúró wà ní gbogbo ọjọ́ ayé wa. Òǹkọ̀wé àti Ajíhìnrere Matt Brown ti ṣe ètò kíkà yìí láti inú ìwé ìfọkànsìn ọlọ́jọ́-30 tí Matt Brown àti Ryan Skoog kọ.

More

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Think Eternity fún ìpèsè ètò yíi. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ kàn sí: https://www.thinke.org