Ẹnití a Yàn: Rán Ara Rẹ Létí Ìhìnrere Lójoojúmọ́Àpẹrẹ

Chosen: Remind Yourself Of The Gospel Everyday

Ọjọ́ 6 nínú 7

Ní abúlé eléruku kan ní ìlú Nepal lébàá òjìji Òkè Everest, bíi ìdá ọgọ́rin nínú ọgọ́rùún àwọn ọmọdébìnrin ni wọn yíó tà sínú òwò nàbì nítorípé wọ́n jẹ́ ìsọ̀rí tó rẹlẹ̀ jù nínú ẹ̀yà tí wọn kò kà sí jù ní orílẹ̀-èdè náà, àwọn ẹ̀yà Badi. Ẹ̀sìn wọn ńkọ́ 'ni pé ní àyé àkọ́wá wọn, ó ní láti jẹ́ pé wọ́n tí ṣẹ̀ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì kí Àtunbọ̀tán tó fi ìyà jẹ wọ́n ó sì rán wọn padà sí ayé sínú ẹ̀yà tí wọn bá ara wọn. Àwọn ènìyàn kò tilẹ̀ bìkítà láti ràn wọ́n lọ́wọ́, nítorípé wọn kò fẹ́ ṣí Àtunbọ̀tán lọ́wọ́ fí f'ìyà jẹ wọ́n. Látárí èyí, àwọn ọmọdébìnrin Badi ni àwọn tó jẹ́ pé ó pọ̀ jùlọ nínú àwọn tí wọ́n maá ńtà kiri l'ágbàáyé. Ẹ̀yà tí a bí wọn sí túmọ̀ sí pé àyànmọ́ wọn ní kí á lò wọ́n ní ìlò ènìyàn lásán èkejì ajá - kí á lò wọ́n, tà wọ́n àti kí á f'ìyà jẹ́ wọ́n.

Níbí yìí gan an ni ọ̀rẹ́ mi Ryan ti pàdé Landana, ọmọdébìnrin ọmọ ọdún méwàá tó rẹwà jùlọ. Bàbá rẹ̀ ti gbà láti tàá sí ilé-aṣẹ́wó tí ará Índìa kan. Ọ̀rọ́ yìí ká ìyá rẹ̀ l'áyà tóbẹ́ẹ̀ tó fi gbìyànjú làti dènà ọkọ rẹ̀ kí ó má ta ọmọdébìnrin rẹ̀ dànù. Ṣùgbọ́n ọkọ f'árígá. Ó bẹ̀rẹ̀ síí lù ìyàwó rẹ̀ nítorípé kò fẹ́ kí óun ta ọmọdébìnrin wọn.

Nígbàtí wọ́n ṣe àwárí èyí, wọ́n gbé ìgbésẹ̀ ní kánkán pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ètò ọmọnìyàn l'ábẹ́lé àti àwọn agbófinró. Wọ́n fi Landana sí ilé ààbò níbití àwọn ọmọdébìnrin bíi tirẹ̀ tí wà ní ìpamọ́ l'álàáfìa, wọ́n ń bọ́ wọn, wọ́n sì ń f'ìfẹ́ hàn sí wọn. Landana gbọ́ nípa ìhìnrere. Ó gbọ́ nípa bí a ṣe gbà wá sínú ẹbí Ọlọ́run nípasẹ̀ Jèsù. Èyí ni ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ nínú ìhìnrere fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní agbègbè yìí ní àgbáyé.

Nígbàtí ó ń bá ọmọdébìrin Badi míràn sọ̀rọ̀ nípa ìhìnrere, ọ̀rẹ́ mi Ryan sọ fún un pé, “Ìhìnrere kọ́ wa pé àpèjá orúkọ rẹ̀ kìí ṣe Badi mọ́. Ó jọ pé orúkọ rẹ kìí ṣe Jarla Badi mọ́; Jarla ‘Krístì’ ni nítorípé o ti wà nínú ẹbí Rẹ̀, ẹ̀yà Rẹ̀ lo jẹ́ báyìí.” Ojú rẹ̀ mú ayọ̀ wá, ò sì wòó pẹ̀lú ìrètí. Ó béèrè pé “Ṣé l'óòótọ́?”. “Bẹ́ẹ̀ni, òtítọ́ tó jẹ́ òtítọ́ jù l'áyé nìyí!”

Landana fi tayọ̀tayọ̀ darapọ̀ mọ́ ẹbí Ọlọ́run, ó fi gbogbo ìtìjú ẹbí rẹ̀ sílẹ̀, ẹ̀yà rẹ̀, ìran rẹ̀. Ọlọ́run di bàbá rẹ̀, ìfẹ́ Rẹ̀ jẹ́ ìdàkejì ti bàbá tí ó fẹ́ ta ọmọdébìnrin rẹ̀. Òun ni Ọlọ́run tí Ó bìkítà láti ta ara Rẹ̀ fún ọgbọ̀n owó fàdákà láti gba ọmọdébìnrin Rẹ̀ là.

Èròńgbà ayé òde-òní wo ẹ̀sìn Krístì ó sì wòye pé, “Kíni èrèdí ẹ̀jẹ̀? Báwo ni o ṣe lè kọrin nípa ẹ̀jẹ̀ Jésù?” Ṣùgbọ́n àwọn tí a ti fi ẹ̀jẹ̀ Krístì rà mọ̀ pé ní báyìí a ṣe àjọpín ìsopọ̀ tí ó ju ti ìran wà ní ayé yìí lọ. Jésù ńpè wá sínú ẹbí titun àti àyànmọ́ titun. Ìdí nìyìí tí àwọn Krìstíẹ̀nì ṣe fẹ́ràn láti máa ronú nípa ẹ̀jẹ̀ Krístì.

Ìhìnrere yìí ju kí a wẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wa àtẹ̀yìnwá nù lọ, ó wẹ gbogbo ìtìjú ìrandíran wa, ti okùn ẹbí àti gbogbo mọ̀lẹ́bí wa nù. O kìí ṣe ara ẹbí ti ayé nìkan mọ́; o ti darapọ̀ mọ́ ẹbí ti ọ̀run. Ẹ̀jẹ̀ Jésù dá ọ yàtọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ẹbí fún ayérayé. A ní ìdánimọ̀ ẹbí titun, àpèlé ẹbí titun, arákùnrin àti arábìnrin titun, àti àpèjá orúkọ titun.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 5Ọjọ́ 7

Nípa Ìpèsè yìí

Chosen: Remind Yourself Of The Gospel Everyday

Kíni yíò ṣẹlẹ̀ bí o bá jí tí o sì rán ara rẹ létí ìhìnrere lójoojúmọ́? Ètò ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ -7 yìí wà láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe èyí! Ìhìnrere kò kàn gbà wá là nìkan, ó tún wà fún ìmúdúró wà ní gbogbo ọjọ́ ayé wa. Òǹkọ̀wé àti Ajíhìnrere Matt Brown ti ṣe ètò kíkà yìí láti inú ìwé ìfọkànsìn ọlọ́jọ́-30 tí Matt Brown àti Ryan Skoog kọ.

More

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Think Eternity fún ìpèsè ètò yíi. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ kàn sí: https://www.thinke.org