Ẹnití a Yàn: Rán Ara Rẹ Létí Ìhìnrere Lójoojúmọ́Àpẹrẹ

Chosen: Remind Yourself Of The Gospel Everyday

Ọjọ́ 1 nínú 7

Kíní yíò ṣẹlẹ̀ bí o bá jí, tí o sì ń rán ara rẹ létí nípa Ìhìnrere lójoojúmọ́? 

Bí o bá dà bí èmi, ó lè máa ṣe ọ́ bíi pé kó o máa ka Ìhìnrere sí ohun tí kò já mọ́ nǹkan kan, kí o sì má ṣe ìpalẹ̀mọ́ fún mọ́ torí pé ó ti wá di ohun tí o mọ̀ dáadáa. A máa ń kọọ́ sínú ìtàn wa kan tí ó ti kọjá, a sì máa ń gbìyànjú láti gbé ìgbéayéwa lọ. Ṣùgbọ́n a nílò láti gbọ́ gbogbo ìpele Ìhìnrere lónìí bíi ti ìgbà tá a kọ́kọ́ gbọ́ ọ. 

Tí a bá ń rán ara wa létí Ìhìnrere lójoojúmọ́, a óò jí, a ó sì máa láyọ̀ pé a ti borí ogun tó le jù lọ tí a lè bá pàdé lónìí. 

Báwo ni ìgbésí ayé rẹ ṣe máa yàtọ̀ tó bí o bá ń wàásù Ìhìnrere náà déédéé sí oókan-àyà rẹ? 

Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni Ìhìnrere ń gbà nípa rere tó sì ń tún wa mọ lórí ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́. Gbogbo wa la nílò àwọn ìránnilétí déédéé nípa àwọn àǹfààní wọ̀nyí, a sì nílò agbára Ọlọ́run láti túbọ̀ lóye wọn. 

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn onígbàgbọ́ ló rò pé ìròyìn rere yìí ti di ìròyìn àtijọ́. A ò tíì gbọ́ Ìhìnrere jù; a ò tíì gbọ tó. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ìkọgun ẹwà dáyámọ́ǹdì, bẹ́ẹ̀ náà ni Ìhìnrere ní ẹwà tí kò lópin, tí kò lè tán láé. Bí a bá ṣe ń jinlẹ̀ si nínú Ìhìnrere, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe máa ní ágbára síi àti ìfọkànbalẹ̀ si nínú ìgbàgbọ́ wa a. 

A nílò àwọn ìránnilétí déédéé nípa ohun gbogbo tí Ọlọ́run ti ṣe fún wa nínú Ìhìnrere, nítorí pé Ìhìnrere ń fún wa lókun ó sì ègbọràn sí Ọlọ́run ká sì máa sìn ín. Nígbàtí a bá rí Oun tó ti ṣe - ọ̀pọ̀ oun ti Ó fi fún wa nínú Ọmọ Rẹ̀ - a kò lè ṣe àyàfi láti yí padà, ká sì gbà ìyànjú láti fi gbogbo ìgbésí ayé wa fún un. Àti pé bí a tilẹ̀ jẹ́ aláìlera àti ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò lágbára, tí à ń tiraka láti tẹ̀lé Olùgbàlà pípé, Ìhìnrere rán wa létí bí a ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó àti bí Ọlọ́run ṣe ń ṣiṣẹ́ nínú wa láti ràn wá lọ́wọ́ láti lè tẹ̀lé E. 

Kò sí ohun tó ṣe pàtàkì jù nínú ìgbésí ayé rẹ bíi Kristẹni ju pé kí o máa rán ọkàn rẹ létí òtítọ́ Ìhìnrere déédéé. 

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Chosen: Remind Yourself Of The Gospel Everyday

Kíni yíò ṣẹlẹ̀ bí o bá jí tí o sì rán ara rẹ létí ìhìnrere lójoojúmọ́? Ètò ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ -7 yìí wà láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe èyí! Ìhìnrere kò kàn gbà wá là nìkan, ó tún wà fún ìmúdúró wà ní gbogbo ọjọ́ ayé wa. Òǹkọ̀wé àti Ajíhìnrere Matt Brown ti ṣe ètò kíkà yìí láti inú ìwé ìfọkànsìn ọlọ́jọ́-30 tí Matt Brown àti Ryan Skoog kọ.

More

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Think Eternity fún ìpèsè ètò yíi. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ kàn sí: https://www.thinke.org