Ẹnití a Yàn: Rán Ara Rẹ Létí Ìhìnrere Lójoojúmọ́Àpẹrẹ

Chosen: Remind Yourself Of The Gospel Everyday

Ọjọ́ 5 nínú 7

p>Mo fẹ̀rẹ̀ sọ ìwé náà silẹ nígbàtí mo ká ìtumọ̀ tí David Bentley Hart fún ọ̀rọ̀ "ibukun" tí ó wà nínú Bíbélì. Ọ̀mọ̀wé olókìkí ni sọ nípa bí ọrọ ìbùkún yí ṣe pàdánù ìtumọ̀ ọrọ yí nípasẹ̀ àṣà wá: bí ó ṣe ló nipe díẹ̀ sì tàbí kéré sì ó yẹ kí ó jẹ "orí-irè" tàbí ohun tí ó "já sí ayọ̀". Dípò èyí, Hart ṣe àríyànjiyàn pe itumọ gidi yíò sunmọ ọrọ wa ti o ni idunnu tàbí fún wa ní ayọ̀.

< p > Eyi ni ohun ti Ọlọrun ti ṣe fun wa ninu ihinrere: O ti fun wa ni gbogbo ibukun ayeraye ti a foju sún de ibi pé a kun fun ayọ! < / p > < p > Ohun tí a ń yàn lójojúmọ́, bí a ṣe ń bá ara wa jà, idanwo tí a ń kojú já si boya tabi rárá lati ranti, mọ, ati gbe nínú otitọ yí.

< p > Ati pe ko da lori awọn àyè tí a wà. Kìí ṣé bẹ́ẹ̀ rárá. Ọ̀dọ́mọkùnrin kan, tí a pé ní Meisha kọ mi ni ọna ti èmi ki yíò gbàgbé lailai
< / p > < p > Meisha jẹ ẹniti o sá àsálà kúrò ni orilẹ-ede tí ogun ti kó lọ. Abule rẹ ati gbogbo ohun ti o ti mọ tẹlẹ ni o parun nipasẹ ológun aninilára, o si fi agbara mu lati jẹ adènà, ó sì rù awọn erù jagunjagun gba inú igbó kìjikìji kan lákókò ti o bojú wolẹ̀ ti o rí ọpá ibon — bí ni àsìkò tí Jesu nigbati ọmọ ogun Romu kan fi agbara mu eniyan lati gbe ẹrù rẹ fun ibùsọ̀ kan. < / p > < p > Ọjọ́ kan ọmọ ogun kan fi agbara mu Meisha tìbọntìbon láti tú àgbá olóró tí a ri mọlẹ. Àgbá náà bú gbàmú. Meisha sì padanu ọwọ méjèèjì ati oju méjèèjì lẹ́sẹ̀kẹ́sẹ̀. Wọn fi silẹ nibẹ, ni ero pe o ti ku, ṣugbọn ko ku. < / p > < p > Lẹ́hìn ẹ̀yìnorẹ̀yìn, ẹnikan ṣe alábápín ìtàn ìjìyà tí Olugbala pẹ̀lú rẹ (Meisha) O ṣe idanimọ pẹlu Ọlọrun kan ti o mọ irora rẹ. Ìyípadà ògo sì dé bá igbe ayé rẹ̀.

< p > Meisha ní ayọ púpọ̀ tí ó sì mú orí rẹ̀ yá nipa Ihinrere pe o ni ki awọn eniyan mu òun lati ibùdó àsálà kan si ìkejì ki o le pin Ihinrere pẹ̀lú àwọn ti ko tíì gbọ nipa Jesu. < / p > < p > Ayọ Meisha jẹ ohun tí ó ń tàn káàkiri. Inu rẹ dun rékọjá ọpọlọpọ eniyan ti o ríran, tí ó sì ni ọwọ mejeeji, ati pe ko gbe ninu iwalaaye òtòṣì ni ibudo àsálà kan. Ayọ rẹ bù jade nípa ìmoore rẹ fun agbelebu. Meisha mọ pé ni igba diẹ sì òun yíò wa pẹlu Kristi títí lai. < / p > < p > Meisha ṣe àpẹẹrẹ eyi nipa fifa ayọ Ìhìnrere yọ ni àárin ibudó àsálà kan. O ṣe agbekalẹ awọn iwe ti Aposteli Paulu kọ̀, ẹniti o sọ pe, “Ìpọ́njú wá tí ò fẹ̀rẹ̀, tí ìṣe fún ìṣẹ́jú kàn, ó ń ṣiṣẹ́ ògo àìnípẹ̀kun tí ó pọ̀ rékọjá fún wá ” ( 2 Korinti 4:17). < / p >

Idagbasoke

 

Bọtini: ọjọ_5

ọjọ_5

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 4Ọjọ́ 6

Nípa Ìpèsè yìí

Chosen: Remind Yourself Of The Gospel Everyday

Kíni yíò ṣẹlẹ̀ bí o bá jí tí o sì rán ara rẹ létí ìhìnrere lójoojúmọ́? Ètò ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ -7 yìí wà láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe èyí! Ìhìnrere kò kàn gbà wá là nìkan, ó tún wà fún ìmúdúró wà ní gbogbo ọjọ́ ayé wa. Òǹkọ̀wé àti Ajíhìnrere Matt Brown ti ṣe ètò kíkà yìí láti inú ìwé ìfọkànsìn ọlọ́jọ́-30 tí Matt Brown àti Ryan Skoog kọ.

More

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Think Eternity fún ìpèsè ètò yíi. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ kàn sí: https://www.thinke.org