Ẹnití a Yàn: Rán Ara Rẹ Létí Ìhìnrere Lójoojúmọ́Àpẹrẹ

Chosen: Remind Yourself Of The Gospel Everyday

Ọjọ́ 2 nínú 7

Ryan, ọ̀rẹ́ mi sọ ìtàn ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọ̀gbẹ́ni Bi t'ó jẹ́ olùkọ́ àgbà ní Yunifásítì Beijing, tí a mọ̀ sí "Harvard ti China" fún mi. Ọkùnirin yìí ṣe àwàdà kan pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan nínú kílásì rẹ̀ nípa ẹgbẹ́ òṣèlú Kọ́múnìstì. Ọ̀kan nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí lọ ròyìn àwàdà náà fún àwọn ọlọ́pàá. Lọ́jọ́ kejì àwọn ọlọ́pàá já wọ inú ọ́fíìsì Ọ̀gbẹ́ni Bi wọ́n sì gbé e, ó di inú ẹ̀wọ̀n nílùú kan tó jìnnà, ẹ̀wọ̀n àwọn Kọ́múnìṣti t'ó m'ótùtù - láì kìlọ̀ fún un, láì gbé e lọ sílé ẹjọ́. 

Ó jí láàárọ̀ ọjọ́ t'á ń wí yìí gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ àgbà tó ń ṣe adarí ọ̀kan nínú àwọn ipò t'ó níyì jùlọ ní gbogbo àgbáyé. Ìgbà tí yóó fi d'àṣálẹ́, ó ti wà ní àtìmọ́lé lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Ní àṣikò yìí, àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n China wà lára àwọn ibi t'ó burú jù láyé - wọ́n jẹ́ ilé àìsàn, ìninilára, àti ikú. Kò pẹ́ tí Ọ̀gbẹ́ni Bi fi sọ ìrètí nù tí ìrẹ̀wẹ̀sì sì dé bá a. Lẹ́hìn ọ̀sẹ̀ dí ẹ̀, ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn mú kí ó bẹ̀rẹ̀ sí ronú láti gb'ẹ̀mí ara rẹ̀. Lọ́sàn ọjọ́ kan, nínú àwọsánmà ìbànújẹ́, ó lọ sí ojú fèrèsé túbú rẹ̀ tí ó wà lórí àjà kẹjọ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. Àwọn ará China kì í fi fèrèsé sí àwọn túbú tó wà ní àwọn àjà òkè. Bí ẹlẹ́wọ̀n kankan bá fẹ́e kú nípa bí bẹ́ sílẹ̀ láti ibẹ̀, kò burú.

Ọkàn Ọ̀gbẹ́ni Bi bẹ̀rẹ̀ síí sáré túpetúpe bí ó ṣe wo ìta t'ó sì ronú pé kí òun bẹ́ sílẹ̀. Nígbà náà ni ó ṣẹlẹ̀. Ó gbọ́ ohùn kékeré kan tí ó sọ pé, "Má lọ. Má lọ. Má lọ." Ó bá jókò kalẹ́ láàrin túbú rẹ̀ láìnírètí 

Lórí ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀ tó jókò sí yìí ni iyè rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ síí jí sí àwọn nnkàn tí ó ti gbàgbé. Ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan tí ó jẹ́ ọmọ ìlú òkèèrè, olùkọ́ àgbà àti ọmọlẹ́hìn Krístì ti wàásù Ìhìnrere fún un. Ọ̀gbẹ́ni Bi bá gbàdúrà, "Jésù t'ó bá jẹ́ pé òtítọ́ lo wà, fún mi ní ìdáríjì àti àlàáfíà tí ọ̀rẹ́ mi sọ pé o ti ṣe ìlérí rẹ̀. Ní pàṣípààrọ̀, èmi yóò fi ayé mi àti iṣẹ́ mi jìn ọ́.” 

Ó b'ojú w'òkè, "Àwọ̀ sánmọ̀n kò já gaara tó báyì rí bẹ́ẹ̀ ni òòrùn kò mọ́lẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ rí láti ojú fèrèsé, ayọ̀ kún inú ọkàn mi ju bí mo ṣe mọ̀ tẹ̀lé lọ.” 

Gbajúgbajà olùkọ́ àgbà yìí kò b'èṣù bẹ̀gbà, ó pariwo "Ọjọ́ ọ̀la mi dára nínú Krístì!" Àwọn ẹ̀ṣọ́ gbọ́ ariwo rẹ̀ wọ́n sì fi tìkàtìkà sọ fún un pé k'ó dákẹ́. Ṣùgbọn kò lè pa ayọ̀ rẹ̀ mọ́ra. Ó tẹ̀síwájú láti máa pariwo ọ̀rọ̀ kanná títí tí wọ́n fi wá nà án mọ́ inú túbú rẹ̀. 

Ẹnìkan tí a tú sílẹ̀ nípa gbígba Ìhìnrere Jésù gbọ́ bí ó tilẹ̀ wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n ní òmìnira ju ẹni tí kò sí lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ṣùgbọ́n tí kò mọ Ìhìnrere Jésù lọ. 

Nígbẹ̀hìn, wọ́n dá Ọ̀gbẹ́ni Bi sílẹ̀ kúrò lẹ́wọ̀n ó sì dá àwọn ilé ọmọ aláìníyàá sílẹ́ káàkiri inú ìgboro China, níbi tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn aláìní t'ó sì n fi ọ̀nà Krístì han ọ̀pọ̀lọpọ̀. Ó ní ọjọ́ ọ̀la tó dára nínú Jésù Krístì. Títí di òní, ayọ̀ rẹ̀ kò lè má ràn ọ́ tí o bá pàdé rẹ̀. Yóó sì sọ fún ọ pé ayọ̀ òun lónìí kò dínkù sí eléyìí tí òun ní nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n 

Nígbà míràn gbogbo ènìyàn náà l'ó máa ń ní ìmọra pé àwọ́n wà nínú ẹ̀wọ̀n àfọwọ́fà - híhá sínú pampẹ́ ìwà, ìṣe, àti ọ̀rọ̀ àná tí kò tú wọn sílẹ̀. 

Ìhìnrere fi yé wa pé ẹ̀wọ̀n tó burú jù ni ẹ̀wọ̀n eléyìí tí a ju ara wa sí. Kọ́kọ́rọ́ tí a fi ti àwọn túbú yìí ni èrò wa pé kò sí ààbò, pẹ̀lú ìmọ̀lára nínú wa pé nnkan kò rí b'ó ṣe yẹ k'ó rí, wípé nnkan kan ti bàjẹ́. A máa ń gbé èyíi káàkiri bí ẹ̀wọ̀n ti a so m'ọ́rùn. Ipò tí ènìyàn wà nìyíi.

Àfi tí nkan ńlá kan bá ṣẹlẹ̀ ni èyi lè fi yípadà.. 

Ìhìnrere ni ọ̀nà gbòógì náà. Àgbélébù ẹlẹ́jẹ̀ ni. Ikú Ọlọ́run fúnrarẹ̀ nítorí wa. Ó jẹ́ gbígbé ikú fúnrarẹ̀ wọ́nlẹ̀ nípa ìṣẹ́gun ti àjínde láti fi ìfẹ́ Ọlọ́run àti agbára Rẹ̀ hàn títí ayérayé.

Bíbélì ń rán wa létí pé kí á fiyèsí nkan tí a ti gbọ́, pàápàá jù lọ èyí t'ó jẹ mọ́ Ìhìnrere (Hébérù 2:1). Ìwàásù tó ṣe pàtàkì jù ni èyí tí o wà sí ọkàn ara rẹ, tí o fi ń rán ọkàn rẹ létí pé "Ọjọ́ ọ̀la mi dára nínú Jésù Krístì”

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Chosen: Remind Yourself Of The Gospel Everyday

Kíni yíò ṣẹlẹ̀ bí o bá jí tí o sì rán ara rẹ létí ìhìnrere lójoojúmọ́? Ètò ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ -7 yìí wà láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe èyí! Ìhìnrere kò kàn gbà wá là nìkan, ó tún wà fún ìmúdúró wà ní gbogbo ọjọ́ ayé wa. Òǹkọ̀wé àti Ajíhìnrere Matt Brown ti ṣe ètò kíkà yìí láti inú ìwé ìfọkànsìn ọlọ́jọ́-30 tí Matt Brown àti Ryan Skoog kọ.

More

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Think Eternity fún ìpèsè ètò yíi. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ kàn sí: https://www.thinke.org