Ètò Olúwa Fún AyéèÀpẹrẹ

God’s Plan For Your Life

Ọjọ́ 1 nínú 6

Ètò Ọlọ́run lè má rújú bí ó ti lérò.

Ǹjẹ́ ìwọ ti gbọ rí wípé Ọlọ́run “ní ètò fún ayéè rẹ”? Lọ́pọ́ ìgbà, àwọn òbí wa tàbí àwọn tó jù wá lọ máa ń sọ̀rọ̀ nípa ètò Ọlọ́run láti fún wa ní ìwúrí, ṣùgbọ́n bí a kó bá ní tan'ra wa jẹ, nígbà míràn ìpáyà ọkàn ní máa ń kó bá wà! Ṣùgbọ́n ohun tó ṣe pàtàkì ni: ètò Olúwa kò rújú bí ó ti lérò. 

Nínú májẹ̀mú láíláí, ní ìtàn ọmọkùnrin kan tí ń jẹ́ Ábrámù wà. Jẹ́nẹ́sísì 12:1 ṣe àkọọ́lẹ̀ rẹ wípé Olúwa sọ fún Ábrámù kí ó kúrò ní ìlú ìbí rẹ̀, kí ó lọ sí ibi tí Ohun yóò fi hàán. Kí ènìyàn fi ìlú ìbí rẹ àti ilé rẹ sílẹ̀, láti lọ sí ibi tí kò mọ̀ rárá? Èyí tó banilẹ́rù! Síbẹ̀ nínú Jẹ́nẹ́sísì 12:4, a kọọ́ wípé “… Ábrámù dìde láti lọ bí Ọlọ́run ti tọ́ọ …” 

Olúwa ó fìgbà kankan sọ bí ohun gbogbo yóò ti lọ fún Ábrámù. Ọ̀pọ̀ ìbéèrè tí ó wà ní ọkàn Ábrámù li a fi sílẹ̀ láì dáhùn. Dípò ìdáhùn, ní ṣeni Olúwa ń fún Ábrámù ni ìtọ́ni nípa ìgbéṣẹ̀ kàǹkaǹtí Ó fẹ́ kó'gbé.

Ju gbogbo rẹ̀ lọ: Nítorí ìgbọràn rẹ̀, Olúwa padà yí orúkọ sì Ábúráhámù, èyí tí ó túnmọ̀ sí “bàbà fún ọ̀pọ̀ ènìyàn.” Ábúráhámù sì wá padà di bàbá ńlá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè! Kódà, orúkọ Ábúráhámù wá nínú àwọn akọni ìgbàgbọ́ tí a ṣe àkọsílẹ̀ rẹ nínú Hébérù 11. Eyi dára, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? 

Ábrámù jẹ́ àpẹrẹ tí ó tayọ ti ènìyàn tó gbé ìgbé ayé ìgbàgbọ́—pẹ̀lú bí gbogbo ètò Olúwa fún ayéè rẹ̀ kò ti yée. Lóòótọ́ kò pé, ṣùgbọ́n kìkìdá ìgbọràn sì Olúwa ni ayéè rẹ̀ jẹ́, bí kò tilẹ̀ yée tààrà. 

Nítorí náà, tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ètò Olúwa fún ayéè wa, ìṣe Olúwa nìyẹn lọ́pọ́ ìgbà—kíkọ sí wa làti'nú Ọ̀rọ̀ọ rẹ̀ (Bíbélì) pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà fún gbogbo ìgbésẹ̀ wa kàànkan. Ètò Olúwa kò jù báyìí lọ. Ó jẹ́ àwọn ìṣísẹ̀ tí à ń gbé ní ìgbọràn sì Olúwa. 

Orin Dáfídì 119:105 sọ wípé ọ̀rọ̀ Olúwa jẹ̀ àtùpà fún ẹsẹ̀ wa àti Ìmọ́lẹ̀ sí ipasẹ̀ wa. Ẹsẹ̀ Bíbélì yìí kò sọ̀rọ̀ nípa àtùpà tí à ń lò nínú yàrá tí maá mọ́lẹ̀ sì gbogbo ilé. Dípò èyí, ẹsẹ̀ Bíbélì yìí ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí a lè pè ní àbẹ́là kékeré. Kò ní mọ́lẹ̀ lọ títí—bí kò ṣe láti rí ẹsẹ̀ bàtà díẹ̀ níwájú ẹni dìímú. Bíi ìgbà tí a bá wọnú yàrá tó ṣókùnkùn birimù pẹ̀lú iná kékeré ni yóò rí —o kò lè rí ju ẹsẹ̀ bàtà díè níwájú. 

Bíi Ábrámù, Olúwa kò ní fi bí ohun gbogbo yóò ti lọ láyé wá hàn sí wa. Bí Ó bá ṣe èyí, a kò ní nílò láti gbé ìgbé ayé ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Rẹ! Dípò èyí, Olúwa fẹ́ máa t'ipasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti àwọn ọmọ-lẹ́yìn Krístì tó ṣeé gbẹ́kẹ̀lé kọ sì wa fún ohun tí ó kàn—l'ẹ́sẹẹsẹ. 

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

God’s Plan For Your Life

Kíni ètò Olúwa fún ayéè rẹ? Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè tí a maá ń bèrè gẹ́gẹ́ bíi ọmọ-lẹ́yìn-Kristi. Ṣùgbọ́n, tí a bá ma jẹ olóòótọ́, ìrònú wa nípa ètò Olúwa fún ayé wa lè lágbára ju ọgbọ́n orí wa lọ. Nínú ètò Bíbélì ọlọ́jọ́-mẹ́fà yìí, a ó kọ́ọ wípé ètò Olúwa kò le bí a ti lérò, ṣùgbọ́n ó dára ní gbogbo ọ̀nà ju bí a ti lérò

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹgbẹ́ Switch, ẹ̀ka iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ìjọ Life.Church, fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: www.life.church