Ètò Olúwa Fún AyéèÀpẹrẹ

God’s Plan For Your Life

Ọjọ́ 4 nínú 6

Àwọn ìlànà ètò mẹ́ta, tí kò l'àkọsílẹ̀ 

Gba èyí rò: O ra ẹ̀wù titun kan èyí tío lérò láti wọ̀ lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ kí àwọn akẹgbẹ́ rẹ bá lè rí ẹwà rẹ̀. O ṣètò ohun gbogbo tío fẹ́ wọ̀ lọ́jọ́ náà bíi afínjú. N'íbi tío tí ń jẹ oúnjẹ-ọ̀sán lọ́jọ́ náà, ni wàhálà bá bẹ́ sílẹ̀ tragedy strikes: o já epo sí ara ẹ̀wù titun tío wọ̀—èyí tún wá ṣẹlẹ̀ nígbà tí ẹni tío ti ń bẹjú wò fún ọjọ́ pipẹ́ ti ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ.

Nígbà míràn, ìgbésí-ayé wa kìí lọ bí a ti ṣètòo rẹ̀.

Nínú Bíbélì, l'ati rí ìtàn nípa ọmọkùnrin kan tí ń jẹ́ Gídíónì. Gídíónì wá láti agbolé tío lẹ jù ní ìlu Mánásè àti wípé ebíi rẹ̀ ni ó lẹ jù ní agbolé yìí. Kò tilẹ̀ dà bíi ènìyàn tí Ọlọ́run lè yàn. Nígbà tó yá, Ọlọ́run daríi Gídíónì láti dìde ogun sì Mídíánì, ẹ̀yà kan tó lòdì, pẹ̀lú ọmọ-ogun ẹgbẹ̀rún méjìdínlógójì. Lẹ́yìn èyí, ní Ọlọ́run sọ fún Gídíónì wípé àwọn ọmọ-ogún ẹyìn rẹ̀ ti pọ̀jù, tí wọ́n bá sì borí àwọn ara Mídíánì, yóò dàbi wípé ipá wọn ló gbà wọ́n. Nítorí èyí, Gídíónì dá àwọn ọmọ-ogun ẹgbẹ̀rún-lọ́nà-ogún padà sílé. Ọlọ́run sọ fún un wípé wọ́n ṣì pọ̀ síbẹ̀, ní ìparí, ọ̀ọ́dúǹrún ọmọ-ogun l'ókù pẹ̀lú Gídíónì. Olúwa mú kí Gídíónì àti Ísírẹ́lì borí Mídíánì pẹ̀lú ọmọ-ogun ọ̀ọ́dúǹrún péré—èyí tíó dájú wípé kò sì nínú ètò Gídíónì.

Nígbà tí a bá ń ronú nípa ọjọ́ọ-wájú àti ohun tí Ọlọ́run ti pèsè sílẹ̀ fún wa, ó ṣe pàtàkì fún wa láti rántí wípé gbogbo ìgbà kọ́ ni ǹkan máa ń lọ bí a tí ṣètò rẹ̀. 

Kódà, àwọn ìlànà mẹ́ta tí kò ní àkọsílẹ̀, tí o nílò láti tẹ̀lẹ́: 

1.) Múra láti padà sí ìbẹ̀rẹ̀. Onírúurú ǹkan l'ènìyàn má bẹ̀rẹ̀ n'ìgbésí ayéè rẹ̀. Ní kété tío bá parí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ̀bẹ́rẹ̀, àsìkò tó fún ilé-ẹ̀kọ́ girama. Nígbà tí eéwo ilé-ẹ̀kọ́ girama bá fẹ́rẹ̀ẹ́ tú, ilé-ẹ̀kọ́ gíga náà yóò yọjú pẹ̀lú ìgbáradì fún bíbọ́sí ipò ojúlówó àgbà. Òtítọ́ ibẹ̀ ni wípé, kò sí òpin rẹ̀. Kọ́ bí atií padà sí ìbẹ̀rẹ̀. Nígbà tí ètò bá yí bírí, gbìyànjú láti yí pẹ̀lú rẹ̀. O kò lè sọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ mú jáde. Se gírí ní ipòkípò tí o bá b'áraà rẹ.

2.) Múra láti s'ọpé rárá. Nígbà míràn, a ní láti sọ wípé “rárá” sí àwọn ǹkan dídára kí a lè ṣe “bẹẹni” sí àwọn ohun tí ó dára jùlọ. A kò lè ṣe ohun gbogbo. Gbàdúrà fún ọgbọ́n àti mọ àwọn ohun tíó lè lo àkókò rẹ fún, láti ní ipa tí ó tóbi jù fún ìjọba Ọlọ́run.

3.) Múra láti s'àgbékalẹ̀ ǹkan titun. Àwọn ètò Ọlọ́run, nígbà míràn a máa mú wa lọ sí ipasẹ̀ tí a kò lérò. Fún Gídíónì, èyí túmọ̀ sí lílo ohun tí ó ní—ìkòkò amọ̀ pẹ̀lú iná nínú dípò àwọn ohun ìjà ogun. Lo ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún ọ lónìí. Má yo'raà rẹ lẹ́nu nítorí ẹ̀bùn àwọn míràn. Fi yé araà rẹ wípé ohun tí Ọlọ́run fi fún ọ, pẹ̀lú ìrànwọ́ rẹ̀ wúlò ju bí o ti lérò. 

Day 3Day 5

Nípa Ìpèsè yìí

God’s Plan For Your Life

Kíni ètò Olúwa fún ayéè rẹ? Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè tí a maá ń bèrè gẹ́gẹ́ bíi ọmọ-lẹ́yìn-Kristi. Ṣùgbọ́n, tí a bá ma jẹ olóòótọ́, ìrònú wa nípa ètò Olúwa fún ayé wa lè lágbára ju ọgbọ́n orí wa lọ. Nínú ètò Bíbélì ọlọ́jọ́-mẹ́fà yìí, a ó kọ́ọ wípé ètò Olúwa kò le bí a ti lérò, ṣùgbọ́n ó dára ní gbogbo ọ̀nà ju bí a ti lérò

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹgbẹ́ Switch, ẹ̀ka iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ìjọ Life.Church, fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: www.life.church