Ètò Olúwa Fún AyéèÀpẹrẹ
Báwo li o tií mọ ètò Ọlọ́run fún ayéè rẹ?
Tí o báti súré ìje rí, o máa mọ̀ wípé ó ṣe pàtàkì láti máa sáré bóti yẹ. Bí o bá sáré oní-jẹ̀lẹ́nkẹ́, kíá loó d'eni ẹ̀yìn tí àwọn akẹgbẹ́ rẹ yóò sì ṣáájú rẹ. Bí o sì tún sáré ní wùrù-wùrù, óṣeéṣe kó tètè rẹ̀ ọ́, kí o sì málè parí ìje náà.
Àti mọ bí a ó ti sáré sì nínú ìje lè má rọrùn. Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni f'Ọlọ́run, wípé nínú ìrìn-àjò wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, a ní ẹni tíí tọ́ wa.
Gálátíà 5:25 sọ wípé kí a máa “gbé ní ìbámu pẹ̀lú Ẹ̀mí kí a sì máa tẹ̀lé ìtọ́ni Ẹ̀mí.”
Tí abá ní láti máa tẹ̀lé ìtọ́ni Ẹ̀mí, èyí túmọ̀ sí wípé Ẹ̀mí mímọ́ ni yóò kọ́wa bí a tií sáré. Aò gbọ́dọ̀ wà lẹ́yìn tàbí jálọ níwájú—a ní láti sáré pẹ̀lú ìtọ́ni.
Nígbà tí a bá wà ní ìtọ́ni pẹ̀lú Ẹ̀mí, Òhun yóò pèsè ìmọ̀ láti tọ́ ìpínnu wa. Òwe 3:6 sọ wípé nígbà tí a bá jọ̀wọ́ ara wa fún Òhun, Yóò tọ̀ ìṣísẹ̀ wa láti mu já geere.
Tí a bá gbe yẹ̀wò, èyí dùn jẹ lẹ́nu. Ṣùgbọ́n báwo laó ti ṣé láì tan r'awa láti máa tẹ̀lé ìtọ́ni Ẹ̀mí?
Ọ̀nà mẹ́ta t'afi lè bẹ̀rẹ̀ nìyí:
1.) Wá Ọlọ́run nínú Òrọ̀ọ Rẹ̀. Wípé o tilẹ̀ ń ka ètò Bíbélì yìí, ti fi hàn wípé ẹsẹ̀ rẹ ti wà ní ipasẹ̀ tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀! Ṣeé l'ójúṣe rẹ láti máa ka ọ̀rọ̀ Ọlọ́run l'ójojúmọ. Oríṣiríṣi ètò Bíbélì ló wà fún ọ láti bẹ̀rẹ̀, tí ìrẹ̀wẹ̀sì àti ṣe irú ǹkan yìí kò bá jìnà síọ, wá ènìyàn bíi mélòó kan mọ́ra!
2.) Gbàdúrà lóòrè-kóòrè. Máse jẹ́kí bí ètò àdúrà yìí yóò ti lọ fẹjú mọ́ọ. Àdúrà rọrùn nítorí ó jẹ́ ọ̀nà tí a fií bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, àti tí a fií tẹ́tí Síi. Tí ó bá rọrùn fún ọkàn rẹ láti ṣáko (bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá ti máa ṣe), yóò ṣe ọ́ l'ànfàní tío bá ṣe àkọsílẹ̀ àwọn kókó àdúrà sórí ẹ̀rọ-alágbèkáá rẹ.
3.) Wà ní ìdàpọ̀-ẹ̀mí. Ọ̀nà kan tí a fií wà pẹ̀lú ìtọ́ni Ẹ̀mí ni dídára pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ-lẹ́yìn-Krístì bíi tìrẹ. Ọ̀nà tíó dára jù láti ṣe èyí ní wíwà níbi àwọn ìjọsìn. Ìbá tún dára: tío bá lè wá iṣẹ́ kan ṣe nínú ìjọ. Ìwọ yóò pàdé àwọn ènìyàn titun pẹ̀lú ànfàní láti ní ìbárẹ́ tó jinlẹ̀ pẹ̀lú àwọn Kristẹni bíi tìrẹ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Kíni ètò Olúwa fún ayéè rẹ? Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè tí a maá ń bèrè gẹ́gẹ́ bíi ọmọ-lẹ́yìn-Kristi. Ṣùgbọ́n, tí a bá ma jẹ olóòótọ́, ìrònú wa nípa ètò Olúwa fún ayé wa lè lágbára ju ọgbọ́n orí wa lọ. Nínú ètò Bíbélì ọlọ́jọ́-mẹ́fà yìí, a ó kọ́ọ wípé ètò Olúwa kò le bí a ti lérò, ṣùgbọ́n ó dára ní gbogbo ọ̀nà ju bí a ti lérò
More