Ètò Olúwa Fún AyéèÀpẹrẹ
Máse jẹ́kí ìfòyà káọ lọ́wọ́ kò.
Óṣeése kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ǹkan ńlá wà níwájú rẹ láti ṣe. Bíi: Ayẹyẹ ìparí ẹ̀kọ́; Ìgbani sì ilé-ẹ̀kọ́ gíga; Yíyan iṣẹ́-àyò; àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. O rọrùn fún nkan láti dàbí pé óti dojú rú—kódà, ó lè da bíi wípé o kò mọ ohun tí ò ńṣe!
Jóṣúà ti wà ní'rú ipò yí rí. Nínú Bíbélì, Mósè ní adarí kan tíó múnádóko tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní. Lọ́rọ̀ kan, Jóṣúà jẹ́ amúgbá-lẹ́gbẹ̀ẹ́ Mósè. Lẹ́yìn èyí, ni Mósè papòdà, gbogbo iṣẹ́ àti ìdarí Ísírẹ́lì di ojúṣe Jóṣúà. Bíi wípé iṣẹ́ yìí ma wọ̀ọ́ l'ọ́rùn, àbí?
Bí Ọlọ́run tií fún Jóṣúà ní ìtọ́ni, Ó sọ èyí fún un lí ẹ̀mẹ́ta òtọ̀tọ̀:
“Ṣe gírí kí o sì mú àyà le.”
Ọlọ́run mọ̀ wípé iṣẹ́ tíó le ló wà níwájú Jóṣúà. Ó mọ̀ wípé óṣeéṣe k'áyà ma foo Jóṣúà. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tún mọ wípé òhun ní ètò àti wípé òhun ma bá Jóṣúà lọ. Èyí ló mú kí Jóṣúà lè mú àyà le—ó mọ̀ dájú pé Ọlọ́run ńbẹ pẹ̀lú òhun.
Ìwúrí ibẹ̀ wá nìyí: Ọlọ́run yíò bá ìwọ náà lọ pẹ̀lú. Bíi Jóṣúà, Ọlọ́run fẹ́ kí o ṣe gírí ko sì máyà le bí o ti ń wọ ìpele títún ní ìgbésí ayéè rẹ.
Bóyá àyà àti parí ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga, bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ tàbí láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-àyò níí fòọ́, kí kojú ìjákulẹ̀, tàbí ìpayà bí ọjọ́-ọ̀la yóò tirí, Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ. Bí a ti sọ ní ọjọ́ Kínní ètò yí, o lè mámọ ibi tí ohun gbogbo yóò yanjú sí. Síbẹ̀, a lè jẹ́rìí Ọlọ́run pẹ̀lú ọjọ́-ọ̀la wa, ní ìmọ̀ wípé ní gbogbo ọ̀nà l'ètò Rẹ̀ fí dára ju tiwa lọ.
Lákòótán, mọ̀ dájú wípé Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ ju bí ọgbọ̀n rẹ tí legbèe. Ohunkóhun tí olè kojú láyé, Ọlọ́run kò ní kọ̀ọ́ tàbí fi ọ́ sílẹ̀. Ǹkan lè yí padà, bíi t'Ọlọ́run kọ́, bẹ́ẹ̀ni ìfẹ́ Rẹ̀ sí wa kìí tán. Wá rántí èyí: ètò Ọlọ́run lè má yẹ́ ọ yéké, ṣùgbọ́n ó dájú wípé ó dára jù ohunkóhun tí o lè bèrè tàbí ní lérò. Nígbà tío bá wá mọ èyí tóo sì gbà á gbọ́—kòsí ohun náà táyà rẹ ò lè gbà.
Fún àwọn àlùmọ́ọ́nì ọ̀fẹ́ nípa kókó ẹ̀kọ́ bí eléyìí, lọ sí www.finds.life.church
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Kíni ètò Olúwa fún ayéè rẹ? Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè tí a maá ń bèrè gẹ́gẹ́ bíi ọmọ-lẹ́yìn-Kristi. Ṣùgbọ́n, tí a bá ma jẹ olóòótọ́, ìrònú wa nípa ètò Olúwa fún ayé wa lè lágbára ju ọgbọ́n orí wa lọ. Nínú ètò Bíbélì ọlọ́jọ́-mẹ́fà yìí, a ó kọ́ọ wípé ètò Olúwa kò le bí a ti lérò, ṣùgbọ́n ó dára ní gbogbo ọ̀nà ju bí a ti lérò
More