Ètò Olúwa Fún AyéèÀpẹrẹ
Ètò Ọlọ́run fún ayéè rẹ nííṣe pelu ẹni t'íwọ jẹ́ ju ohun t'íwọ íṣe.
Kí ni mo nílò láti ṣe?
Ó ṣeé ṣe kí ó ti wà ìdáhùn sí ìbéèrè yìí lọ́pọ̀ ìgbà, pàápàá tí o bá ní ìpinnu pàtàkì láti ṣe, bíi ilé-ẹ̀kọ́ gíga tío máa lọ tàbí irú iṣẹ́ t'oma yàn láàyò.
Irú ìbéèrè yí ni olórí ẹ̀sìn kan bi Jésù nínú Bíbélì: “Àṣẹ wò ni ó ṣe pàtàki jùlọ nínú ìwé òfin?” (Mátíù 22:36 NIV) Lọ́rọ̀ kan: kíni mo nílò láti ṣe?
Ní ẹsẹ̀ tí ó tẹ̀le, a rí èsì tí Jésù fi: “Ó gbọ́dọ̀ fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn, ẹ̀mí àti èrò rẹ.” Èyí ni ó jù tí ó sì jẹ́ àkọ́kọ́ nínú òfin. Èkejì tíó tún ṣe pàtàkì: ‘Fẹ́ràn ọmọ làkejì rẹ gẹ́gẹ́ bíi ara rẹ.’ (Mátíù 22:37-39 NIV, pẹ̀lú àfikún)
Nígbà tí a bá ń gbìyànjú láti wádìí ètò Ọlọ́run fún ayéè wa, a lè bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ǹkan méjì tí Jésù ní k'áṣe yìí:
1.) Fẹ́ràn Ọlọ́run.
2.) Fẹ́ràn àwọn èèyàn bíi tìrẹ.
O lè máa gbàárò, ìyẹn kò le, ṣùgbọ́n báwo ni màáṣe mọ ilé-ẹ̀kọ́ tí màa lọ tàbí iṣẹ́ tí máa yàn láàyò?
Ìbéèrè tío dára l'èyí. Adùn ibẹ̀ nìyí: T'íwọ bá ń tẹ̀lé Jésù tío sì ń bá àwọn ènìyàn mímọ́ ṣe, Èmi Mímọ́ máa tọ́ ṣíṣe ìpinnu rẹ.
O lè ma ṣiyèméjì lóri ilé-ẹ̀kọ́ gíga méjì tí ó dára, láìmọ èyí tí Ọlọ́run fẹ́ kí o lọ nínú méjèèjì. Jẹ́kí a padà wo àṣẹ pàtàkì méjì tí Jésù ṣòro rẹ̀: Ìfẹ́ Ọlọ́run àti ìfẹ́ ọmọlàkejì. Ǹjẹ́ o lè fẹ́ràn Ọlọ́run àti ọmọlàkejì rẹ ni ilé-ẹ̀kọ́ gíga méjèèjì bí? Tí ìdáhùn bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ni, o kò nílò láti d'ara rẹ láàmú. Ọlọ́run lè lòọ́ níbi méjèèjì.
Nípa ìpinnu fún ètò ọjọ́-ọ̀la wa, Ọlọ́run lè má fún wa ní ìdáhùn “bẹ́ẹ̀ni” tàbí “bẹ́ẹ̀ kọ́”. Èyí lè fa ìpòrúru-ọkàn, ṣùgbọ́n ànfàní wà níbẹ̀ nígbà tí a bá mu yé ọ wípé ètò Ọlọ́run fún ayéè rẹ ní ìṣe pẹ̀lú ẹni t'íwọ yóò dà ju ohun tí ìwọ ìṣe.
Ǹjẹ́ èyí wá túmọ̀ sí wípé a lè ṣe ohunkóhun tí a bá fẹ́ àti gbé ìgbé ayé tó wùn wá? Kò ríbẹ̀ o! A lè má ní ànfàní láti mọ ètò Ọlọ́run ni gbogbo ìgbà, ṣùgbọ́n a lè rìn ní ipasẹ̀ Ọlọ́run ni gbogbo ìgbà. Kíni èyí túmọ̀ sí? Ìtumọ̀ rẹ ni wípé bí a kò tilẹ̀ mọ ohun tíò kàn láyé wa, a lè tẹ̀síwájú nínú ìgbọràn sì ìpè Ọlọ́run ní àsìkò yìí. Èyí túmọ̀ sí títẹ̀lé, gbígbé ayé òtítọ́, ìgbọràn pẹ̀lú ìbọ̀wọ̀ fún òbí àti àwọn adarí, àti fí-féràn gbogbo ènìyàn tí Ọlọ́run bá mú wa pàdé.
Ohun tó dùn jù níbẹ̀: Tí a bá tẹ̀lé Kristi, Yóò fún wa ní ọgbọ́n nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. (Kọ́ríńtì Kínní 2:12-13) Yóò sọ èrò wa di titun (Róòmù 12:2) pẹ̀lú ìfojúsùn lórí àwọn ǹkan tíó tọ̀. Nígbà tí a bá wà ní sàkání àwọn ọlọ́gbọ́n (Òwe 13:20), àwọn pẹ̀lú yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu rere. Ọ̀nà kan tí ó tún fi lè rí ọgbọ́n gbà ní nípasẹ̀ àdúrà. Kódà, Jákọ́bù 1:5 sọ wípé tí àwa bá bèrè fún ọgbọ́n lọ́dọ̀ Ọlọ́run, Yóò fi fún wa!
Nípa Ìpèsè yìí
Kíni ètò Olúwa fún ayéè rẹ? Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè tí a maá ń bèrè gẹ́gẹ́ bíi ọmọ-lẹ́yìn-Kristi. Ṣùgbọ́n, tí a bá ma jẹ olóòótọ́, ìrònú wa nípa ètò Olúwa fún ayé wa lè lágbára ju ọgbọ́n orí wa lọ. Nínú ètò Bíbélì ọlọ́jọ́-mẹ́fà yìí, a ó kọ́ọ wípé ètò Olúwa kò le bí a ti lérò, ṣùgbọ́n ó dára ní gbogbo ọ̀nà ju bí a ti lérò
More