Ètò Olúwa Fún AyéèÀpẹrẹ

God’s Plan For Your Life

Ọjọ́ 5 nínú 6

Kínní Maá Ṣẹlẹ̀ Tí A Kò Bá Rí Ètò Olúwa? 

Nínú Májẹ̀mú Láíláí, Jeremáyà jẹ́ wòlíì tí ń jíṣẹ́ Olúwa fún àwọn ènìyàn Rẹ̀ tí a tí kó ní ìkógun lọ sí Bábílónì. Ó dájú wípé èyí kìí ṣe ipò tí wọ́n fẹ́ wà. Kìí ṣe ètò tí wọ́n ṣe nìyí. Dípò kí Olúwa gbà wọ́n lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ṣeni Ó sọ fún wọn kí wọ́n “kọ́'lé, àti pinu láti tèdó” (Jeremáyà 29:5 NLT) àti láti “wá àlàáfíà...ìlú tí Mo yàǹda kó'gun le yín lọ.” (Jeremáyà 29:7 NLT)

Ní ẹsẹ̀ Bíbélì díẹ̀ ṣíwájú, Olúwa sọ wípé, … “Ẹ ó wà ní Bábílónì fún àádọ́rin ọdún . Ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí ni Èmi yóò tọ̀ yín wá láti ṣe àwọn ohun rere tí Mo ti ṣèlérí, Èmi yóò sì mú yín padà wá sí lé.” Jeremáyà 29:10 NLT (pẹ̀lú àfikún) 

Àádọ́rin ọdún tán tán! Ọ̀pọ̀ nínú wa ò lè ṣe sùúrù fún àádọ́rin ìṣẹ́jú-àáyá láti rí ǹkan gbà, ká má wá sọ̀rọ̀ àádọ́rin ọdún. 

Gbogbo èyí ni ó tẹ́ pẹpẹ ètò fún ohun tí ó wà nínú ẹsẹ̀ Bíbélì tí ó tẹ̀le: “Nítorí Mo mọ àwọn ètò tí mo ní fún yín,” ni Ọlọ́run wí. “Ètò rere ni, kìí ṣe ti ibi, láti fún yín ní ọjọ́-ọlá tó dára àti ìrètí.” Jeremáyà 29:11 NLT

Àwọn ohun mẹ́ta nípa ètò Olúwa tí o nílò láti mọ̀ nì wọ̀nyí:

1.) Eto tí ó dára lè gba àkókò. Olúwa sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wípé wọn yóò wà nínú ìgbèkùn fún àádọ́rin ọdún. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn tí ó gbọ́ àsọtẹ́lẹ̀ yí ni kò ní sí láyé nígbàtí ìlérí náà yóò wá sí ìmúṣẹ. Nígbà míràn, yóò rí bíi wípé ìlérí náà gbà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún fún Olúwa láti fi ètò rẹ hàn sí ọ. Òtítọ́ ibẹ̀ ni wípé, ó ṣeé ṣe kí ènìyàn má rí ìfarahàn ètò Olúwa fún ayéè rẹ̀—ó ṣeé ṣe fún ọ láti máa nípa nínú ayé àwọn ìran tí a kò tíì bí láìmọ̀!

2.) Àkókò tí a fi dúró d'Olúwa kò ṣòfò dànù. Ṣe àkíyèsí wípé Olúwa ò kàn sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti dúró lásán, láì ni ǹkan íṣe fún àádọ́rin ọdún. Óní kí wọ́n ṣiṣẹ́ fún àlàáfíà àti ìdàgbàsókè ìlú tí a rán wọn lọ. Ibikíbi tío bá wà nísinsìnyí, Olúwa lè lòọ́ níbẹ̀! Máse kùnọ̀ láti nípa fún Ìjọba Ọlọ́run nísinsìnyí nípasẹ̀ dídúró de ipò kan tí Olúwa kò tíì mú ọ dé.

3.) Àwọn ètò Rẹ̀ dára. Ipò-kípò tí ó bá wà nísinsìnyí, ìlérí Jeremáyà 29:11 ṣì dúró síbẹ̀: Olúwa ṣì létò rere fún ọ—ètò fún ọjọ́ wájú rere àti ìrètí. Ohun gbogbo lè má dàbí wípé yóò lọ ní ìrọ́wọ́-rọsẹ̀ l'ásìkò yí, ṣùgbọ́n tí ìwọ kò bá kùnà láti jọ̀wọ́ ọjọ́ ọ̀la rẹ fún Olúwa, ohun dídára ni yóò t'ẹ̀yin rẹ̀ yọ. 

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 4Ọjọ́ 6

Nípa Ìpèsè yìí

God’s Plan For Your Life

Kíni ètò Olúwa fún ayéè rẹ? Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè tí a maá ń bèrè gẹ́gẹ́ bíi ọmọ-lẹ́yìn-Kristi. Ṣùgbọ́n, tí a bá ma jẹ olóòótọ́, ìrònú wa nípa ètò Olúwa fún ayé wa lè lágbára ju ọgbọ́n orí wa lọ. Nínú ètò Bíbélì ọlọ́jọ́-mẹ́fà yìí, a ó kọ́ọ wípé ètò Olúwa kò le bí a ti lérò, ṣùgbọ́n ó dára ní gbogbo ọ̀nà ju bí a ti lérò

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹgbẹ́ Switch, ẹ̀ka iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ìjọ Life.Church, fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: www.life.church