OLUWA si ti wi fun Abramu pe, Jade kuro ni ilẹ rẹ, ati kuro lọdọ awọn ara rẹ, ati kuro ni ile baba rẹ, si ilẹ kan ti emi o fi hàn ọ: Emi o si sọ ọ di orilẹ-ède nla, emi o si busi i fun ọ, emi o si sọ orukọ rẹ di nla; ibukun ni iwọ o si jasi: Emi o bukun fun awọn ti nsúre fun ọ, ẹniti o nfi ọ ré li emi o si fi ré; ninu rẹ li a o ti bukun fun gbogbo idile aiye. Bẹ̃li Abramu lọ, bi OLUWA ti sọ fun u; Loti si ba a lọ: Abramu si jẹ ẹni arundilọgọrin ọdún nigbati o jade ni Harani.
Kà Gẹn 12
Feti si Gẹn 12
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Gẹn 12:1-4
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò