Tani Jésù?Àpẹrẹ

Who Is Jesus?

Ọjọ́ 4 nínú 5

Àwọn Búrẹ́dì àti Àwọn Ẹja

Ǹjẹ́ o ti rí sinimá Disney, “Ọmọ Ọba Íjíbítì?”

Èmi yóò sọ òótọ́ — kì í ṣe Aladdin. 

Fíìmù tó dáa jù lo ni "The Lion King". 

Ṣùgbọ́n, láìdàbí Aladdin tàbí Ọba kìnnìún, Ọmọ ọba Íjíbítì ni ó dá lórí ìtàn gidi kan tí a rí nínú Bíbélì — ìtàn Ìyọrísí.

Nínú ìwé ẹ́kísódù tó wà nínú májẹ̀mú láéláé, ọlọ́run lo mósè láti dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè kúrò lóko ẹrú ní íjíbítì. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá rí i pé àwọn ń rìn gbéregbère nínú aginjù, tí àárẹ̀ mú àwọn, tí wọ́n dọ̀tí, tí ebi sì ń pa àwọn. Wọ́n ń kùn nípa àìrí oúnjẹ jẹ, nítorí náà Ọlọ́run rán "mánà" láti ọ̀run wá, èyí tó túmọ̀ sí ní èdè Hébérù pé, "Kí ni èyí?"” 

Gbogbo ìtàn yìí jẹ́ apá pàtàkì nínú ìtàn inú Bíbélì. 

Ṣùgbọ́n o lè máa béèrè pé, "kí ni Ẹ́kísódù ní í ṣe pẹ̀lú ìtàn tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere?” 

Ìdáhùn náà wà nínú búrẹ́dì náà. 

Nínú ìwé Jòhánù orí kẹfà, àwọn èèyàn náà bá ara wọn nínú aginjù láìsí oúnjẹ. Nígbà tí Jésù ń gbàdúrà, ó wo ọ̀run, búrẹ́dì sì rọlẹ̀ lọ́nà ìyanu. 

Ṣé ohun tí mo sọ yìí kò ṣàjèjì sí ẹ?? 

A tún ní búrẹ́dì tí a pèsè lọ́nà ìyanu fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run nínú aginjù. 

Nítorí náà, kí ni èyí sọ fún wa nípa ẹni tí Jésù jẹ́ nínú àyíká ètò tí Ọlọ́run ṣe nínú ìtàn??

Mósè kọ̀wé nípa wòlíì kan tó tóbi ju òun lọ, ìyẹn aṣáájú àgbàyanu kan tó máa jẹ́ aṣojú Ọlọ́run lọ́jọ́ iwájú. Jésù ń mú ìlérí yẹn ṣẹ, ó sì ń mú ìdáǹdè ńláǹlà wá. Jésù yóò dà bí Mósè tuntun kan tó ń darí ìrìn àjò tuntun kan láti gba àwọn ènìyàn Ọlọ́run là kúrò lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀. Àti pé, gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà tí Ọlọ́run ṣèlérí, Òun yóò kó àwọn ènìyàn Rẹ̀ lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí tó ga jùlọ, ọ̀run tuntun àti ayé tuntun ti Ọlọ́run, yóò sì pèsè oúnjẹ tẹ̀mí láti gbé àwọn ènìyàn Rẹ̀ ró títí di ọjọ́ náà!

Ìtàn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ kà yìí tún fún wa ní àpẹẹrẹ bí Ọlọ́run ṣe ń pe àwọn ènìyàn bíi tiwa láti jẹ́ apá kan ètò rẹ̀. 

Ó ṣeé ṣe kí ọ̀dọ́mọkùnrin tí kò lórúkọ yìí máa kó oúnjẹ tó ní pa mọ́ fún ara rẹ̀. Ó lè fi oúnjẹ rẹ̀ pa mọ́, àmọ́ ì bá pàdánù iṣẹ́ ìyanu Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ onínúure àti ọ̀làwọ́, èyí tó fún un láyè láti di apá kan ohun kan tó tóbi ju ara rẹ̀ lọ! 

Má ṣe jẹ́ kí ohun tí Ọlọ́run ń ṣe nínú ayé yìí bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́ nítorí pé ọkàn rẹ àti ọwọ́ rẹ ti dí lójú Ọlọ́run àti lójú àwọn èèyàn. Má ṣe pàdánù iṣẹ́ ìyanu nítorí oúnjẹ tí kò tó nǹkan, tàbí nítorí ààbò ojú ẹsẹ̀ nítorí ipa tó máa wà pẹ́ títí nínú ìjọba Ọlọ́run. 

Kàkà bẹ́ẹ̀, bi ara rẹ pé, kí ló wà lọ́wọ́ rẹ? Àwọn ẹ̀bùn wo ni Ọlọ́run fún ẹ? Ó lè dà bíi pé kò tó nǹkan, àmọ́ Ọlọ́run wa ò nílò ohun tó pọ̀ kó tó lè ṣe iṣẹ́ ìyanu — Ìwọ̀n búrẹ́dì márùn - ún àti ẹja méjì péré ló kù fún un. 

Lédè míì, ohun tó wà lọ́wọ́ rẹ nìkan ló nílò. 

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Who Is Jesus?

Jésù ní àárín gbùngbùn ìgbàgbọ́ Krìstẹ́nì, ètò ọlọ́jọ́ 5 yìí mú wa lọ inú ọ̀gbun Ẹni tí ṣe: Olùdárí ẹ̀ṣẹ̀ jì, Ọ̀rẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Ìmọ́lẹ̀, Oníṣẹ́-ìyanu, Olúwa-tó-Jíìnde.

More

Ètò kíkà yìí la mú tọ̀ yín wá látọwọ́ Alpha and the Alpha Youth Series, àpérò onípa-mẹ́tàlá tí ńṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìbéèrè tó tóbi jù ní ìgbésí ayé ènìyàn. Fún àlàyé síwájú sí, jọ̀wọ́ lọ sí: http://alpha.org/youth