LẸHIN nkan wọnyi, Jesu kọja si apakeji okun Galili, ti iṣe okun Tiberia.
Ọpọ ijọ enia si tọ̀ ọ lẹhin, nitoriti nwọn ri iṣẹ àmi rẹ̀, ti o nṣe lara awọn alaisàn.
Jesu si gùn ori òke lọ, nibẹ̀ li o si gbé joko pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.
Ajọ irekọja, ọdun awọn Ju, si sunmọ etile.
Njẹ bi Jesu ti gbé oju rẹ̀ soke, ti o si ri ọ̀pọ enia wá sọdọ rẹ̀, o wi fun Filippi pe, Nibo li a o ti rà akara, ki awọn wọnyi le jẹ?
O si sọ eyi lati dán a wò; nitoriti on tikararẹ̀ mọ̀ ohun ti on ó ṣe.
Filippi da a lohùn pe, Akara igba owo idẹ ko to fun wọn, ti olukuluku wọn iba fi mu diẹ-diẹ.
Ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, Anderu, arakunrin Simoni Peteru wi fun u pe,
Ọmọdekunrin kan mbẹ nihinyi, ti o ni iṣu akara barle marun, ati ẹja kékèké meji: ṣugbọn kini wọnyi jẹ lãrin ọ̀pọ enia wọnyi bi eyi?
Jesu si wipe, Ẹ mu ki awọn enia na joko. Koriko pipọ si wà nibẹ̀. Bẹ̃li awọn ọkunrin na joko, ìwọn ẹgbẹdọgbọn enia ni iye.
Jesu si mu iṣu akara wọnni; nigbati o si ti dupẹ, o pin wọn fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si pín wọn fun awọn ti o joko; bẹ̃ gẹgẹ si li ẹja ni ìwọn bi nwọn ti nfẹ.
Nigbati nwọn si yó, o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ kó ajẹkù ti o kù jọ, ki ohunkohun máṣe ṣegbé.
Bẹ̃ni nwọn kó wọn jọ nwọn si fi ajẹkù ìṣu akara barle marun na kún agbọn mejila eyi ti o ṣikù, fun awọn ti o jẹun.
Nitorina nigbati awọn ọkunrin na ri iṣẹ àmi ti Jesu ṣe, nwọn wipe, Lõtọ eyi ni woli na ti mbọ̀ wá aiye.