Tani Jésù?Àpẹrẹ

Who Is Jesus?

Ọjọ́ 5 nínú 5

Jésù Ni Olúwa Tó Jíǹde

Ńjé o ti lo fún ìsìnkú ri? Mo mò pé èyí jẹ́ ìbéèrè tó ń kóni nírìíra, má ṣe bínú pé mo kàn béèrè ìrù béèrè yìí. Àmọ́ ìsìnkú máa ru àwon ìbéèrè to kọminú nípa ikú jáde, àti pápá nípa ìgbé àyè léyìn ikú.

Se ikú dà bí àsìkò (tàbí àmì ìparí òrọ̀) tó parí ìgbé ayé wa ní ayé yìí? Tàbí ikú dà bí àmì komá tó ń ṣíṣe ìyípadà wọnú iwàláàyè mìíràn to yàtọ̀ sí èyí?

Ǹjẹ́ ìdí kankan wà láti gbà gbọ́ pé ìwàláàyè mbẹ lẹ́yìn ikú, àti ìrètí léyìn sàréè?

Ibi tí ìtàn tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kà yìí ti wáyé ní yàrá òkè kan láìpẹ́ lẹ́yìn tí ọmọ ogun Róòmù pá Jésù. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn kóra jọ, ẹ̀rù bà wọ́n gan-an nígbà tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó bani nínú jẹ́ yìí wáyé, nígbà náà, lójijì, ti Jésù farahàn láàrín won gan-an.

Kìí se ìgbà àkókò ti Jésù máa ẹ̀rù bà á àwọn ọmọlẹ́yìn Rè nípa fifarahàn Ó tún fi ara Rẹ̀ hàn ní alààyè lekan síi. Síbè Tọ́másì, kò si níbè nígbàti Jésù farahàn ní àwọn àkókò wọ̀nyẹn, O yìí jé alárìíwísí nípa ìtà nàá, torí náà Jésù yíjú sí O si sọ wípé,

“Fi ìka rẹ síbí, kí o sì wo ọwọ́ mi, ki ọwọ́ rẹ bọ ẹ̀gbẹ́ mi. Má sì ṣiyèméjì mọ́ ki o bẹ̀rẹ̀ sí í gbà gbọ́.” Tọ́másì wi fún Un pé, ”Olúwa mi àti Ọlọ́run mi “ (vs. 27, 28).

Níhìn-ín ni a ti rí gbólóhùn òrò yìí "Tọ́másì oníyèméjì ”.

Nísinsìnyí, bii Tọ́másì, gbogbo wa le ni àwọn àsìkò iyèméj; àwọn ìgbà tí a ń ro bóyá Ọlọ́run ́bá wà lóòótọ́; àwọn àkókò ti a máa ń ṣe kàyéfì bóyá Jésù féràn wa. A lè máa bi ará wa, “Njẹ́ eyi je òtítọ́?” “Se mò lè gbàgbó nínú ohun ti mò o ri?”

A dúpẹ́, àwon iyèméjì wa kò bà Ọlọ́run lẹ́rù, àti pe nígbà ti a bá sọ iyèméjì fun Ọlọ́run èyí pàápàá je ìgbésẹ̀ ìgbàgbọ́. Kódà, a kọ nínú ìtàn náa pé Jésù sẹtán láti sún mọ́ wa láàrín àwọn ìbéèrè wa, àti lópò ìgbà igbàgbọ́ to dánílójú, àti eyi to lókun ni a máa rí ni apá kejì gbígbógun ti iyèméjì wa.

Àmó, ki a pa àwọn iyèméjì sí ẹgbẹ́ kan, ìròyìn ayọ̀ ni pe a àwọn ìdí tó ṣe gúnmọ́ pe Ọlọ́run jí Jésù dìde kúrò nínú òkú. Ìwọ̀nba díẹ̀ rèé:

  • Wọ́n rí i pé kò sí nǹkan kan nínú ibojì jésù lọjọ́ àìkú ti a kàn mo àgbélébùú ti wọ́n si sọ pé ó ti kú.
  • Jésù fárá hàn àwọn ọmọ eléyìn E láàrín ogójì ọjọ́, pẹ̀lú aṣiyèméjì bí Tọ́másì, àti si àwọn alárìíwísí bii Jákọ́bù àti Pọ́ọ̀lù, ti won kìí se ọmọlẹ́yìn àkọ́kọ́ ti Jésù.
  • Fun ìdí àwọn ìfarahàn yìí, ìgbé aye àwọn ọmọlẹ́yìn ’ yí padà pátápátá dé ibi tí òpò lara won setán láti jìyà àti kú fún ìgbàgbọ́ won nínú Jésù. Dájúdájú àwọn ènìyàn ń kú fún ìdí kàn ( tàbí fún ẹṣin) ti wón gbàgbọ́ láti je òtítọ́, àmọ́ kò si ẹnikẹ́ni tó ní ọpọlọ to máa kú fún ohun ti o mò pé o jé ayédèrú! Bi ìtàn yii se ran wa létí, àwọn omo eléyìn àkókò wa ni ipò láti mò bóyá itàn nípa àjíǹde Jésù je òdòdó tàbí ìrò!

Ònà tó dára jú làti sàlàyé ìdàgbàsókè ẹ̀sìn krístì àti àwon Itèsiwajú ìyípadà to de ba ayé àwon èniyàn lọjọ́ òní, pẹ̀lú ìsọfúnni tó wà lókè yìí, ni àjíǹde Jésù Kristi!

A dá ètò Bábélì olojoọjọ́ márùn-ún yìí lórí ìdánimò Jésù. Àjíǹde Rè nípa ti ara fún wa ní àlàyé to kẹyìn.

Olórun, Fúnra Rè, ti fi ìdánimò Jésù múlè ’ nípasẹ̀ isé ìyànú.

Lóòótọ́ ni Jésù jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run àti Olùgbàlà wa!

Àjíǹde túmò si pè ikú kò ni ọ̀rọ̀ ìkẹyìn.

Ìrètí mbẹ lábẹ́ sàréè.

Ikú kìí se àsìkò; o jé àmì komá tó ń mú wa kojá siwájú Jésù.

A si pè wa làti dáhùn si Jésù nípa sisọ ìró àwọn ọ̀rọ̀ Tọ́másì: “Olúwami ati Ọlọ́runmi!”

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Who Is Jesus?

Jésù ní àárín gbùngbùn ìgbàgbọ́ Krìstẹ́nì, ètò ọlọ́jọ́ 5 yìí mú wa lọ inú ọ̀gbun Ẹni tí ṣe: Olùdárí ẹ̀ṣẹ̀ jì, Ọ̀rẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Ìmọ́lẹ̀, Oníṣẹ́-ìyanu, Olúwa-tó-Jíìnde.

More

Ètò kíkà yìí la mú tọ̀ yín wá látọwọ́ Alpha and the Alpha Youth Series, àpérò onípa-mẹ́tàlá tí ńṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìbéèrè tó tóbi jù ní ìgbésí ayé ènìyàn. Fún àlàyé síwájú sí, jọ̀wọ́ lọ sí: http://alpha.org/youth