Tani Jésù?Àpẹrẹ

Who Is Jesus?

Ọjọ́ 2 nínú 5

Jésù jẹ́ Orẹ́ Àwọn Ẹlẹ́sẹ̀

 Ibùdó onjẹ lákòókò onjẹ ọsan kì í ṣe ibi tó fani mọ́ra lọ títí.

Àkókò oúnjẹ lè ṣe àkójọpọ̀ àwọn ènìyàn, tàbí kó yà wọ́n sọ́tọ̀. Àwọn oúnjẹ jíjẹ sì tún lè fà ìdènà tàbí tú àwọn ènìyàn ká. Àwọn ènìyàn tí ò ń bá jẹun tàbí tí o yẹra fún ní àkókò oúnjẹ ọ̀sán a máa ṣe àfihàn fún àwọn tí ó wà ní àyíká lákòókò náà irúfẹ́ èyàn tí o faramọ́ àti àwọn tí o lè bá ṣe pọ̀.

 Àkókò oúnjẹ nígbà ayé Jésù fi ara pẹ́ iru àpèjúwe tí a ṣe ṣáájú yìí.

Ní ìgbà gbogbo ni àwọn olórí ẹ̀sìn máà ń tako Jésù nípa àwọn tí ó ń bá jẹun pọ nítorí pé nínú àṣà wọn àkókò oúnjẹ jẹ àpẹẹrẹ ìbánidọ́rẹ àti ìfanimọ́ra, àti pé ohun tí ó jẹ ìyàlẹ́nu fún àwọn míràn ni pé àwọn tí Jésù ń bá jẹun pọ̀ jẹ́ àwọn tí kò ní láárí, àwọn ẹlẹ́sẹ̀ tí wọn jìnà sì Ọlọ́run.

Nígbàtí àwọn Farisí tí wọn jẹ òlukọ́ni nípa òfin rí tí Ó ń ba"awon ẹlẹ́sẹ̀" àti àwọn agbowó orí jẹun, wọn béèrè lọ́wọ́ awọn ọmọ lẹhin Rẹ̀ pé:" Kí lóde tí Ó fi ń bá àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́sẹ̀ jẹun pọ?"(ẹsẹ. 16).

Ṣùgbọ́n Jésù wí fún wọn pé, "Èmi kò wá láti pé àwọn olódodo, bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́sẹ̀" (ese. 17).

Ara ìdánimọ̀ Jésù ni orúkọ tí wọn fún gẹ́gẹ́ bí "ọ̀rẹ́ àwọn ẹlẹ́sẹ̀"

Tí ó bá fí ojú inú wò ìjọba Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan, àwọn Farisí ń fẹ́ pé àwọn ìlúmọ́ká ènìyàn nìkan, àwọn tí ó dúró déédéé ní àwùjọ tí wọn pá òfin mọ tí wọ́n sì dà bí olùjọsìn

Jésù, ní ìdàkéjì, ń pè gbogbo ènìyàn. Ohunkóhun tí ó wù kó tí hù ní ìwà tàbí bí ó ti ṣe burú tó -- a pé ọ́ sì ẹgbẹ́ Ọlọ́run nípa ìbásepọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀. Àyè wá ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀ fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ àti àwọn arúfin

Èyí mú kí àwọn Farisí bínú nítorí pé wọ́n rò wípé ìmọ́-tótó, ìwà mímọ tàbí ìhùwàsí dáradára ní ó lè yọrí sí ìbásepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.  Ṣùgbọ́n Jésù mọ Ó sì ṣe bí ẹni mímọ, tàbí gbé ìgbé ayé dáradára, tí ó sì yọrí sí ìbásepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run

Láti sọ ní ọ̀nà míràn: Dípò, yípadà kí Ọlọ́run tó fẹ́ràn rẹ,Jésù ń pè wá láti gbá gbọ́, Ọlọ̀run fẹ́ràn rẹ àti pé ìfẹ́ Rẹ̀ lè yí ọ padà. Jésù kò fi ìgbé ayé bẹ̀rẹ̀; Ó máa ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run, níní imọ wípé ìfẹ́ Ọlọ́run lè ṣe ìyípadà ìwà àti ìgbé ayé wa bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́.

 Nípasẹ̀ Jésù, Ọlọ́run pé wá láti wá ṣíwájú kí a tó gbàgbọ́ àti pàápàá ṣíwájú kí a tó hùwà, nítorí ìfìwépè wá sí ẹgbẹ́ Ọlọ́run kò dá lórí rere tí a ṣe, ó dá lórí oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀

 Tábìlì onjẹ tí Jésù ń sọ nípa ìtàn bí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ṣe fà ìfọwọ́sọwọ́ pọ̀ gbogbo oríṣiríṣi ènìyàn

 Mò ń wòye irúfẹ́ ìtàn tí tábìlì oúnjẹ wa ńsọ lóde òní?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Who Is Jesus?

Jésù ní àárín gbùngbùn ìgbàgbọ́ Krìstẹ́nì, ètò ọlọ́jọ́ 5 yìí mú wa lọ inú ọ̀gbun Ẹni tí ṣe: Olùdárí ẹ̀ṣẹ̀ jì, Ọ̀rẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Ìmọ́lẹ̀, Oníṣẹ́-ìyanu, Olúwa-tó-Jíìnde.

More

Ètò kíkà yìí la mú tọ̀ yín wá látọwọ́ Alpha and the Alpha Youth Series, àpérò onípa-mẹ́tàlá tí ńṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìbéèrè tó tóbi jù ní ìgbésí ayé ènìyàn. Fún àlàyé síwájú sí, jọ̀wọ́ lọ sí: http://alpha.org/youth