Tani Jésù?Àpẹrẹ

Who Is Jesus?

Ọjọ́ 1 nínú 5

Ìtàn Alárùn-ẹ̀gbà: Jésù Ni Ẹni Tó Ń Dárí Ẹ̀ṣẹ̀ Jì

Tí o bá lè jẹ́ àràmàǹdà akíkanjú, kíni yíò jẹ́ agbára ọ̀tọ̀ rẹ? Ìbéèrè yìí jẹ́ èyí tí ó ṣe pàtàkì, nítorí náà ronú gidi kí o tó fèsì. 

Fífò?

Dídi ẹni àìrí?

Ìdarí ẹ̀mí ẹlòmíràn?

Máàdáríkàn? 

Tí ó bá ṣeéṣe láti yàn “gbogbo àwọn ẹ̀ṣà” tí ó wà nkọ́? 

Ní ojú lásán, ìfẹ́ wa sí àwọn akíkanjú aláràmàǹdà lè jẹ́ nítorí pé a máa n fẹ́ kí á dá wa l'ára yá kí a lè baà gbàgbé ìjàkadì ojoojúmọ́ ayé wa. Ṣùgbọ́n tí a bá wòó jinlẹ̀, ó ṣeéṣe pé a fẹ́ràn àwọn alágbára àràmàǹdà yìí gidigidi nítorí nínú ọkàn wa bí ènìyàn, à n pòùngbẹ kí á gbà wá, a sì n lépa agbára ju déédé ohun tó ṣeéṣe lọ. 

A mọ̀ wí pé Jésù kìí ṣe alágbára àràmàǹdà bíi ti àwọn òṣèré Marvel, ṣùgbọ́n tí a bá ka awon ìwé Ìhìnrere, a ó ríi pé Jésù ní agbára láti ṣe ìyanu tó ju ohun tí ènìyàn mọ̀ lọ, bíi mímú aláìsàn lára dá àti lílé ẹ̀mí èṣù jáde. Fún ìdí èyí, Jésù wọ́ ọ̀pọ̀ èrò, òfófó agbára Rẹ̀ tàn káàkiri bíi iná pápá. 

Nínú ìtàn yí, àwọn ọkùnrin mẹ́rin kan gbọ́ òkìkí Oníṣẹ́ ìyanu yìí, wọ́n sì mú ìrìn-àjo pọ̀n láti ríi. Wọ́n pinu láti gbé ọ̀rẹ́ wọn ti ojú ń pọ́n tọ Jésù wá, ṣùgbọ́n lójú ẹsẹ̀ náà ni wọ́n ti pàdé ìdínà àwọn ènìyàn.

“Nígbà tí wọn kò sì le dé ọ̀dọ̀ Jesu, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, wọ́n dá òrùlé ilé lu ní ọ̀gangan ibi tí Jesu wà. Wọ́n sì sọ ọkùnrin arọ náà kalẹ̀ ti òun ti àkéte rẹ̀ níwájú Jesu.” (ẹsẹ̀. 4). 

Ẹ jẹ́ kí á tẹ bọ́tìnì ìdá-ẹnu-dúró fún ìgbà díẹ̀.

Àwọn arákùnrin yìí kò ṣe méjì ju pé wọ́n ba ilé onílé jẹ́ lọ!

Ọpẹ́ ni pé Jésù f'ojú fo èyí, pé Ó sì sọ fún ọkùnrin ẹlẹ́gbà náà, “Ọmọkùnrin, adarí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ji”. Lẹ́yìn èyí Jesu wo ẹsẹ̀ rẹ̀ sàn. Ẹnu ya àwọn èrò tó pé jọ, ṣùgbọ́n àwọn olórí ẹ̀sìn ń béèrè lọ́kàn wọn, “Tani ẹni náà tó ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì, bí kò ṣe Ọlọ́run nìkan?” 

Ẹnìkan ṣoṣo tí ó lè dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ jì náà ni Ẹni tí a ti ṣẹ̀ sí ní gbogbo ọ̀nà — Ẹni náà ni Ọlọ́run, Òun tìkára Rẹ̀. 

Lẹ́ẹ̀kan sí, ìtàn yíì tọ́ka sí ìru ẹni tí Jésù ǹṣe. Nínú ìtàn yìí, Jésù ń sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ ló ń hùwà ní ipò Ọlọ́run láì sí à n bẹ ẹnikẹ́ni. Jésù pàápàá fi ẹ̀rí àṣẹ tó ní hàn nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìyanu. Lọ́nà míràn ẹ̀wẹ̀, ìtàn yìí ń fi yé wa pé Jésù ni Ọlọ́run! 

A lè má jẹ́ alárùn-ẹ̀gbà bíi arákùnrin inú ìtàn yí. 

Ṣùgbọ́n ẹnì kọ̀ọ́kan wa la ti ṣe àṣìṣe, tí ó sì dà bíi pé àwa náà di arọ nítorí ìtìjú, ẹ̀rù wa àti àìmọ̀ọ́ṣetóo wa. Ẹsẹ̀ wa lè máa ṣiṣẹ́ déédé, ṣùgbọ́n ki ayé wa jọ pé ó ṣẹ́ nítorí pé ìṣòro wa tó lóòrìn jù jẹ́ ti ẹ̀mí kí ó tó di ẹran ara. 

Àìní wa tó jinú jù ni kí á gba ìdáríjì, kí á sì ní ìbálàjà pẹ̀lú Aṣẹ̀dá wa — láti ní ìrírí agbára ìwòsàn tó wà nínú ìfẹ́ Ọlọ́run bí ó ti ṣe ń ṣàn bọ̀ sí orí gbogbo àìbalẹ̀ ọkàn wa láti sọ wá di pípé.

Jésù kìí ṣe alágbára àràmàǹdà láti inú eré sinimá. 

Jésù wà lóòótọ́. 

Àwọn ohun dáradára ma ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí a bá súnmọ́ Jésù: à n mú ara dá, ọ̀kan ngba ìwòsàn, à n pa ẹ̀rù lẹ́nu mọ́, ìrètí ń dáyé, a ṣì mú gbogbo ẹ̀gàn lo. 

Fún ìdí èyí, njẹ́ a ó dárúkọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, a ó sì gba Jésù láàyè láti dáríjì wá kí Ó sì tú wa sílẹ̀ bí? Ju èyí lọ, ǹjẹ́ a ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jésù lè ṣe bákan náà fún àwọn ọ̀rẹ́ wa? Àti pé, tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé àwa ṣe tán láti ṣe ohunkóhun tí ó pé fún láti fi àwọn ọ̀rẹ́ wa han Jésù? 

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Who Is Jesus?

Jésù ní àárín gbùngbùn ìgbàgbọ́ Krìstẹ́nì, ètò ọlọ́jọ́ 5 yìí mú wa lọ inú ọ̀gbun Ẹni tí ṣe: Olùdárí ẹ̀ṣẹ̀ jì, Ọ̀rẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Ìmọ́lẹ̀, Oníṣẹ́-ìyanu, Olúwa-tó-Jíìnde.

More

Ètò kíkà yìí la mú tọ̀ yín wá látọwọ́ Alpha and the Alpha Youth Series, àpérò onípa-mẹ́tàlá tí ńṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìbéèrè tó tóbi jù ní ìgbésí ayé ènìyàn. Fún àlàyé síwájú sí, jọ̀wọ́ lọ sí: http://alpha.org/youth