NIGBATI o si tún wọ̀ Kapernaumu lọ lẹhin ijọ melokan; okikí kàn yiká pe, o wà ninu ile.
Lojukanna ọ̀pọ enia si pejọ tobẹ̃ ti aye kò si fun wọn mọ, kò si, titi de ẹnu-ọ̀na: o si wasu ọ̀rọ na fun wọn.
Nwọn si wá sọdọ rẹ̀, nwọn gbé ẹnikan ti o li ẹ̀gba tọ̀ ọ wá, ẹniti mẹrin gbé.
Nigbati nwọn kò si le sunmọ ọ nitori ọ̀pọ enia, nwọn si ṣí orule ile nibiti o gbé wà: nigbati nwọn si da a lu tan, nwọn sọ akete na kalẹ lori eyiti ẹlẹgba na dubulẹ.
Nigbati Jesu ri igbagbọ́ wọn, o wi fun ẹlẹgba na pe, Ọmọ, a dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ.
Ṣugbọn awọn kan ninu awọn akọwe wà ti nwọn joko nibẹ̀, nwọn si ngbèro li ọkàn wọn, wipe,
Ẽṣe ti ọkunrin yi fi sọrọ bayi? o nsọ ọrọ-odi; tali o le dari eṣẹ jìni bikoṣe ẹnikan, aní Ọlọrun?
Lojukanna bi Jesu ti woye li ọkàn rẹ̀ pe, nwọn ngbèro bẹ̃ ninu ara wọn, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nrò nkan wọnyi ninu ọkàn nyin?
Ewo li o ya jù lati wi fun ẹlẹgba na pe, A dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ; tabi lati wipe, Dide, si gbé akete rẹ, ki o si ma rìn?
Ṣugbọn ki ẹ le mọ̀ pe, Ọmọ-enia li agbara li aiye lati dari ẹ̀ṣẹ jìni, (o wi fun ẹlẹgba na pe,)
Mo wi fun ọ, Dide, gbé akete rẹ, ki o si mã lọ ile rẹ.
O si dide lojukanna, o si gbé akete na, o si jade lọ li oju gbogbo wọn; tobẹ̃ ti ẹnu fi yà gbogbo wọn, nwọn si yìn Ọlọrun logo, wipe, Awa ko ri irú eyi rí.