Tani Jésù?Àpẹrẹ

Who Is Jesus?

Ọjọ́ 3 nínú 5

Jésù Ni Ìmọ́lẹ̀ náà

Ǹjẹ́ o ti bẹ̀rù nínú òkùnkùn rí bí? 

Ṣé o tun sùn pẹ̀lú iná-alẹ́ bí? 

O le gbà wípé. Èyí jẹ́ ààyè ìpamọ́. 

Nkankan wà nípa òkùnkùn biribiri tí ó le mú ìbẹ̀rù ṣílẹ̀ wọ inú ọ̀pá ẹhìn wa kí ó ṣì fi wá ní ara aìbalẹ̀. 

Nígbàtí o bá bẹ̀rù òkùnkùn o ma kọ́ ẹ̀kọ́ láti ní fẹ̀ Ìmọ́lẹ̀. 

Ìmọ́lẹ̀ ń tan kedere sí àyíká wa. Ìmọ́lẹ̀ ṣe àfihàn ibiti a ma gbé ẹsẹ̀ wa sí. Ìmọ́lẹ̀ Jẹ́ kí á bu ọlá fún àwọn tí a ní fẹ sí. Ìmọ́lẹ̀ Jẹ́ pàtàkì fún ìgbésí ayé, méjèèjì nípa tí ọ̀nà ìbí àti ti ẹ̀mí. 

Nínú Bíbélì, a sábà máa lo ìmọ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àmì fún òye ọgbọ́n àti ìwà mímọ́. Rín rìn nínú òkùnkùn ń tọ́ka sí gbígbé ni ìlòdì sí Ọlọ́run àti ìfẹ́ Rẹ̀ fún wa, ṣùgbọ́n láti rìn nínú ìmọ́lẹ̀ ni láti ṣàwárí ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ àti kọ́ ẹ̀kọ́ bí a ti le tẹ́lẹ̀ lẹ́hìn. Fún èyí a nílò ìrànlọwọ́ Jésù. 

Nínú ẹ̀kọ́ tí a ṣèṣè kà, Jésù sọ pé òun ni ìmọ́lẹ̀ ayé! 

Jésù ni ìmọ́lẹ̀ wa tí ó tàn kedere sí ojú Ọlọ́run tí ó ṣì ṣe amònà ọ̀nà wa sí iyè kíkún. 

Àti, kìí ṣe Jésù nìkan ni ìmọ́lẹ̀ ayé; àti ìwọ náà! Ní Mattew 5: 14 Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pe, "Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé." 

Bí Jésù bá jẹ́ Ọmọ, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ níláti dàbí dígí tí ń tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn. 

Nígbàtí a bá tan ìfẹ́ àti òtítọ́ Jésù sínú ilé-ìwé wa, ilé, àti láàrin ọ̀rẹ́ wa, à ń ti òkùnkùn padà sẹ́yìn nínú ayé wa; à ń mú ìrètí àti ìfẹ́ wa ní orúkọ Jésù, ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé àwọn ènìyàn yóò tọpa ìmọ́lẹ̀ wa sí orísun rẹ nínú Jésù, fún rárá rẹ!

ìmọ́lẹ̀ kò yẹ kí ó farapamọ́ tabi fi bò.

ìmọ́lẹ̀ wá wà fún gbogbo enìyàn láti rí ní gbangba. 

Ìdí pàtàkì ìmọ́lẹ̀ ni láti mú òkùnkùn kúrò. 

Nítorí náà àwọn ọ̀nà wo ni o le mú ìmọ́lẹ̀ ìfẹ́ Ọlọ́run wá sínú ilé-ìwé tàbí ilé rẹ ní pàṣẹ àwọn ọ̀rọ̀ inú rere àti àwọn ìṣe rere? 

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Who Is Jesus?

Jésù ní àárín gbùngbùn ìgbàgbọ́ Krìstẹ́nì, ètò ọlọ́jọ́ 5 yìí mú wa lọ inú ọ̀gbun Ẹni tí ṣe: Olùdárí ẹ̀ṣẹ̀ jì, Ọ̀rẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Ìmọ́lẹ̀, Oníṣẹ́-ìyanu, Olúwa-tó-Jíìnde.

More

Ètò kíkà yìí la mú tọ̀ yín wá látọwọ́ Alpha and the Alpha Youth Series, àpérò onípa-mẹ́tàlá tí ńṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìbéèrè tó tóbi jù ní ìgbésí ayé ènìyàn. Fún àlàyé síwájú sí, jọ̀wọ́ lọ sí: http://alpha.org/youth