Orin ìyìn: Oore òfẹ́ ninu Ìtàn RẹÀpẹrẹ

Orin ìyìn: Oore òfẹ́ ninu Ìtàn Rẹ

Ọjọ́ 4 nínú 5

Oore-Ọfẹ Ninu Idoti Wa

Oore-ọfẹ wa fún gbogbo ènìyàn. Yálà o tẹ̀ lé gbogbo òfin náà, tàbí àṣìṣe rẹ ló mú ọ lọ sẹ́wọ̀n. Yálà o ti di arungun, tàbí o ti di ajoògùnyó.Yálà ìdílé rẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ, tàbí gbogbo àwọn tó wà nínú ìgbésí ayé rẹ ti pa ọ́ tì.

Yálà o rò pé o yẹ e, tàbí pé o rò pé o ti ṣe aṣiṣe lọ́pọ̀ ìgbà— oore- ọfẹ wa fún Ọ.

Oore-ọfẹ kì í ṣe fún ẹni tí ó dára, ti o pe, tí ó tán, tàbí ẹni tí ó ti mọra. Oore-ọfẹ jẹ fún ẹni tí ó tún ti ṣèṣì tí ó ní, "kò sẹni tó lè nífẹ ẹ mi mọ, mo ti sọnù jù."

Johannu 8 sọ itan ti obinrin kan ti a mu ninu iṣe panṣaga. Àwọn aṣáájú ẹsìn ìgbà ni rí obìnrin kan tó ń sùn pẹlú ọkùnrin tí kì í ṣe ọkọ rẹ. Ofin sọpe ijiya panṣaga jẹ iku.

Jésù ń kọni nínú àgbàlá tẹńpìlì nígbà táwọn aṣáájú èsìn mú obìnrin yìí wá síwájú Rẹ. A lè ṣàníyàn nípa ẹgbin, ìtìjú, àti ìbẹrù tí obìnrin náà ní bí wọn ṣe gbé e wá síwájú Jésù. Awọn ẹsun ti n dun ni etí rẹ. Ìdálẹbi yí i ká. Ó mọ ohun tí ó ti ṣe. Ó mọ pé ó ti ṣe aṣiṣe.

Bí ogunlọgọ náà ti di òkúta mú lọwọ, ọrọ tí Jésù sọ jáde lẹnu yà wọn lénu pé: “Ẹnikẹni tí kò ní ẹṣẹ, kí ó kọkọ ju òkúta sí i” (Johannu 8:7)." Gbogbo ènìyàn sì ń sọ òkúta wọn sílẹ lọ kọ ọ kan títí tí ofi ku Jésù àti obìnrin náà.

Kò kígbe sí i, kò ṣe ẹlẹyà rẹ, tàbí kó dá a lẹ́jọ́. Dípò náà, Jésù wọ inú ìdààmú rẹ, O wọ inú ìparun rẹ, ó sì sọ fún un pé kò dá a lẹ́jọ́, ó sì pe e láti gbé ìgbé ayé tó yàtọ̀ (Johannu8:10-11).

Jésù fún obìnrin yìí ni ohun tó jẹ́ pé ó nílò jùlọ, ṣùgbọ́n kò ṣeé retí oore- ọfẹ. Kò bẹ̀rù láti wọ inú ìdààmú rẹ. Kò sọ fún un pé kó lọ wẹ ara rẹ̀ kí ó tó bá a sọ̀rọ̀. Ó wá sọ́dọ̀ rẹ̀ bí ó ti rí, ó sì fún un ní oore-ọ̀fẹ́ tí kò gba ẹ̀mí rẹ̀ là nìkan, ó tún yí i padà.

Oore-ọfẹ kò bẹ̀rù ìdààmú. Jésù ké sí wa láti wá sọ́dọ̀ Òun láìka àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sí nítorí pé oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ wẹ̀ wá mọ́, ó sì ń darí wa sílé.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Orin ìyìn: Oore òfẹ́ ninu Ìtàn Rẹ

O ṣeéṣe pé o ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “ọ̀rẹ́-ọfẹ́,” ṣùgbọ́n kí ni ó tumọ̀ sí gangan? Báwo ni ọ̀rẹ́-ọfẹ́ Ọlọ́run ṣe lè gba wa là àti yí ìgbé aye wa padà? Kọ́ nípa bí ọ̀rẹ́-ọfẹ́ àgbàyanu yìí ṣe ń pàdé wa ní ibi tí a wà, tí ó sì ń yí ìtàn wa padà.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Pulse Evangelism fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://pulse.org