Orin ìyìn: Oore òfẹ́ ninu Ìtàn RẹÀpẹrẹ

Orin ìyìn: Oore òfẹ́ ninu Ìtàn Rẹ

Ọjọ́ 3 nínú 5

Itumọ Oore-ọfẹ

Kò sí ẹbùn tí a lè fi wé ẹbùn tí Ọlọrun ti fi fún gbogbo ìṣẹdá— oore-ọfẹ.

Oore-ọfẹ jé kò lẹtọ sí, tàbí àìlẹ tọsí, ojú rere Ọlọrun. Oore-ọfẹ jẹ pataki si ẹniti Ọlọrun jẹ. O jẹ ẹbun ọfẹ ti igbala ti o wa fun gbogbo eniyan.

"Nítorí oore-ọfẹ ní a fi gbàyín là nípa ìgbàgbọ. Èyí kì í ṣe nípa agbára ẹyin fúnrayín: ẹbùn Ọlọrun ni: 9 Kì í ṣe nípa àwọn iṣẹ, kí ẹnikẹni má ba à ṣògo” (Ẹfesu 2:8-9).

Bí Ajihinrere Billy Graham ṣe sọ ọ́ ”àánú Ọlọ́run, ní ṣókí, ni àánú àti oore Ọlọ́run sí wa.” Kò sí nǹkan kan tí oore-ọ̀fẹ́ ní í ṣe pẹ̀lú wa, gbogbo rẹ̀ ló sì ní í ṣe pẹ̀lú Ọlọ́run. Òun ló ń pèsè rẹ̀, àwa la sì ń gbà á.

Ní ayé wa, wọ́n ń kọ́ wa pé a gbọ́dọ̀ rí ohunkóhun tá a bá fẹ́ gbà, a gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára ká lè rí i gbà, a sì gbọ́dọ̀ lẹ́tọ̀ọ́ sí i. Ìdí nìyẹn tá a fi máa ń ṣe ẹrú iṣẹ́ wa, tá a máa ń kàwé títí di òru, tá a sì ń fi àwọn kùdìẹ-kudiẹ wa pamọ, a sì ń fi ara wa hàn sí àwọn tó wà yí ká wa. A ń ni ero pé a ní láti ṣe akinkanju láti jèrè, kí a sì yẹ fún góńgó tí a ń lépa.

Oore- ọfẹ Ọlọ́run jẹ́ idakeji. Kristẹni ni ẹ̀sìn kan ṣoṣo ti kò sọ “ṣe,” ṣùgbọ́n “ṣe é.” A lè ṣiṣẹ́ fún gbogbo ìgbé ayé wa, a sì lè gbiyanju pé ká dára tó láti gba ọ̀rẹ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n a kì í yoo dára tó.

Jésù wá, ó sì gbé ìgbé ayé pipé nípò wa, ó sì kú ìkú tí kọọkan wa yẹ kí ó ku. Ẹbọ rẹ̀ lórí agbelebu ń pe ẹnikẹ́ni tí ó fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ rẹ̀, kí wọn lè jẹ́ ẹni tó tọ́ níwájú Ọlọ́run. A lè dáwọ́ dúró láti ṣe gbígbìyànjú ìfaramọ́ Ọlọ́run àti ìfẹ́ rẹ̀, a sì lè sinmi nínú iṣẹ́ tí Jesu ṣe láti rí i dájú pé ó wà fún wa. Ẹ̀yi yìí ni oore-ofe!

Nígbà tí a bá ti ní ìrírí oore-ofe Ọlọ́run, ó ma yí bí a ṣe ń gbé ayé wa pada. Oore-ọfẹ ko nilo igbiyanju wa lati le gba, ṣùgbọ́n ó ń kọ́ wa láti sọ “bẹ́ẹ̀kọ” sí ẹ̀se àti láti gbé ìgbé ayé tó yẹ fún Ọlọ́run (Titu 2:11-13). Oore-ofe náà ń fún wa ní agbára láti ṣe iṣẹ́ rere:

“Ọlọrun sì lè mú kí gbogbo oore-ọfẹ máa pọ sí i fún yín, kí ẹ lè ní ohun gbogbo nígbà gbogbo, kí ẹ lè máa pọsí i nínú iṣẹ rere gbogbo” (2 Kọríńtì 9:8).

Jesu gba wa. Oore-ọfẹ rẹ yiwapada o si sọ wa di ominira.

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Orin ìyìn: Oore òfẹ́ ninu Ìtàn Rẹ

O ṣeéṣe pé o ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “ọ̀rẹ́-ọfẹ́,” ṣùgbọ́n kí ni ó tumọ̀ sí gangan? Báwo ni ọ̀rẹ́-ọfẹ́ Ọlọ́run ṣe lè gba wa là àti yí ìgbé aye wa padà? Kọ́ nípa bí ọ̀rẹ́-ọfẹ́ àgbàyanu yìí ṣe ń pàdé wa ní ibi tí a wà, tí ó sì ń yí ìtàn wa padà.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Pulse Evangelism fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://pulse.org