Orin ìyìn: Oore òfẹ́ ninu Ìtàn RẹÀpẹrẹ
Ìgbà Kan Wà Tí Mo Ṣìnà
Ìtàn Newton ni akopọ tunmosi, Nígbà kan rí mo ti sọnù, ṣùgbọ́n mo ti di àwárí.
A lè rí arawa nígbà tí a bá mọ pé a sọnù; nígbà tí a bá mọpé ọnà tó tọ wà, ṣùgbọn a kò sí lórí rẹ. Nígbà yìí, a máa mọpé a nílò ìgbàlà.
Òtítọ́ ni pé, láìsí Jesu, gbogbo wa ni a sọnù. A sọnù ní ẹ̀mí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò sọnù ní ara.
Bíbélì ṣe apejuwe ohun tí ó túmọ̀ sí láti sọnù:
"Ní ti ẹ̀yin, ẹ ti kú nínú àwọn ìrékọjá àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, nínú èyí tí ẹ ti wà láàyè nígbà kan rí nígbà tí ẹ ń tẹ̀lé àwọn ọ̀nà ayé yìí àti alákòóso ìjọba ojú ọ̀run, ẹ̀mí tí ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn aláìgbọràn." (Éfésù 2:1-2 )
Nígbà tí a bá sọnù, a ń gbé nínú ẹ̀se — àwọn ohun tí kọ́ to láti ṣe tí o lodi si ìlàna Ọlọ́run. A ò mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ẹ̀ṣẹ̀ àti òdodo. A kò tẹ̀lé Jesu, ṣùgbọ́n “ọ̀nà ayé yìí”. Ọ̀nà ayé yìí ń ṣe ìlérí ìyè, ṣùgbọ́n ó máa darí wa lọ sí iparun, àti, ní ìkẹyìn, ikú.
Kò sí ẹni tí ó sọnù tó lè wà ní ilé ní akoko kanna. Nígbà tí a bá sọnù ní ẹ̀mí, a kò ń gbé ní ilé pẹ̀lú Jésù. Jesu ṣe ileri pe Baba ati Òun tikararẹ yoo kọ ibugbe wọn pẹlu awọn ti o nifẹ wọn (Johannu 14:23).
Ìròyìn ayọ̀ ni pé a lè rí ọ̀nà àbáyọ. A kò ní lati gbé níta ilé Ọlọ́run titi ààyè. Kò sí ọ̀pá ìdákọ́ró lórí ilẹ̀kùn náà. Ṣùgbọ́n, a lè rí wa nigbatí ẹlòmíràn bá wá tí ó sì rí wa.
Ìdí nìyi tí Jésù fi wá. Nínú Lúùkù 19:10 ó sọ pé, "Nítorí Ọmọ-Eniyan wá láti wá àwọn tí ó sọnù, kí ó sì gbà wọ́n là".
Jesu ń wá àti gba àwọn tó sọnù, ń dari eni kọọkan sí ilé fúnra rẹ̀. -Kí àwa àti John Newton lè jọ kọrin pé, "Nígbà kan rí mo ti sọnù, ṣùgbọ́n bayii mo ti di àwárí”
Nípa Ìpèsè yìí
O ṣeéṣe pé o ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “ọ̀rẹ́-ọfẹ́,” ṣùgbọ́n kí ni ó tumọ̀ sí gangan? Báwo ni ọ̀rẹ́-ọfẹ́ Ọlọ́run ṣe lè gba wa là àti yí ìgbé aye wa padà? Kọ́ nípa bí ọ̀rẹ́-ọfẹ́ àgbàyanu yìí ṣe ń pàdé wa ní ibi tí a wà, tí ó sì ń yí ìtàn wa padà.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Pulse Evangelism fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://pulse.org