Orin ìyìn: Oore òfẹ́ ninu Ìtàn RẹÀpẹrẹ

Orin ìyìn: Oore òfẹ́ ninu Ìtàn Rẹ

Ọjọ́ 5 nínú 5

Oore-Ọfẹ Fún Gbogbo Ènìyàn

Lẹyìn tí a ti gba oore-ọfẹ, bi a se n ri awon eniyan ma yatọ

Dipo kí a wo àwọn ènìyàn bí òtá, a le ri wọn bí ẹni tí ó nílò oore-ọfẹ. Dípò tí a ó fi máa retí pé káwọn tó yí wa ká jẹ́ ẹni pípé, a lè nífẹ̀ẹ́ wọn pẹ̀lú gbogbo àṣìṣe àti àìpé wọn. Dipo kí a máa gbé ara wa ga, a lè mọpé ìyàtọ kan ṣoṣo tí ó wà láàárín wa àti wọn ni oore-ọfẹ Ọlọrun.

A kò lè dakẹ nípa oore-ọfẹ Ọlọrun.

Ọpọ ènìyàn ń wá ìfẹ, ìrètí, ayọ, àti ifokanbale nínu ohun gbogbo ayafi ní Jesu.

Charles Spurgeon, tí wọn mọ sí “Aremo àwọn Oníwàásù” sọ pé, “Olùtọjú ìwòsàn ti o tóbi náà ti fi oogun tí ń mú aláìsàn lára dá lé wa lọwọ. Ìwọ sì ń wo wọn bí wọn ṣe ń kú, àmọ o kò sọ fún wọn nípa ìmúnilára!”

Otitọ ni pé, ayé tó yí wa ká ń kú láìsí Jésù. Níwọn bí a ti bá Ọlọrun rẹ nípasẹ Jésù, a mọ ibi tí a ti rí ìgbàlà. Ọlọrun ti fun wa ni ifiranṣẹ igbala asi ni lati sọ fun awọn miiran.

“Gbogbo èyí wá láti ọdọ Ọlọrun, ẹni tí ó bá wa làjà sọdọ ara rẹ nípasẹ Kristi, tí ó sì fi iṣẹ ìránṣẹ ìlaja fún wa” (2 Kọríńtì 5:18).

Ihinrere ni iroyin ti o dara julọ ti ẹnikẹni lè gbọ. O jẹ ọrọ ifiranṣẹ Ọlọrun si agbaye, O si ti fi le wa lọwọ, àwa ọmọ Rẹ.

Alabasise rẹ nilo lati gbọ ọrọ ifiranṣẹ yii.

Aladugbo rẹ nilo lati gbọ ọrọ ifiranṣẹ yii.

Ọmọ kíláàsì rẹ ní láti gbọ ọrọ ifiranṣẹ yìí.

Idile rẹ nilo lati gbọ ọrọ ifiranṣẹ yii.

Gbogbo eniyan nilo lati gbọ ọrọ ifiranṣẹ yii.

Bẹ̀rẹ̀ nípa sísọ ìtàn oorẹ ọfẹ rẹ. Báwo ni o ṣe lọ láti sísọnù sí ẹni tí a ti rí? sísọ nípa ìgbàgbọ́ rẹ nínú Jésù lè jẹ ohun tí o bani lẹru. Àmọ́, ó tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Jésù fara da ẹ̀gàn, ìfiniṣẹ̀sín, àríwísí, àti ọ̀pọ̀ nǹkan mìíràn nítorí tiwa. Ṣé ìwọ náà ṣe tán láti fara da irú nǹkan bẹ́ẹ̀ nítorí Rẹ̀?

Béèrè lọwọ Ọlọrun láti fún ọ ní ìgboyà. Béèrè lọwọ Rẹ láti ran ọ lọwọ láti rí àwọn ènìyàn àti gbọ àwọn ìtàn wọn. Fífi ohun tó o gbà gbọ́ wàásù túmọ̀ sí pé kó o máa fetí sílẹ̀ kó o sì máa fìfẹ́ hàn bíi ti Jésù dípò kó o máa sọ gbogbo ohun tó tọ́.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn kò mọ̀ Jésù nítorí pé kò sí ẹni tó ti fihàn wọn tàbí sọ fún wọn nípa ọ̀rẹ-ọfẹ Ọlọrun. Ọjọ òní je ọjọ tí gbogbo èyí lè yípadà.

Ṣe igbasilẹ ikẹkọ ihinrere wa ọfẹ lórí pulse.org/makejesusknown.

Ìgbésẹ̀ tókàn

Olúkúlùkù wa ló ní ìtàn tirẹ̀.

Ìtàn nípa bí ọ̀rẹ-ọfẹ Ọlọrun ṣe kan wá. Àgbáyé nílò láti gbọ àwọn ìtàn wa. Ìdí nìyí tó fi jẹ́ pé ní ọdún mẹ́ta tó ń bọ̀, Pulse Evangelism yóò lọ sí àgbáyé láti gba ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìtàn nípa oore-ọ̀fẹ́.

Àwọn ènìyàn nílò láti gbọ́ ìhìn tí ó yí wa padà—ọrẹ-ọfẹ Ọlọrun jẹ fún gbogbo ènìyàn. Kò sí ẹni tí a yọ sílè. Kò sí ẹni tí ó ti jìnnà púpọ. Ẹnikẹ́ni tó bá sọnù lè di rírí. orẹ-ọfẹ ni ọnà kan ṣoṣo sílé.

A fẹ́ kí ẹ wà lára ètò àgbáyé yìí.
Ẹ lọ sí http://anthem.org/youversion Kí ẹ sì sọ ìtàn yín.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Orin ìyìn: Oore òfẹ́ ninu Ìtàn Rẹ

O ṣeéṣe pé o ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “ọ̀rẹ́-ọfẹ́,” ṣùgbọ́n kí ni ó tumọ̀ sí gangan? Báwo ni ọ̀rẹ́-ọfẹ́ Ọlọ́run ṣe lè gba wa là àti yí ìgbé aye wa padà? Kọ́ nípa bí ọ̀rẹ́-ọfẹ́ àgbàyanu yìí ṣe ń pàdé wa ní ibi tí a wà, tí ó sì ń yí ìtàn wa padà.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Pulse Evangelism fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://pulse.org