Orin ìyìn: Oore òfẹ́ ninu Ìtàn RẹÀpẹrẹ
Oore-ọ̀fẹ́ àgbàyanu
Báwo ni orin kan tí a kọ́ ní ọdún 1772 ṣe wà láàyè fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún? Báwo ní àwọn ọ̀rọ̀ nipa irírí ọkùnrin kan ṣe ṣe pàtàkì ninu ayé wa lónìí?
Boya nítorí pé awọn òrò orin wònyí sọrọ nípa iwulo pàtàkì ti gbogbo wa nílo: iwulo fun oore-òfé. Boya nitori itan okunrin yi pelu tiwa je ikana: Sísọ nun si dídi àwárí.
Ìdí ni yí ti o fi jẹ pé orin Oore ọ̀fe ṣe wa titi laye.
Ohun ti ọpọlọpọ ko mọ̀ ni itan ti ọkunrin ti o kọ awọn ọrọ olokiki wọnyi ni Ìlú Olney ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.
Gẹgẹ bí ọdọkùnrin, John Newton burú ju bí ó ti n gbàdúrà lọ. Ó maa n lo àwọn èeyàn nilokulo dipo kó nífẹẹ wọn. Ó nímọ lára àìnírètí jìnnà ju bí ó ṣe ní ìmọlára ìrètí lọ. Gẹgẹ bí ọgágun ọkọ ojú omi ti a fi n ko ẹrú, ó jìnnà sí ọlọ́run, ó sì pa àwọn ìlànà kristẹni tí ìyá rẹ̀ fi kọ́ ọ nígbà tó wà ní kékeré.
Lédè mìíràn, Newton ti ṣìnà. Pátápátá, láìsí àní-àní, láìsí iyèméjì. Ṣugbọn itan rẹ ko pari sibẹ.
Ní ọdún 1748, Newton ń darí ọkọ ojú omi rẹ nínú ìjì líle kan. Ó bẹrù pé ọkọ ojú omi náà àti àwọn atukọ̀ rẹ yóò ba afefe ìjì náà lọ, awon yóò sì pàdánù gbogbo nkan, títí kan ẹmí rẹ. Ninu ìjì yii ni Newton ranti Ọlọrun ti iya rẹ ti kọọ nipa rẹ. Ó ké pè é, ó sì bẹbẹ fún ìgbàlà pé kí o gbà òun lọwọ ikú nínú òkun àti lọ́wọ́ irú èèyàn tó ti di.
Ìyípadà ńlá gbáà lèyí jẹ́ fún Newton. Ọkọ náà gunlẹ layọ, ó sì bẹ rẹ ayé tuntun rẹ pẹlú Kristi. Ohun Atijọ ti koja lọ, tuntun ti bẹrẹ.
Newton tẹ síwájú láti di ọ̀kan lára àwọn pásítọ̀ tó ní ipa jù lọ nígbà ayé rẹ̀, ó sì di ọkan pàtàkì lára àwọn pásítọ tí wọn fi òpin sí ìmuni leru — ìyẹn ètò tóun fúnra rẹ̀ dá sílẹ̀ nígbà kan rí.
Ní gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀, Newton kò gbàgbé nǹkan méjì: “ Ó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ńlá àti pé Kristi ni Olùgbàlà ńlá.” Newton mọ ìdí tí ìtàn rẹ̀ fi yí padà nítorí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.
"Nítorí oore-ọfẹ ni a fi gbà yín là nípa igbagbọ. Kì í ṣe nítorí iṣẹ, ẹbùn Ọlọrun ni. Kì í ṣe ìtorí iṣẹ tí eniyan ṣe, kí ẹnikẹni má baà máa gbéraga"(Ẹfesu 2:8-9)
John Newton ti fi ilẹ ayé sílẹ ní ìgbà pípẹ sẹyìn, ṣùgbọn orin ìyìn ìgbésí ayé rẹ kò tíì fi ayé sílẹ.
Ore-ọfẹ Iyanu:
Ore-ofe! b’o ti dun to!
T’o gba em’ abosi;
Mo ti sonu, O wa mi ri,
O si si mi loju.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
O ṣeéṣe pé o ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “ọ̀rẹ́-ọfẹ́,” ṣùgbọ́n kí ni ó tumọ̀ sí gangan? Báwo ni ọ̀rẹ́-ọfẹ́ Ọlọ́run ṣe lè gba wa là àti yí ìgbé aye wa padà? Kọ́ nípa bí ọ̀rẹ́-ọfẹ́ àgbàyanu yìí ṣe ń pàdé wa ní ibi tí a wà, tí ó sì ń yí ìtàn wa padà.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Pulse Evangelism fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://pulse.org