Ìtàn Nípa Ọgbọn ỌlọrunÀpẹrẹ

Ìtàn Nípa Ọgbọn Ọlọrun

Ọjọ́ 7 nínú 7

Ẹbùn Ọlọrun Fun Ẹdá Eniyan

Ọgbọn, lẹyìn ìgbà ti Ọlọrun dá ayé tán di ẹbun ajogunba fún ẹdá ènìyàn fún awọn ìdí to ṣe pàtàkì; èkíní, fún igbekalẹ ẹkọ kíkà ati kíkọ, ẹkeji; làti lè kò ayé yí ti a ngbe lori rẹ, iketa; láti lè mọ Ọlọrun ati láti lè rìn nínú Ọnà Rẹ. Bẹ, Ọgbọn ti wá láti tẹdó

sí ayé yí.

Ni ọpọ ìdí a nlepa ẹkọ ìwé kíkà to jẹ ẹyà àpá kan Ọgbọn ati Ikeji láti mú ayé yí dára, ṣugbọn ìkẹta to ṣe pàtàkì la pati. O ṣe pàtàkì láti ni ẹyà Ọgbọn to ni ṣe pẹlú ibaṣepọ pẹlu Ọlọrun.

Ọlọrun fẹ kí o sunmọ Ohun, kí o tẹwọ Gba Ẹbùn Ọmọ bíbí Rẹ kán ṣoṣo láti bá rin, ṣugbọn, eleyi pé fún gbigboran sí òhun Ọgbọn láti. Inu ọrọ Ọlọrun; Bibeli, o ko le yan lati kọ eti dídì sí itọni, ẹkọ, ìbáwí ati imọran Rẹ, ti o bá fẹ́ gbádùn ìbùkún ati ojurere Ọlọrun.

Siwaju kika: Jakọbu 4:8, Johannu 3:16, Iṣe 2:38

Adura: OLÙWÀ, Mo rọ mọ ẹbùn Ọgbọn Rẹ.

Ìwé mímọ́

Day 6

Nípa Ìpèsè yìí

Ìtàn Nípa Ọgbọn Ọlọrun

Ọgbọn lati Ọrun jẹ ẹbùn Ọlọrun fún wà láti mọ ohun to jẹ ti Ọlọ́run to tọ ati òhún ti o tọ, níní oyè wọn ati gbígbé nípa wọn bi ofin. A ngbe nínú ayé tó kún fún ètò, ayineke, àrékérekè, irọ ati etekete satani, báwò ni wa ṣe lá gbogbo èyí já láì sí Ọgbọn Ọlọrun? Oba Solomoni lẹyin gbogbo ànfàní Ọrọ, Owo, Okiki, Ìmọ, ati irin re nínú itura ayé, ṣe àkòtàn Ọgbọn bi "ìbẹrù Olùwà"

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Adeoye Gideon fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://www.facebook.com/gideon.adeoye?mibextid=ZbWKwL