Ìtàn Nípa Ọgbọn ỌlọrunÀpẹrẹ

Ìtàn Nípa Ọgbọn Ọlọrun

Ọjọ́ 1 nínú 7

Ìwà Ọgbọn Ọlọrun

Ọgbọn na jẹ isẹra ẹni nipa ìrònú tó péye, ṣiṣe àkóso ati eto to péye ati idasilẹ nipa èrò inú; níní èrò abayọri fún ìṣòro ati wíwà ọnà láti ṣe ati ṣíṣe àwárí nkán ni ọnà ti yóò mú ìtẹ̀síwájú wa tàbí ṣe ohun na lọtun.

Gbígbé igbe ayé tó fi ọwọ, iwarìri ati Ògo Fún Ọlọrun ni Ọgbọn; ayé to korira níní ipin nínú ṣiṣe ibi, to ṣọra fún ìgbéraga ati riro àrà ẹni ju, ayé tí kó fẹ ni ohun ṣe pẹlú irọ ati ẹtan.

Ọgbọn tayọ jíjẹ ẹni tó yara tabi to ni imo iwe, ojẹ ohun mímọ̀, o ti Ọrun wa òsì kun fún òtítọ, nipa bẹ ẹni tó bá pé àrà rẹ ni Ọlọgbọn láì sí ìwà bi Ọlọrun ko sí loju ila.

Ọgbọn amā fi ọ sí ipò anfani lati gbà ìmọràn ti yóò fi ẹsẹ rẹ lè ọnà otitọ, yíò ró ọ lágbára imọ ati Oyè tó péye, nipa bẹ wa ma ni ayọ ati okun ni ìgbà gbogbo.

Kika siwaju: Owe 9:10-12, Oniwasu 9:11, Jákọ́bù 3:15-18

Adura: OLÙWÀ, Gbin ìbẹrù Rẹ Sí inú àyà mi.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Ìtàn Nípa Ọgbọn Ọlọrun

Ọgbọn lati Ọrun jẹ ẹbùn Ọlọrun fún wà láti mọ ohun to jẹ ti Ọlọ́run to tọ ati òhún ti o tọ, níní oyè wọn ati gbígbé nípa wọn bi ofin. A ngbe nínú ayé tó kún fún ètò, ayineke, àrékérekè, irọ ati etekete satani, báwò ni wa ṣe lá gbogbo èyí já láì sí Ọgbọn Ọlọrun? Oba Solomoni lẹyin gbogbo ànfàní Ọrọ, Owo, Okiki, Ìmọ, ati irin re nínú itura ayé, ṣe àkòtàn Ọgbọn bi "ìbẹrù Olùwà"

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Adeoye Gideon fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://www.facebook.com/gideon.adeoye?mibextid=ZbWKwL