Àlàyé nípa Ètò Bíbélì

Ìpè sí Iṣẹ́ Aṣíwájú tó jẹ́ Ìránṣẹ́Àpẹrẹ

Ìpè sí Iṣẹ́ Aṣíwájú tó jẹ́ Ìránṣẹ́

Ọjọ́ 3 nínú 5

Ìgbésẹ̀ tó jẹ mọ́ Ipò Ọ̀rọ̀

Bóyá o ní ìtàn tó panilẹ́rìn-ín (tàbí tó tinilójú) nípa àìgbáradì bó ṣe yẹ fún eré-ìje, ìdánwò tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ kan. Bóyá kò rí bẹ́ẹ̀ nítorí tí ìwọ má a ń gbáradì bó ṣe yẹ ní ipò yòówù tàbí ní gbogbo ìgbà. Ní ọ̀pọ̀ àwọn ipele tó wà nílé ayé, ìgbáradì wa a má a sọ irú ipa tí àwa yóò ní, bẹ́ẹ̀ sì ni iṣẹ́ aṣíwájú pàápàá kò yàtọ̀ sí èyí. Ó má a ń ran ni lọ́wọ́ láti ní òye ohun tó túmọ̀ sí láti kojú ipò aṣíwájú wa pẹ̀lú òye àti ìyọ́nú, láti gbáradì bó ṣe yẹ láti lè ṣe àṣeyọrí nípa dídarí àwọn ènìyàn, kí àwọn ènìyàn tó wà ní ibití ipa wa yóò dé lè dé ibi rere tó yẹ ki wọ́n dé.

Ẹ rántí pé Mose dé ipò aṣíwájú tó lágbára púpọ̀ náà nítorí ipò àìlágbára tí àwọn ènìyàn Ọlọrun ti bá ara wọn, ní Egipti. Àìní àwọn ènìyàn ni ó gbé Mose dé ipò aṣíwájú. Bákan náà, Nehemiah dààmú púpọ̀ nígbàtí ó gbọ́ nípa ipò tí ohun gbogbo wà ní Jerusalemu, ó sì gbéra rẹ̀ díde láti ṣe aṣíwájú àwọn ènìyàn Ọlọrun. Bóyá o lè ronú nípa irú iṣẹ́ aṣíwájú báyìí nítorí tí a ti dá ọ lóró – a sì ti pá ọ láyà – nípasẹ̀ ìrẹ́jẹ. Ìwọ kọsẹ̀ dé ipò aṣíwájú nítorí ìfẹ́ gbígbóná inú ọkàn rẹ láti mú àyípadà bá ipò àwọn ènìyàn Ọlọrun.

Nígbàtí Jesu dé ìlú kan, inú Rẹ̀ yọ́ sí àwọn èèrò tó wà níbẹ̀ nítorítí wọ́n dàbí àgùtàn tí kò ní olùṣọ́. Òun yára láti ní òye ipò tí àwọn ènìyàn náà wà lótìítọ́, Ó sì bá àìní wọn nípa ti ẹ̀mí àti nípa ti ara pàdé nípa pípe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ wá láti wá ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún wọn. Bóyá ìwọ tilẹ̀ nílò láti bèèrè lọ́wọ́ ara rẹ bí ó bá jẹ́ pé Ọlọrun ń pè ọ́ láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Òun láti lè darí àwọn ènìyàn lọ sí ibi rere tí Òun ti pèsè sílẹ̀ fún wọn. Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo ni ìwọ ṣe ń gbáradì fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí?

Ìtàn nípa bí Ọlọrun ṣe ń bá ọmọdékùnrin Samueli sọ̀rọ̀ fi àpẹẹrẹ hàn wá pé nígbàti Ọlọrun bá wá, Òun kò tíì rán wa lọ. Ààyè má a ń wà laarin àsìkò tí a pè àti àsìkò tí a rán ni lọ, nígbàtí ìgbáradì yóò wáyé. Ìgbáradì wa ni yóò sọ bí ipa wa yóò ṣe fẹsẹ̀múlẹ̀ tó. Bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà pé kí Ọlọrun ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lè mọ ohun tí Ọlọrun ń pè ọ́ sí, kí o tó gbà láti ṣe iṣẹ́ aṣíwájú tí a fi lọ̀ ọ́.

Rántí pé àkókò kìí yí iṣẹ́ aṣíwájú rẹ padà, ṣùgbọ́n a má a yí ìwọ fúnraàrẹ – tó jẹ́ aṣíwájú náà padà. Bóyá o tilẹ̀ mọ̀ nípa àwọn aṣíwájú tó gba ipò aṣíwájú tí wọn kò gbáradì bó ṣe yẹ fún un, bóyá èyí sì mú ìrìn-àjò iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí aṣíwájú tó ń darí àjọ kan tí kò mọ ibi tó ń lọ dópin pàápàá. Àìgbáradì bó ṣe yẹ lè ní àwọn àtúnbọ̀tán ọlọ́jọ́-pípẹ́ tí kò dára rárá. Lẹ́ẹ̀kan síi, iṣẹ́ aṣíwájú tí Ọlọrun fifún ọ yóò jẹ́ bákan náà láì kà ipò ìgbáradì rẹ sí, ṣùgbọ́n kò sí ẹnikẹ́ni lára wa tó fẹ́ gbé ilé ayé pẹ̀lú àbámọ̀ pé wọ́n ki ẹsẹ̀ ara wọn bọ ipò aṣíwájú pẹ̀lú ìjọraẹnilójú tàbí lásìkò tí kò tọ́, tàbí láì gba ìkẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ tó múnádóko.

Gẹ́gẹ́ bí aṣíwájú, a pè ọ́ sínú iṣẹ́ kan pàtó, iṣẹ́ aṣíwájú yòówù tí yóò sì ní ipa rere níí ṣe pẹ̀lú níní òye iṣẹ́ náà tí a pè ọ́ sí. Iye àkókò wo ni ìwọ ti lò láti fi gbàdúrà fún àwọn ènìyàn tí ìwọ ń wàásù fún? Iye àkókò wo ni ìwọ ti lò láti fi ní òye ipò wọn? Ní pàtàkì jùlọ, ǹjẹ́ ìwọ ní òye ibití Ọlọrun ń fẹ́ mú wọn lo, ǹjẹ́ o sì ti ṣàkójọ ìwásù rẹ ní ìbámu pẹ̀lú èyí bí? Kí Ọlọrun jọ̀wọ́ yí ọ padà sí aṣíwájú tó ń fẹ́ láti mú àyípadà rere bá àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè fi kádàrá rere wọn ṣe èrè jẹ.

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Ìpè sí Iṣẹ́ Aṣíwájú tó jẹ́ Ìránṣẹ́

A pè wá sí iṣẹ́ aṣíwájú bíi Jesu. Iṣẹ́ aṣíwájú bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ara-ẹni, kìí ṣe ipò, ibi-àfẹ́dé Iṣẹ́ aṣíwájú sì jẹmọ́ ìdarí àwọn ènìyàn Ọlọrun sí ìpinnu Rẹ̀ fún ayé wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀kọ́-kíkà ojoojúmọ́ yìí yóò ṣèrànwọ́ láti ...

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Afrika Mhlophe fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://afrikam.co.za/

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa