Ìpè sí Iṣẹ́ Aṣíwájú tó jẹ́ Ìránṣẹ́Àpẹrẹ

Ìpè sí Iṣẹ́ Aṣíwájú tó jẹ́ Ìránṣẹ́

Ọjọ́ 5 nínú 5

Ìlànà Ìrònú Nípa Iṣẹ́ Aṣíwájú

Àwọn àwùjọ onígbàgbọ́ kò tíì borí jíjọ̀wọ́ ara wọn sílẹ̀ fún ìsìn ẹni tó gbajúmọ̀, irú èyí tó wọ́pọ̀ laarin àwọn oríṣiríṣi àṣà káàkiri àgbáyé. Ìwà kárími gẹ́gẹ́ bí onígbàgbọ́ jẹ́ ohun tó wà láàyè, tó sì ń wáyé laarin àwọn ènìyàn ní àwọn ilé-ìjọ́sìn kan, ó sì ṣe pàtàkì fún wa láti sọ òtítọ́ nípa àwọn ewu tó wà nínú irú ìṣesí báyìí, kí a sì wá àwọn ìlànà ìrònú tó hàn kedere, tó sì kún fún ìrètí rere nípasẹ̀ àpẹẹrẹ iṣẹ́ aṣíwájú ti Jesu àti àwọn aṣíwájú inú Bibeli mìíràn fílélẹ̀.

A pè mí láti wá sọ̀rọ̀ níbi ìpàdé kan ní àsìkò kan, a sì pè mí ni “Aposteli” nínú ìpolówó ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí a lẹ̀ mọ́ òde káàkiri, láti lè mú kí ń lè jọ àwọn ènìyàn lójú síwájú síi, àti láti lè mú kí ọ̀pọ̀ ènìyàn wá sí ibi ìpàdé náà. Ohun tó jẹ́ kókó jùlọ lọ́kàn àwọn tó ṣàgbékalẹ̀ ètò náà ni iye èèrò tí yóò wá síbi ìpàdé náà. Bẹ́ẹ̀ sì ni, nígbàtí Paulu ṣe àkọsílẹ̀ àwọn oríṣiríṣi ẹ̀bùn iṣẹ́ aṣíwájú nínú ìwé Efesu 4, ó fi yé wa pé èrèdí àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí ni fún ìrẹ́pọ̀, ìmúrasílẹ̀, ìdàgbàsókè, ìmúnidúró, àti ìmúnilọ́kànle laarin àwọn ènìyàn Ọlọrun. Ìfinisípò gẹ́gẹ́ bí aṣíwájú a má a wá látọwọ́ Ọlọrun fún iṣẹ́ àti ìdí kan pàtàkì – kìí ṣe fún èrè ti ara ẹni. Àwọn ẹ̀bùn tí a fifúnni láti lè jẹ́ aṣíwájú wà fún ògo Ọlọrun àti fún ire àwọn ènìyàn Rẹ̀. Jesu a má a fúnni lẹ́bùn láti lè mú ìjọ Rẹ̀ dúró. Ó yẹ kí o lè bèèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé: Tani èmi tilẹ̀ ń fi ẹ̀bùn mi ṣètọ́jú ní báyìí? Tani ó ń jèèrè látara iṣẹ́ aṣíwájú mi? Ọ̀nà wo ni wọ́n ń gbà fi jèèrè?

Tún rántí pé ẹnití ó ní ẹ̀bùn kọ́ ni ó ni ẹ̀bùn náà. Òun kàn ń pa ẹ̀bùn náà mọ́ dípò ẹlòmíràn ni. Paulu pàápàá kò pe ara rẹ̀ ní “Paulu Aposteli”. Òun kọ́kọ́ jẹ́ Paulu lásán – lẹ́yìn náà ní ó jẹ́ aposteli.

Jesu, aṣíwájú tó ga jùlọ, ń pè wá pé kí a kọ́ nipa àwọn ìlànà Rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí aṣíwájú, a gbọ́dọ̀ ṣàgbékalẹ̀ àṣà tó ń mú àjàgà àwọn ènìyàn tí àwa ń darí lápapọ̀ fúyẹ́ síi, kí a mọ̀ọ́mọ̀ gbé ọkàn wa kúrò nínú àwọn ohun ti ara wa àti àwọn ẹ̀bùn tí a fifún wa, kí a sì ní ìfẹ́ àwọn ènìyàn tí a pè wá láti sìn. Jọ̀wọ́ mọ̀ pé, bí a bá ń sọ nípa iṣẹ́ aṣíwájú Kristeni, a má a ń sábà gbé ìwọ̀n tó ga ju bó ṣe yẹ lọ sórí ìtàn ìhùwàsí rẹ. Dípò èyí, ìrẹ̀lẹ̀ ni ó ṣe pàtàkì jùlọ. Ìyàtọ̀ wà laarin àwọn ènìyàn tó ní àwòrán ìhùwàsí tí a ti fi ọ̀dà kùn, àti àwọn ènìyàn tó ń foríbalẹ̀ níwájú Ọlọrun nítòótọ́. Àwọn ènìyàn tó lè kúnlẹ̀ níwájú Ọlọrun lè dúró níwájú ẹnikẹ́ni. Ẹnikan tó wà ní ipò aṣíwájú kò ṣe pàtàkì rárá ju ẹlòmíràn tí kò ní oyè aṣíwájú kankan lọ. Yálà ìwọ jẹ́ aṣíwájú tàbí ìwọ kìí ṣe aṣíwájú, ìwọ̀n bí ìwọ ṣe gba Ọlọrun tọwọ́tẹsẹ̀ tó láìṣiyèméjì ni yóò sọ bi ìwọ ṣe ṣe pàtàkì tó.

Ètò ẹ̀kọ́-kíkà yìí ń lọ sópin, ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe kí ìrìn-àjò rẹ gẹ́gẹ́ bí aṣíwájú tó jẹ́ ìránṣẹ́ ṣẹ̀ṣẹ̀ má a bẹ̀rẹ̀. Kí Ọlọrun mú ọkàn rẹ ṣípayá, kí ó sì rí ìtùnú gbà nípasẹ̀ òtítọ́ wípé ìwọ ń fi ẹ̀bùn aṣíwájú rẹ sin Ọlọrun, o sì fi ń ṣe rere fún àwọn ènìyàn tí Òun fẹ́ràn. Ayé rẹ kìí ṣe tìrẹ. Ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọrun láti lò ọ́ fún iṣẹ́ agbára Rẹ̀ nínú ìran yìí. Gbẹ́kẹ̀lé E láti jà fún ọ, àti láti dáàbòbò ọ́ nígbàtí ìṣesí rẹ bá wà lábẹ́ ìdánwò, kí ìwọ sì lè ní ìfọ̀kànbalẹ̀ nínú òye pé ìwọ dúró ṣinṣin nínú Rẹ̀. Bí ìwọ ṣe ń fi ìrẹ̀lẹ̀ wá láti mú kí àwọn àǹfàní tí o ní láti jẹ́ aṣíwájú mú ire bá àwọn ẹlòmíràn, kí Oluwa mú ọ rí Ìjọba Ọlọrun kí ó dé, kí ìfẹ́ Rẹ̀ sì ṣẹ.

Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Ìpè sí Iṣẹ́ Aṣíwájú tó jẹ́ Ìránṣẹ́

A pè wá sí iṣẹ́ aṣíwájú bíi Jesu. Iṣẹ́ aṣíwájú bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ara-ẹni, kìí ṣe ipò, ibi-àfẹ́dé Iṣẹ́ aṣíwájú sì jẹmọ́ ìdarí àwọn ènìyàn Ọlọrun sí ìpinnu Rẹ̀ fún ayé wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀kọ́-kíkà ojoojúmọ́ yìí yóò ṣèrànwọ́ láti ṣàgbékalẹ̀ ìpìlẹ̀ fífẹsẹ̀mulẹ̀ nípa ipò aṣíwájú tó ńránnilétí pé, kí o tó jẹ́ aṣíwájú, o kọ́kọ́ jẹ́ ìránṣẹ́, kí o tó jẹ́ ìránṣẹ́, o kọ́kọ́ jẹ́ àyànfẹ́ ọmọ-Ọlọrun

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Afrika Mhlophe fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://afrikam.co.za/