Àlàyé nípa Ètò Bíbélì

Ìpè sí Iṣẹ́ Aṣíwájú tó jẹ́ Ìránṣẹ́Àpẹrẹ

Ìpè sí Iṣẹ́ Aṣíwájú tó jẹ́ Ìránṣẹ́

Ọjọ́ 4 nínú 5

Iṣẹ́ Aṣíwájú tó Finilọ́kànbalẹ̀

Ó rọrùn láti lérò pé kò ṣeé ṣe fúnni láti jẹ́ aṣíwájú, kí ó sì tún jẹ́ ìránṣẹ́ nígbà kan náà. Ṣùgbọ́n bí àwa yóò bá jẹ́ aṣíwájú bíi ti Jesu, a gbọ́dọ̀ ṣetán láti ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ wa bíi Tirẹ̀. Aṣíwájú tó jẹ́ ìránṣẹ́ kọ́kọ́ jẹ́ ìránṣẹ́ ná kí ó tó jẹ́ aṣíwájú. Ó jẹ́ ohun tó jọ ni lójú pé, ní abala àkọ́kọ́ tó jẹ́ ìdajì lára ìwé ìhìnrere ti Marku, a ṣàfihàn Jesu gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ tó jẹ́ adarí, ní abala tó kẹ́yìn, a sì fihàn gẹ́gẹ́ bí adarí tó jẹ́ ìránṣẹ́.

A kò lè fọwọ́sọya nípa ìgbàlà wa nítorí tí ó jẹ́ ẹ̀bùn ore-ọ̀fẹ́ tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá. Ore-ọ̀fẹ́ kan náà ni ó pè wá sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ aṣíwájú pàápàá, nítorí náà, a kò lè fọwọ́sọya nípa èyí náà pẹ̀lú. Èyí lòdì sí èrò tó wọ́pọ̀ pé iṣẹ́ aṣíwájú jẹ́ ìgbéga tí a ṣiṣẹ́ fún. Kí Jesu tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ ní gbangba, Bàbá Rẹ̀ sú ìre fún Jesu, Ó sì jẹ́rìí pé, “Èyí sì ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.” (Matiu 3:17) Jesu kò tíì ṣe ìwásù tàbí iṣẹ́ ìyanu kankan rárá nígbà náà, síbẹ̀ Ọlọrun nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀ púpọ̀, Ó sì gbà Á tọwọ́tẹsẹ̀. Bí ìwọ bá jẹ́ òbí, ìwọ yóò mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ nítorí tí wọ́n jẹ́ tìrẹ; ìwọ kìí nífẹ̀ẹ́ wọn nígbàtí wọ́n bá hùwà rere nìkan. Síbẹ̀, bóyá o bá ara rẹ níbi tó ti jẹ́ pé o gbọ́dọ̀ kún ojú òṣùwọ̀n kan fún ìwà rere gẹ́gẹ́ bí aṣíwájú láti lè rí ojúrere àti ìfẹ́ Ọlọrun gbà. Gbìyànjú láti ṣàlàyé fún ara rẹ pé ọmọ Ọlọrun ni ìwọ ń ṣe nípasẹ̀ ìbí rẹ, kìí ṣe nípasẹ̀ ìwà rẹ.

Nínú ìwé Luku 10, a ṣàkíyèsi pé Martha ń wá ìfọwọ́sí nípa iṣẹ́ tí a fi lé e lọ́wọ́ láti ṣe, níbití Maria sì ti rí ìfọwọ́sí gbà lẹ́sẹ̀ Jesu. Mọ̀ pé àjọṣepọ̀ ni yóò kọ́kọ́ wáyé ṣáájú ojúṣẹ. Gẹ́gẹ́ bí aṣíwájú, jíjẹ́ ìránṣẹ́ jẹ́ ara iṣẹ́ rẹ, kìí ṣe oyè, kìí sì ṣe ìrẹnisílẹ̀ rárá.

Iṣẹ́ ìránṣẹ́ Jesu mú ohun tó kan àwọn ẹlòmíràn ní pàtàkì. Òun sin àwọn ẹlòmíràn, Ó sì ṣe aṣíwájú nípa mímú ìnira àwọn ènìyàn kúrò, àti ṣíṣètọ́jú àláfíà wọn. Ní ìdàkejì, iṣẹ́ ìránṣẹ́ ọ̀pọ̀ àwọn aṣíwájú nínú Ìgbàgbọ́ mú ohun ti ara wọn ní pàtàkì. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà ti Jesu bọ́ àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (5000) ènìyàn pẹ̀lú àkàrà àti ẹja mélòó kan. Lónìí, Satani ti yí àpẹẹrẹ náà padà, a sì ń rí àwọn ilé-ìjọ́sìn níbití ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (5000) ènìyàn ti ń bọ́ ẹnìkanṣoṣo: àlùfáà tàbí aṣíwájú wọn. Ó ba ni nínú jẹ́ pé ìtàn àwọn ilé-ìjọ́sìn kún fún àwọn ẹ̀rí tó fihàn pé ohun gbogbo kìí lọ déédé fún àwọn àwùjọ ibití oníwàásù ti jẹ́ olórí tó ga jùlọ lára àwọn aṣíwájú. Dípò èyí, aṣíwájú yẹ kó jẹ́ ẹni tó lè lo àṣẹ ipò rẹ̀ láti fi mú ire bá àwọn ènìyàn Ọlọrun. Lọ́nà kìíní, aṣíwájú a má a gbé idà ti Ẹ̀mí láti fi bá àwọn tó jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun jà, àti láti fi dáàbòbo àwọn ènìyàn Rẹ̀. Lọ́nà kejì, aṣíwájú a má a gbé gèlè ìránṣẹ́ dání láti fi wẹ ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn bí Jesu ti ṣe.

Lónìí, rán ara rẹ létí nípa ààmì ìdánimọ̀ rẹ: ìwọ jẹ́ ọmọ Ọlọrun. Fún ìdí èyí, kò sí iye iṣẹ́ tí o ṣe tó lè dín bí Òun ṣe fẹ́ ọ tò kù tàbí tó lè fikún bí Òun ṣe fẹ́ ọ. Ìwọ ní ore-ọ̀fẹ́ àti ààmì òróró Ọlọrun lórí ayé rẹ, nítorí tí ogun ti ẹ̀mí wà láti jà fún kádàrá àwọn ènìyàn tó wà lábẹ́ ìtọ́jú rẹ. Kí Ọlọrun jẹ́ kí gbogbo ìṣesí rẹ gẹ́gẹ́ bí aṣíwájú tó jẹ́ ìránṣẹ́ lè má a wá láti ipò tó ní ìgbẹ́kẹ̀lé tó ga nínú ìfẹ́ Bàbá rẹ tí mbẹ ní Ọ̀run, kí gbogbo èrò ọkàn rẹ fún ìsìn àti ìdarí àwọn ẹlòmíràn sì lè jẹ́ fún rere wọn.

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Ìpè sí Iṣẹ́ Aṣíwájú tó jẹ́ Ìránṣẹ́

A pè wá sí iṣẹ́ aṣíwájú bíi Jesu. Iṣẹ́ aṣíwájú bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ara-ẹni, kìí ṣe ipò, ibi-àfẹ́dé Iṣẹ́ aṣíwájú sì jẹmọ́ ìdarí àwọn ènìyàn Ọlọrun sí ìpinnu Rẹ̀ fún ayé wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀kọ́-kíkà ojoojúmọ́ yìí yóò ṣèrànwọ́ láti ...

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Afrika Mhlophe fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://afrikam.co.za/

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa