Ìpè sí Iṣẹ́ Aṣíwájú tó jẹ́ Ìránṣẹ́Àpẹrẹ

Ìpè sí Iṣẹ́ Aṣíwájú tó jẹ́ Ìránṣẹ́

Ọjọ́ 2 nínú 5

Àwọn Aṣíwájú a má a Gbé Àwọn Ènìyàn

Ronú nípa àwọn ènìyàn tó ní ipa tó ga jùlọ lórí ayé rẹ, tí wọ́n gbé ọ – nípa ti ara tàbí nípasẹ̀ ìgbaninímọ̀ràn – láti ipò kan sí òmíràn. Òtítọ́ ni pé aṣíwájú jẹ́ ẹni tó lè gbà láti bọ́ sí ipò kan, tó ní èrò àti gbé àwọn ènìyàn súnmọ́ àwọn ìpinnu Ọlọrun fún ayé wọn, pẹ̀lú agbára àti ojúṣe tí Ọlọrun fifún un. Nípasẹ̀ ìgbé-ayé àwọn aṣíwájú inú Bibeli bíi Mose, Nehemiah, àti àwọn mìíràn, àwa lè kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ohun tí sísúnni síwájú túmọ̀ sí, láì kíí ṣe nípasẹ̀ ìjọraẹnilójú, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ èrò rere tó ti ọ̀run wá.

Mose dàgbà nínú ìdílé àwọn ará Egipti tó ní àǹfàní tó pọ̀ ní ìkáwọ́, lẹ́yìn èyítí òun wá sá kúrò lọ sínú igbó níbití òun ti di darandaran. Èmi a má a ronú nígbà púpọ̀ nípa ohun tí kò bá ṣẹlẹ̀ sí Mose tó bá jẹ́ pé òun kò ní ìbápàdé igbó tó ń jóná náà pẹ̀lú Ọlọrun. Ṣùgbọ́n Ọlọrun farahàn láìsí àníàní, Ó sì jẹ́ kí Mose mọ àwọn ohun kan pàtó nípa àwọn ènìyàn Rẹ̀ – àti nípa ìjẹníyà – tí wọ́n ń là kọjá. Lótìítọ, Mose bọ́ sí ipò aṣíwájú nítorí ipò búburú tí àwọn ènìyàn Ọlọrun wà, nítorí pé wọ́n wà lábẹ́ ìdè àwọn ará Egipti, bákan náà, ọ̀pọ̀ àwọn aṣíwájú ló dé ipò adarí lẹ́yìn Mose nítorí ipò búburú tí àwọn ènìyàn tí a rán sí wà.

Mose jẹ́ afàdúràjagun àti wòlíì àti oníṣẹ́ ìyanu, síbẹ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí kọ́ ni wọ́n ṣàpèjúwe ipò aṣíwájú rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn nǹkan náà ni wọ́n ṣe pàtàkì. Dípò bẹ́ẹ̀, ohun tó ṣàpèjúwe ipò aṣíwájú rẹ̀ ni bí ó ṣe gbé àwọn ènìyàn Ọlọrun jade lọ sínú òmìnira wọn. Àwọn ohun èlò àti ìlànà iṣẹ́ aṣíwájú jẹ́ àwọn ohun tí à ń lò láti lè dé òpin ibití a fẹ́ dé. Ohun tó ṣe pàtàkì jùlọ ni pé kí àwọn ènìyàn Ọlọrun dé ibití Ọlọrun ti pèsè sílẹ̀ fún wọn. Ó ṣe pàtàkì pé a kò gbọdọ̀ fọkànsí àwọn ohun èlò iṣẹ́ aṣíwájú púpọ̀ jù, dípò bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí a fọkànsí ibití à ń gbé àwọn ènìyàn lọ.

Ó jọnilójú pé, Mose kò wọ Ilẹ̀ Ìlérí náà. Àlá rẹ̀ fún àwọn ènìyàn náà kìí ṣe nípa ara rẹ, èyí sì wà láàyè rékọjá ìgbé-ayé òun pàápàá. Àwọn aṣíwájú kan, ní ìdàkejì, a má a dé ibití a lè fi wé “Ilẹ̀ Ìlérí”, nígbàtí àwọn ènìyàn tó yẹ kí wọ́n ṣe aṣíwájú fún ṣì wà ní “Egipti”. Aṣíwájú tó ní èrò rere, tí kò ní ìjọraẹnilójú, kìí fi ẹnikẹ́ni sẹ́yìn. Aṣíwájú a má a dúró bí afárá tó so ìgbé-ayé àtẹ̀yìnwá àwọn ènìyàn pọ̀ mọ́ ọjọ́-ọ̀la wọn tó ti rékọjá sẹ́yìn. Wọ́n jẹ́ onígbọ̀wọ́ àyànmọ́, iṣẹ́ aṣíwájú wọn ni a sì lè ṣàpèjúwe nípasẹ̀ bí ìgbé-ayé àwọn ènìyàn ṣe yípadà sí rere tó lábẹ́ ìṣàkóso wọn.

Nígbàtí a bá ṣe iṣẹ́ aṣíwájú ní ìbámu pẹ̀lú bí Jesu ṣe fẹ́ kí a ṣe é, àwa yóò má a ronú ní ipò náà nípa àwọn ẹlòmíràn, kìí ṣe nípa ara wa. Kí Ọlọrun fún wa ní ìmọ̀ àti òye láti mọ ibití Ó ń gbé àwọn ènìyàn Rẹ̀ lọ, àti ọgbọ́n láti gbé wọn lọ sí ibi-àfẹ́dé tó yẹ. Kí a sì lè ní okun àìmọtaraẹninìkan láti jọ̀wọ́ ara wa sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí afárá tó so ìgbé-ayé àtẹ̀yìnwá àwọn ènìyàn mọ́ ọjọ́-ọ̀la ológo wọn, kí a sì má a rán wọn létí pé ìrètì mbẹ nígbà gbogbo.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Ìpè sí Iṣẹ́ Aṣíwájú tó jẹ́ Ìránṣẹ́

A pè wá sí iṣẹ́ aṣíwájú bíi Jesu. Iṣẹ́ aṣíwájú bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ara-ẹni, kìí ṣe ipò, ibi-àfẹ́dé Iṣẹ́ aṣíwájú sì jẹmọ́ ìdarí àwọn ènìyàn Ọlọrun sí ìpinnu Rẹ̀ fún ayé wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀kọ́-kíkà ojoojúmọ́ yìí yóò ṣèrànwọ́ láti ṣàgbékalẹ̀ ìpìlẹ̀ fífẹsẹ̀mulẹ̀ nípa ipò aṣíwájú tó ńránnilétí pé, kí o tó jẹ́ aṣíwájú, o kọ́kọ́ jẹ́ ìránṣẹ́, kí o tó jẹ́ ìránṣẹ́, o kọ́kọ́ jẹ́ àyànfẹ́ ọmọ-Ọlọrun

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Afrika Mhlophe fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://afrikam.co.za/