Àlàyé nípa Ètò Bíbélì

Ìpè sí Iṣẹ́ Aṣíwájú tó jẹ́ Ìránṣẹ́Àpẹrẹ

Ìpè sí Iṣẹ́ Aṣíwájú tó jẹ́ Ìránṣẹ́

Ọjọ́ 1 nínú 5

Ṣíṣe Àgbékalẹ̀ Ìpìlẹ̀ tó Tọ̀nà

Nípasẹ̀ ọgbọ́n inú ara ẹni, ó yé wa pé àwọn ẹni tó ní ìwà rere ni wọ́n má a ń sábà jẹ́ aṣíwájú rere, àwọn aṣíwájú rere sì ni wọ́n má a ń sábà mú kí àwọn ilé-iṣẹ́ tàbí àjọ kan lè ṣe rere. Ṣùgbọ́n láti lè ṣàgbékalẹ̀ ìpìlẹ̀ tó tọ̀nà fún iṣẹ́ aṣíwájú tó jẹ́ ìránṣẹ́ nínú ìgbé-ayé ti ara wa, a gbọ́dọ̀ ní òye tó yẹ nipa ìlànà ètò náà: ìhùwàsí ẹni ṣáájú ipò.

Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tó ń gbèrò àti jẹ́ aṣíwájú ni kò ní òye ohun tí iṣẹ́ aṣíwájú túmọ̀ sí. Ó ṣeé ṣe kí a ti yàn ọ́ sí ipò aṣíwájú láìní òye ohun tí ipò náà túmọ̀ sí. Ohun mẹ́ta pàtàkì ni ó ṣe kókó nipa iṣẹ́ aṣíwájú: aṣíwájú náà fúnraarẹ̀, àwọn ènìyàn tí òun ń darí (àwọn ọmọ-lẹ́yìn rẹ̀), àti ipò náà tí òun wà. Ìtumọ̀ èyí ni pé iṣẹ́ aṣíwájú bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ara ẹni, kìí ṣe pẹ̀lú ipò. Aṣíwájú kìí ṣe ènìyàn kan ṣáá tí a fi sí ipò tàbí tí a fún ní oyè. Òun gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹnití yóò má a lo ìwà rere rẹ̀, òye rẹ̀ nipa ohun gbogbo, àti ìṣesí rẹ̀ láti fẹsẹ̀ ìlànà rere àti ìlọsíwájú múlẹ̀. Nítorí náà, ilé-iṣẹ́ tàbi àjọ tó ń ṣe rere a má a wáyé nípasẹ̀ àwọn aṣíwájú rere, àwọn aṣíwájú rere a sì má a wáyé láti ara àwọn ènìyàn rere: àwọn ènìyàn tí ìwà rere wọn kìí yẹ̀, tí ìgbàgbọ́ wọn nínú ṣíṣe rere nígbà gbogbo dánilójú.

Gẹ́gẹ́ bí aṣíwájú, o gbọ́dọ̀ mú kí òye ibi-àfẹ́dé rẹ hàn kedere láti ìbẹ̀rẹ̀, nítorí ibi-àfẹ́dé tí o ní lọ́kàn ni yóò sọ irú àwọn ènìyàn tí ìwọ yóò má a tẹ́tísí fún ìyànjú. Ó yẹ kí o bèèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé: Ǹjẹ́ èmi ti ní àmọ̀dájú nípa ibi-àfẹ́dé mi bí? Ǹjẹ́ ìyẹn ti ràn mí lọ́wọ́ láti tọpasẹ̀ àwọn àṣàyàn tó wà fún mi gẹ́gẹ́ bí aṣíwájú bí? Tani tàbí kí ni àwọn ohun tí yóò mú àwọn ìgbésẹ̀ mi fẹsẹ̀múlẹ̀?

Àwọn aṣíwájú tó jẹ́ Kristẹni kọ́kọ́ jẹ́ Kristẹni kí wọ́n tó di aṣíwájú. Bẹ́ẹ̀ si ni, ní ìdàkejì, àwọn aṣíwájú tó jẹ́ Kristẹni kọ́kọ́ jẹ́ – wọn yóò sì má a fi ìgbà gbogbo jẹ́ – ọmọ-lẹ́yìn, nítorítí wọn a má a tẹ̀lé Jesu nígbà gbogbo. Fún èmi gẹ́gẹ́ bí ọmọ-lẹ́yìn Kristi, iṣẹ́ aṣíwájú gbọ́dọ̀ jẹ́ ìṣàfihàn àwọn ìwà rere Kristi. Kìí ṣe nípa ṣíṣe ìpinnu àti nípa pípín iṣẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn láti ipò agbára tí ènìyàn wà nìkan. Ó jẹ́ nípa gbígbé ìgbé-ayé tí àwọn ẹlòmíràn lè má a ṣàfarawé rẹ̀. Ronú nípa àwọn ohun tí yóò yípadà láwùjọ rẹ bí àwọn ènìyàn bá jẹ́ aṣíwájú bíi tìrẹ. Pẹ̀lúpẹ̀lú, ronù nípa àwọn ọmọ-lẹ́yìn rẹ ní báyìí – àti ìdí tí wọ́n fi jẹ́ bẹ́ẹ̀.

Jesu ṣàmúkúrò èrò àìtọ́ nípa pé iṣẹ́ aṣíwájú níí ṣe pẹ̀lú oyè tàbí ipò, àpẹẹrẹ iṣẹ́ aṣíwájú Tirẹ̀ sì mú wa jìnnà sí ewu tó wà nínú ìjọraẹnilójú, èyí tó má a ń bá ipò agbára àti àṣẹ rín papọ̀. Èrò Rẹ̀ nípa jíjẹ́ aṣíwájú yàtọ̀ pátápátá sí ìrírí tí àwọn ọmọ-lẹ́yìn Rẹ̀ kò bá ní pẹ̀lú àwọn àṣà ayé òde-òní, ó sì yàtọ̀ pátápátá sí àwọn àṣà iṣẹ́ aṣíwájú ti ayé wa òde-òní pẹ̀lú. Ó jọnilójú pé, àwọn ọmọ́-lẹ́yìn àti ọ̀rẹ́ Jesu àkọ́kọ́ kò ní òye bí ògo àti ipa wọn yóò ṣe pọ̀ tó ní ìkẹyìn. Síbẹ̀ wọ́n tẹ̀lé Jesu. Bóyá ìwọ lè ronú nípa àwọn aṣíwájú tí ìṣesí wọn jẹ́ ohun tí àwọn ènìyàn láti ìran-dé-ìran fi ṣe àwòkọ́ṣe láì jẹ́ pé aṣíwájú náà mọ irú ipa àìṣeégbàgbé tí òun ń fi lélẹ̀ sínú ayé nígbà náà, tàbí àwọn aṣíwájú tó má a ń kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹlòmíràn, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ-lẹ́yìn Jesu ṣe rí, tí wọ́n má a ń wá ọ̀nà láti kọ́ ẹ̀kọ́ láti lè tẹ̀síwájú.

Jesu ṣì ń fi ni ṣe aṣíwájú ní báyìí – ṣùgbọ́n ǹjẹ́ àwa ṣì ń tẹ̀lé E bí? Ẹ jẹ́ kí á bi ara wa àti ẹnìkọ̀ọ̀kan léère àwọn ibití a ti má a ń sábà tẹ̀lé àpẹẹrẹ àwọn aṣíwájú tí kò bá àwọn ohun tí Kristi ń fẹ́ mu. Ẹ jẹ́ kí á fi ìpìlẹ̀ iṣẹ́ aṣíwájú tó jẹ́ ìránṣẹ́ rere lélẹ̀, kí a si má a rántí pé jíjẹ́ aṣíwájú a má a ti ara ènìyàn jade wá, kìí sì ti inú ipò jáde, kí a sì má a gbìyànjú láti jẹ́ irú ènìyàn tí àwọn ẹlòmíràn yóò má a ní ìwúrí láti farawé.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Ìpè sí Iṣẹ́ Aṣíwájú tó jẹ́ Ìránṣẹ́

A pè wá sí iṣẹ́ aṣíwájú bíi Jesu. Iṣẹ́ aṣíwájú bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ara-ẹni, kìí ṣe ipò, ibi-àfẹ́dé Iṣẹ́ aṣíwájú sì jẹmọ́ ìdarí àwọn ènìyàn Ọlọrun sí ìpinnu Rẹ̀ fún ayé wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀kọ́-kíkà ojoojúmọ́ yìí yóò ṣèrànwọ́ láti ...

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Afrika Mhlophe fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://afrikam.co.za/

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa