I. Sam 3

3
OLUWA fara han Samuẹli
1ỌMỌ na Samueli nṣe iranṣẹ fun Oluwa niwaju Eli. Ọ̀rọ Oluwa si ṣọwọ́n lọjọ wọnni; ifihàn kò pọ̀.
2O si ṣe li akoko na, Eli si dubulẹ ni ipo tirẹ̀, oju rẹ̀ bẹrẹ̀ si ṣõkun, tobẹ̃ ti ko le riran.
3Ki itana Ọlọrun to kú ninu tempeli Oluwa, Samueli dubulẹ nibiti apoti Ọlọrun gbe wà,
4Oluwa pe Samueli: on si dahun pe, Emi nĩ.
5O si sare tọ Eli, o si wipe, Emi niyi; nitori ti iwọ pè mi. On wipe, emi kò pè: pada lọ dubulẹ. O si lọ dubulẹ.
6Oluwa si tun npè, Samueli. Samueli si dide tọ Eli lọ, o si wipe, Emi niyi; nitoriti iwọ pè mi. O si da a lohun, emi kò pè, ọmọ mi; padà lọ dubulẹ.
7Samueli ko iti mọ̀ Oluwa, bẹ̃ni a ko iti fi ọ̀rọ Oluwa hàn a.
8Oluwa si tun Samueli pè lẹ̃kẹta. O si dide tọ Eli lọ, o si wipe, Emi niyi; nitori iwọ pè mi. Eli, si mọ̀ pe, Oluwa li o npe ọmọ na.
9Nitorina Eli wi fun Samueli pe, Lọ dubulẹ: yio si ṣe, bi o ba pè ọ, ki iwọ si wipe, ma wi, Oluwa; nitoriti iranṣẹ rẹ ngbọ́. Bẹ̃ni Samueli lọ, o si dubulẹ nipò tirẹ̀.
10Oluwa wá, o si duro, o si pè bi igbá ti o kọja, Samueli, Samueli. Nigbana ni Samueli dahun pè, Ma wi; nitori ti iranṣẹ rẹ ngbọ́.
11Oluwa si wi fun Samueli pe, Kiyesi i, emi o ṣe ohun kan ni Israeli, eyi ti yio mu eti mejeji olukuluku awọn ti o gbọ́ ọ ho.
12Li ọjọ na li emi o mu gbogbo ohun ti mo ti sọ si ile Eli ṣẹ: nigbati mo ba bẹrẹ, emi o si ṣe e de opin.
13Nitoriti emi ti wi fun u pe, emi o san ẹsan fun ile Eli titi lai, nitori iwa buburu ti on mọ̀, nitori awọn ọmọ rẹ̀ ti sọ ara wọn di ẹni ẹgàn, on kò si da wọn lẹkun.
14Nitorina emi ti bura si ile Eli, pe ìwa-buburu ile Eli li a kì yio fi ẹbọ tabi ọrẹ wẹ̀nù lailai.
15Samueli dubulẹ titi di owurọ, o si ṣi ilẹkun ile OLUWA. Samueli si bẹru lati rò ifihan na fun Eli.
16Nigbana ni Eli pe Samueli, o si wipe, Samueli, ọmọ mi. On si dahun pe, Emi nĩ.
17O si wipe, Kili ohun na ti Oluwa sọ fun ọ? emi bẹ ọ máṣe pa a mọ fun mi: ki Ọlọrun ki o ṣe bẹ̃ si ọ, ati jù bẹ̃ lọ pẹlu, bi iwọ ba pa ohun kan mọ fun mi ninu gbogbo ohun ti o sọ fun ọ.
18Samueli si rò gbogbo ọ̀rọ na fun u, kò si pa ohun kan mọ fun u. O si wipe, Oluwa ni: jẹ ki o ṣe eyi ti o dara li oju rẹ̀.
19Samueli ndagba, Oluwa si wà pẹlu rẹ̀, kò si jẹ ki ọkan ninu ọ̀rọ rẹ̀ wọnni bọ́ silẹ.
20Gbogbo Israeli lati Dani titi o fi de Beerṣeba mọ̀ pe a ti fi Samueli kalẹ ni woli fun Oluwa.
21Oluwa si nfi ara hàn a ni Ṣilo: nitoriti Oluwa ti fi ara rẹ̀ han fun Samueli ni Ṣilo nipa ọ̀rọ Oluwa.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Sam 3: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa